Make your own free website on Tripod.com

Afonrere YORUBA Gbode

Abawole Home Bonvenido Bonvenue

Abawole Home Bonvenido Bonvenu | Igbelaruge Yoruba | Irohin Lakotun | oloyenewsgbode.tripod.com | Konyin, opon-itewe titun wo'ja agbaye | Irohin | Irohin | Iforowero Interview Page | Ikede | Photo Album Page | Leta Mailbag | E kowe si wa lori ero okan yin tabi nipa Yoruba: afonrereyoruba@yahoo.com E seun | Archives | New Page Title

Eemo; Awon Oyinbo tun de: Won ni Malesia lo ni epo pupa!

Ojoojumo ni idi ti o fi ye ki awa alawodudu mura giri lori oro ara wa n je jade. Yato si ika aleebu olori-ojori ti awon eya yooku ni agbaye n na si wa, eyi to tun sese n je jade bayii ni ti iyanju awon Oyinbo ile Amerika lati da ori itan dokodo nipa siso pe orile-ede Malesia (Malaysia) ni ope ti n so eyin ti wa si aye.

A o se iranti pe ni nnkan bi odun mejo lehin ti orile-ede Naijiria ti gba ominira ni orile-ede Malesia wa gba eso ope (ti n so eyin) lowo Naijiria ti won si bere sii gbin ni odo won. Sugbon bayii ti eso naa tun fe di owo ni oja agbaye (fun anfaani ti won sese ri pe o wa ni ara re), won n so pe Malesia ni eso yi ti se ni odun 18   . Bee si ni, nnkan bi ogorun odun sehin ni awon oyinbo arinrinajo to wa si Afrika ti so pe awon ri igi ope (ati epo pupa ti n jade lara re) ni Afrika – paapaa julo ni iwo oorun ile naa, Naijiria.

Se a ranti pe ohun to ba ti dara gbogbo ni won maa n fe so pe lati okeere lo ti wa si ile alawodudu!

Ohun to je kayeefi ni pe akosile ile Geesi kan http://www.cambridge.org/us/Books/kiple/palmoil.htm jewo, o si jerii si pe ile Afrika ni ope ti se. Sugbon awon afonsansegbagbo Amerika so ni ti won pe Malesia ni. A pe won ni      afonsansegbagbo Amerika nitoripe lenu igba ti won ri pe ohun ti awon n lo nibi ounje won tele n fa ailera ba won, ti won si ri pe epo pupa dara ni won tun itan ti gbogbo aye mo tele ko. Iyan ni siso  pe Malesia ni ope (ati epo pipon) ti se wa. E wo http://www.americanpalmoil.com/story.html. Awa ni afonrereyoruba n so pelu idaniloju pe IRO GBUU ni awon ara Amerika n pa lori oro yii. Apeere didori itan kodo won ni. Ki Oluwa gba wa.

Amo o, ikilo ni eyi n je fun wa. O ye ki a tete tun ero ara wa pa – ki a se ohun gbogbo to ye lati gbe Afrika ati orile-ede wa gbogbo laruge. Edumare a ba wa se o. Sugbon a gbodo ranti pe omo to si owo ni iya n gbe soke. Ire o.

Awon Irohin to je yo lasiko yii

 

 

Konyin, ape-itewe n wo oja agbaye

 Awon omo Yoruba tun f'akoyo ninu imo ero ati ise opolo

Lati owo Jare Ajayi

 

Laipe, ape-itewe (keyboard) eyokan-soso yoo le te iwe edekede to wu ki eniyan fe te ni agbaye. Iyan ede ti o ba je pe alifabeeti ikowe re da lori leta ti o je jade lati inu ede Latin. Ede Yoruba ati awon ede miran to wa ni ile Naijiria lo je pe iru alifabeeti ti a wi yii ni won n lo.

Ohun to je nnkan iwuri nipa oro yii ni pe awon omo Oodua ni won wa ni idi bi ape pataki yii se wa si aye ati bi yoo se di ohun ti mutumuwa n lo kaakiri agbaye.

Olobo to so Afonrere Yoruba fi han pe awon ede to je gbajugbaja gege bi ede Oyinbo (Geesi), Faranse, Jamani, Potugi, Giriiki, Latin, Sipaniisi, Rosia ati bee bee lo ni ape yii yoo see lo fun.

Ile-ise onimo ero ode oni kan ti oruko re n je Lagos Analysis Corporation (Lancor) ni o se agbejade ape yii. Ilu Boston ni orile-ede Amerika ni olu ile-ise yii wa. O tun ni eka pataki ni ilu Eko ni orile ede Naijiria.

