Afonrere YORUBA Gbode

Leta Mailbag

Abawole Home Bonvenido Bonvenu | Igbelaruge Yoruba | Irohin Lakotun | oloyenewsgbode.tripod.com | Konyin, opon-itewe titun wo'ja agbaye | Irohin | Irohin | Iforowero Interview Page | Ikede | Photo Album Page | Leta Mailbag | E kowe si wa lori ero okan yin tabi nipa Yoruba: afonrereyoruba@yahoo.com E seun | Archives | New Page Title

Here's a chance for you to contribute.

Ise o kare si awon omo Yoruba ti n fako yo
 
Lati owo Dokita Samuel Kayode Olamijulo
 
Respeted Yoruba People worldwide, a ku dede iwoyi o.
Acting Vice -Chancellor Abiodun Adediran, greetings.
Congratulations on the challenges of your new position.
Ki Edumare jowo se Obafemi Awolowo University ni ile ogbon pataki  fun alaafia ati itesiwaju iran Yoruba -Amin
Professor Osotimehin, greetings. E ku ojo meta.
It is heart warming to know you now work at UNESCO.Oluwa a maa ran yin se o -Amin
Vice Chancellor Oyewale Tomori, greetings.
E ku ise ribiribi ti e ngbe se  ni Redeemers University ni ilu Eko.Owo a maa roke o -Amin.
Vice Chancellor Dele Aladekomo, E ku ise pataki ti e ngbe se lati ilu Ibadan. E si tun ku idele Dr. Adetunji. Oluwa a maa se emi ni fun yin lenu gbogbo aayan yin o -Amin.
Professor Yetunde Folarin Schleicher, greetings.
E ku ise pataki ti e nse fun eko ede Yoruba ni ilu Amerika.Oore ofe Olodumare a maa pelu yin o - Amin
Dr. Omidire in Brazil, greetings.
E ku akitiyan lori ilosiwaju ede ati asa Yoruba ni Brazil. Iwaju ni ebiti yin yio ma a re si o -Amin.
Princess Ademide Adinasse, greetings. congratulations again for your very energetic pursuits for Yoruba and African People advancement from Benin Republic. 
Compatriot Onayemi , thank you very much for "Learn Yoruba."
Dr. Fakinlede, thank you very much for your Yoruba dictionary and other publications.
Compatriot Babatola Aloba, thank you very much for your productive ventures for Yoruba Development from Austria.
Engr Oladele Olawole, thank you very much for your Yoruba products from Norway.
Olootu Molara Wood , e ku aayan lori eto Tiwantiwa.
Moderator Martin Akindana, we are very proud of your accomplishments in Chat Afrik.
Ojogbon Jare Ajayi , a dupe fun ise yin lori Afonrere Yoruba
Alagba Odunlami ati gbogbo omo egbe Yoruba, National Association ti USA e ku ise o.
Professor Adesuyi Ajayi, thank youfo doing us proud in USA.
Professor Mobolaji Aluko, like father like son, thank you for yourtireless commitment to the common good.
Lawyer Ibukunolu Babajide, thank you for your very insightful contributions from the UN in Arusha Tanzania.
Compatriot Wole Akande, thank you for Radio Abeokuta.
On and on and on goes the list from village farmers to Nobel Prize winners.
Egan ni en 
AWA YORUBA NI ENIYAN KAAKIRI AGBAYE.
A fi ogo fun Olodumare.
 
At Obafemi Awolowo University in Ile -Ife we cooperated to write a book:
People Cooperation for African Development.
We advocate the acceptance of a framework for African People Mutual Development pursuits at the complimentary levels of  Family; Native Town or Village ; Language Nationality ; Country Nationality ; Continent and Global.
 
The book can be accesses for free at:
 
Still unknown to most Yoruba people, including us the educated, there is an estimated  over 100 Million Yoruba people in the world today if we include:
 
1) All Persons who have one or more Yoruba parents, grandparents, great-grandparents, ancestors.

2) All Yorubas by marriage.

3) All who have become Yorubas, all over the world, through adoption or naturalization.
 
 
Please read more at :
 
We appeal to you and all Yorubas throughout the world to please do the best we can , at every opportunity to enhance better, polite, mature, very inclusive cooperation in tangible pursuits for mutual development among Yorubas whereever currently located .
 
Olodumare a fun wa se o - Amin.
 