Ogbeni Adejumobi Oyegbola ati Ogbeni Walter O. Oluwole   ni won je oludari ile ise ti a wi yii. Enikeeta won ti o je alabojuto ni Ogbeni George C.K. Van-Lare.

Ilu Eko ni won ti bi Ade Oyegbola nigba ti Walter je omo ilu Sagamu ni ipinle Ogun.

A o se iranti pe Afonrere Yoruba ti gbe oro jade nipa awon eniyan yii tele nigba ti a n soro nipa ape itewe won eyi ti won pe ni Konyin.

Pelu ape yii, eniyan le ko iwe ninu ede gbogbo to wa ni Naijiria – bi o ba ti je pe alifabeeti ede Latin ni ede naa fi n kowe.

alifabeeti ikowe ti o da lorii A B D ati bee bee lo gege bi Yoruba,  Igbo, Geesi, Faranse ni apere alifabeeti to da lori ede Latin ti a n so.

Orisi ona ikowe miran to wa ni agbaye ni ti Arabiiki, Sainiisi (Chinese), Japaniisi (Japanese to je pe o fi ara pe Sainiisi) ati bee bee lo. Omiran ni Heeburu Hebrew.

Lowo bayii, igbese ti n lo lowo lati ri pe ape titun yi bo si ori igba ni awon ilu nla-nla kaakiri agbaye.

A o mu ekunrere alaye nipa ile ise Lancor ati paapaa julo awon to se agbekale nnkan pataki yii wa fun yin laipe. E ku oju lona. Ire o.

 

OPA n mura fun ayeye odun kewaa

Egbe kan ti idagbasoke agbegbe Oke ogun je logun, Oke Ogun Progressive (USA) Incorporated n gbaradi fun ayeye odun kewaa ti o ti di dida sile.

Ojo kokandinlogbon osu kokanla (osu Belu) odun yii ni ayeye naa yoo waye.

Agbegbe Queens ni ilu New York ni ayeye naa yoo si ti sengere.

Awon omo-bibi agbegbe Oke ogun ni ipinle Oyo ni o da egbe yii sile. Gege bi alukoro egbe naa, Ogbeni Sunday Adegbola se fi to wa leti, ona ati ri pe, “ a ko ara wa jo, a si jo n se asepo, a si tun n jiroro lori idagbasoke enikookan wa ati ti ilu ti a ti wa” ni o se okunfa dida egbe yii sile.

Lenu igba ti egbe yii di kikojo, opo nnkan idagbasoke lo ti gbe se. Pataki ninu eyi ni iranlowo owo goboi ti won n fun awon akekoo to wa ni ile-eko giga ni Naijiria. Egberun meedogbon naira ni won n fun akekoo kookan lodoodun. Akekoo bii metala ni n je anfaani yii lodun kan. Titi ti akekoo bee yoo si fi pari eko re ni ile eko giga ni yoo ma je anfaani naa niwon igba ti o ba ti n se daadaa ninu eko re. Odun bii merin sehin ni eto pataki yii ti bere.

Oloye Gbode ri gbo pe egbe naa yoo maa se iranlowo fun awon omo egbe to ba jade ile iwe ni Amerika paapaa bere lati odun yii lo.

Lara awon to se agbateru egbe yii ni Alagba Tolani Ogundiran ti o je Aare egbe naa ki o to di oloogbe ni odun 2004, Ojogbon Segun Odesina, Alhaji Yekini Salami, Oloye R. Adedokun Atitebi, Diakoni Timothy Ayinla, Ogbeni Toye Okesola, Alhaja Yinka Atitebi, Oloye Yinka Ayedun, Ogbeni Sunday Adegbola, Alhaja Adunola Salami, Ogbeni Adejare ati Alagba Olaleye.

Lara awon ti won fun dijo n gbe egbe yii ro ni Iyaafin Ayinla, Ogbeni Omodewu, Ogbeni Adesola Ige, Ogbeni Akande, Iyaafin Oladokun ati Iyaafin Akande ati awon jankan jankan miran.

Sise Aare ti ko ni gbedeke:

Awon asofin ni ‘Ko s’ona nibe’

 

Idunnu subu layo fun awon omo Naijiria ni ibere ose yii latari bi awon asoju-sofin se fi opin si aba ati fun Oloye Olusegun Obasanjo ni anfaani ati tun se ijoba eleeketa si lehin ti saa ti n se lowo bayii ba pari ninu osu karun-un odun ti n bo.