Dr. Samuel Kayode Olamijulo

debayo121@yahoo.com

Ogbeni Bamgbose
a dupe pupo fun oro iwuri yin. Oluwa Eledumare yoo ma bu kun fun yin, ami.
A ti gbiyanju lati ni itakun-agbaye 9webusaiti) ti wa, sugbon olayanju (ti o so pe bi oun ko ba si nile ohun pupo ko lee je sise0 - iyen ni owo ni ko tii je.
Nipa nnkan keji ti e mu enu ba - ti kiko ede Yoruba pelu ami; ohun ti a ti gbiyanju ni. koda a ra ate-itewe (keyboard) ti won se fun ede yii (ati awon ede Naijiria miran. Awon omo bibi Yoruba kan lo see. Konyin ni won pe ate naa. Sugbon bi won ba si webusaiti wa ninu awon Komputa miran, oto ni ohun ti awon leta ti a te pelu ami yii yoo gbe jade.
E lo faa ti a fi n lo keyboard to kari.
Sugbon a ko dake. A o se nnkan gbogi lori eyi laipe. E seun.
Inu wa yoo dun bi e ba n kan si wa ni ida kookan.
Ire.
Ti yin tooto.
Jare ajayi
Olootu Agba
AfonrereYoruba

E ku dede iwoyi o,

Iyalenu gbaa ni o je nigbati mo ri webuasiti yin. Dansaki si yin o. Ori mi
wu fun ise ti e nse.

Mori pe ori Tripod ni e wa. Iranlowo wo ni e fe ki e le ni webusaiti tiyin
gan gan ki awon eniyan le ma wa si ibe.

Papa a ni lati wa bi a o se ma ko ede yourba ti a le ma yan ati lati ma fi
ami si pelu ero computa. E yi yio mu ki a le ka ede yi dara dara.

Ki Olodumare ati awon Baba nla wa fun yin se.

Oduduwa yio gbe yin o.

Emi ni tiyin ni toto

debayo


Olootu,
 
Inu mi dun, ayò mi si kun nigba ti mo ri iwe irohin afonrereyoruba lori itakun agbaaye. Ojó ti pe ti mo ti n wo ònà lati ri iwe irohin ni ede e yoruba lori itakun agbaaye. Mo lero wi pe laipe a o ri elomiran ti yoo ran wa lowo lati ri 'key-board' ti a o le fi ko yoruba lákoyé ati lákopé.
 
Oro mi ko ni po loni, sugbon lagbara Olorun e o maa ri owo o mi loore-koore. Mo fi gbogbo ara ki yin. Oduduwa a gbe gbogbo wa.
 
Oladipo Amolegbe

Alagba Amolegbe,

A dupe pupo fun kikan ti e kan si wa lori iyanju ti a n gba pelu Afonrere Yoruba. Nnkan iwuri gbaa lo je fun wa lati maa gburoo lati odo eyin onkawe. Eyi fi n han wa pe ohun ti a n se ki i se ifi akoko sofo. Se bi atokun ba ri pe awon eniyan n wo eegun re ti n jo, ori re a maa ya. E seun.

A n reti iwe yin lori ohunkohun ti e ba fe gbe jade fun araye paapaa julo nipa omo Yoruba nibikibi lorile agbaye. A o gbe jade lori iwe irohin naa.

Mo fe so fun yin pe e le to ipa google-search (www.google.com) de ibi ti Afonrere ati iwe irohin wa keji to wa fun awon eniyan wa ni esekuku Oloye News/Oloye Gbode (http://Oloyenewsgbode.tripod.com) wa.

Nipa ti ate-itewe, mo layo lati so fun yin pe awon omo Yoruba meji kan ti se agbekale ate-itewe (keyboard) ti o le ko gbogbo leta to wa ninu ede ti a ni lorile ede Naijiria - Yoruba, Hausa, Igbo, Efik, Igala ati beebee lo. Amerika ni awon to se n gbe. Sugbon omo Yoruba ni won. Laipe a o maa lo ate-itewe naa lagbara Alawura. E o ri pe Edumare n gbe owo awa omo Naijiria (paapaa julo awa omo Yoruba) soke. A dupe. Ekunrere alaye nipa ate-itewe ti a wi yii yoo jade ninu Afonrere laipe lagbara Olohun, e foju sona.

Titi ti a o tun fi ri iwe yin, Ire o.

Jare Ajayi

Olootun Afonrere

AfonrereYORUBA: Fun ipolongo, imugbooro ati ilosiwaju Yoruba kaakiri agbanla-aye. E-mail: afonrereyoruba@yahoo.com