Ile asoju-sofin agba (Senate) dibo lati fi so pe asiko ko tii to fun atunse si Konstitusan orile-ede wa. Abe atunse yii ni awon ti n da aba ati so Obasanjo di aare ayeraye fe go si.

Opo awon omo Naijiria lo ri eleyii ti won si ja takuntakun lati ri pe ala ti ko se ni.

Ni kete ti awon asoju-sofin agba (Sineto) ti bi aba yii wo, ni ile igbimo asoju-sofin kekere naa ti semi lori gbigbe aba naa ye wo.

Ko pe lehin ti Obasanjo bere saa keji ti n pari lo yii ti oun ati awon ‘arije labe ijoba’ ti bere ete bi Obasanjo yoo se maa ba ijoba lo titi di igba to ba wuu – dipo igba ti ofin ile wa ati awon eniyan ile wa fe.

Awon omoran to woye ke gbajare, sugbon awon kan so pe ohun ti ko sele ni won n pariwo le lori.

Ododo bere sii fi oju han nigba ti Obasanjo funraare soro lori oro naa nigba ti o se abewo kan lo si orile ede Jamini (Germany) ninu osu kewaa odun 2003.

Ajo to wa fun eto Gbangba L’Asa a ta  (Transparency International) lo pe Obasanjo lati wa soro lori akori kan ti won pe ni Iwa Ibaje ni Niaijiria: Irinajo Lati Adagun Asemase si Erekusu Bo se To  Ibe ni Obasanjo ti jewo pe awon kan n fi owo le oun lejika lati lo fun saa keta. Ko so boya oun yoo lo tabi oun ko nii lo. Sugbon lati igba yii ni awon omo ogun re ti mura si ise lati ri pe Obasanjo n ba ijoba lo. Awon to mo ewu to wa ninu ki enikankan soso maa se ijoba lo titi gbere bere sii ran Obasanjo ati awon omo-ogun re leti itan ‘A o m’erin joba’.

Won o gbo sa o, titi ti abuku fi kan won lati ile igbimo asoju-sofin yii.

Obasanjo nikan ko ni awon arije ninu ijoba kan-n-pa yoo koko ti gbon-on gbon-on. Bee ni won se fun Alagba Nelson Mandela ati Aare Thabo Mbeki ti orile ede Guusu Afrika (South Afrika). Sugbon awon yen so pe rara o, o ni igba ti ‘je mi lowo’ n ye’ni mo.

Lara awon aare to fe ku sori aleefa ni Afrika ni Robert Mugabe ti Zimbabwe, Compaore ti Cote D’Ivoire ati beebee lo.

Iru iwa yii lo si n begidina idagbasoke ile alawodudu. Oun naa lo fa ti ogun ati hilahilo se po.

A dupe pe Oluwa ba wa segi le ti Naijiria ki o to d’ogun, ki o to di ote.

 

OKE OGUN ni Amerika n se'pade

 

Ipade awon omo Oke ggun to wa ni Amerika (Oke ogun Progressive Association (USA) Inc.) yoo waye ni ojo Abameta, ojo ketadinlogbon osu Karun-un (Osu Ebibi) ti a wa yii.

Oro nipa idagbasoke agbegbe Oke ogun ati ti orile-ede Naijiria ni  awon omo egbe fe gbe yewo nibi ipade yii gege bi akowe egbe, Ogbeni Olatoye Okesola se so.

Ojule 245, Opopona Hillhurst, New Britain, Conneticutt, 06053 USA ti o je ibugbe ebi Jare Adeyemo ni ipade ote yii yoo ti waye bere lati agogo meji osan.

OPA je pataki lara awon egbe ti oro eko awon omo Oke ogun ati idagbasoke agbegbe naa lapapo je logun gidigidi. Egbe naa si ti n se iranwo olorijori latari eyi lati bi odun meloo kan sehin.  

Aare Ile Naijiria

Isunsiwaju asiko sisejoba la n beere fun kii se Saa Keta’

Alaga egbe PDP lo so bee

Lati owo Jare Ajayi ati Dejo Olaiya

Awon adari egbe oselu Alaburanda ti n se ijoba lowo ni orile-ede Naijiria ti tun gba ona ara yo latari oro mima a ba eto isejoba lo lehin ti saa awon to wa lori aleefa ba pe tan.

Nigba ti o n soro nibi ipade ti o ba awon osise aare ati awon eekan lenu ise ijoba apapo (oloselu) soro ni Abuja lojo ‘Ru to koja, alaga egbe alaburanda (Peoples Democratic Party, PDP), Dokita Ahmadu Ali so pe awon eniyan ko ni agboye nipa ohun ti egbe oun ati awon emewa aare Olusegun Obasanjo n beere fun.

Gege bi o ti wi, awon eniyan n gbe oro kiri pe awon n beere fun sise aare leeketa fun Oloye Olusegun Obasanjo.

"Eyi ko ri bee rara. Ohun ti a n beere fun ni isunsiwaju eto ijoba ti Aare Obasanjo n se lowo yii. Kii se pe a n beere fun asiko miran. Eyi ti n se lowo yii naa ni a fe ki o di sisun si waju ki Aare le baa ri aye pari awon ise ribiribi to dawo le fun idagbasoke orile-ede Naijiria". Ahmadu Ali lo so bee nibi ipade ti o se naa.

Gbagede Ipade to wa ni ibujokoo Aare (Presidential Villa) ni olu-ilu wa, Abuja ni ipade naa ti waye ni ale ojo ti a wi yii.

Oloye Anthony Anenih tii se alaga igbimo teekoto egbe naa, amugbalegbee aare Obasanjo lori oro to je mo ti Ile Igbimo Asofin, Iyaafin Florence Ita-Giwa ati awon lookolooko osise ti Aare yan s’enu ise lo pejupese sibi ipade naa.

Ali so yanya pe iyato gedegede wa laarin ‘saa keta’ ati ‘sisun asiko isakoso siwaju’.

O wa paa lase fun gbogbo awon ti Aare Olusegun Obasanjo yan si ipo pe o di dandan fun won lati lo maa sa gbogbo ipa won won lati ri pe aba sisun asiko isejoba Obasanjo siwaju di amuse.

"Orile-ede k’orile-ede ti o ba se oriire lati ni iru Oloye Olusegun Obasanjo gege bi aare gbodo ki ara re ku oriire. Iru orile ede bee gbodo sa gbogbo agbara lati ri pe iru eni bee ko kuro lori aleefa ki ise ribiribi ti n se ma baa di ajambaku ati pipati.".

Lara awon ise ribiribi ti Ali toka si gege bi ohun manigbagbe ati ‘mapati’ ti Obasanjo n se ni ti afefe alagbara

(liquidified natural gas).

Ni tie, Oloye Anenih ti o ti je minista tele ti o si tun je eni ti o maa n ba Aare Obasanjo san igbo to ba diju so pe Obasanjo lo yan awon to wa ni ipo ijoba kaakiri. Obasanjo yii ni won si gbodo maa wari fun.

"Ibikibi to wu ki e ti maa sise lowo bayii, Aare Obasanjo lo fowo si gbigba sise yin. Nitori naa ohunkohun to ba fe ni e gbodo ba fe. Ni bayii, ohun to fe ti a si gbodo ba fe ni mimaa ba eto ijoba lo gege bi aare orile-ede yii. Latari eyi, ki onikaluku yin lo si ijoba ipinle, ijoba ibile ati odo awon asoju yin to wa ni ile Igbimo Asofin lokookan. Ki e lo ri pe won fi owo si aba lati je ki Oloye Obasanjo tun n ba ise re lo gege bi aare orile ede yii."

Nigba ti okan lara awon to wa nibi ipade naa beere boya awon to n gbero sisun iseto ijoba siwaju yii yoo se eto ti yoo je ki awon ri ise yii se nibi ti won n ran awon lo fun awon, Iyaafin Ita Giwa so pe ki obinrin onibeere naa pa enu re mo. "Se gbogbo ohun ti aare se fun yin yen ko to? Lai tile je pe eni kan so fun yin tabi enikan se eto kan fun yin laye oto, se o ye ki e tun beere nnkankan mo ki e to maa polongo aare kiri lori ohun ti a n beere yi?"

Awon agbenuso fun Aare yii toka si orile-ede Libya, Gabon ati Malaysia gege bi ibi ti awon aare won ti n lo ‘saa koniye’

"Eyi ti n je ki awon orile-ede yii ri ere ailegbe."

Ajodun tun ko fun JF Odunjo

Eto Isedajo Awon Yoruba: Bo ti Je, Eko Inu Re ati Ipenija to wa Nibe ni akori eto idanilekoo to waye ni gbogban apero nla (Conference Centre) to wa ni ile-eko giga Fasiti Ibadan.

Ojo Isegun tii se ojo kinni Osu Ebibi (osu karun-un) ni idanilekoo yii n waye.

Idanilekoo yii je ara ayeye ti won fi n se iranti ojo-ibi ati ojo ipapoda ogbontagi ninu amugbooro kiko ati kika Yoruba, Oloye J.F. Odunjo.

Oludanilekoo ojo naa ni Ojogbon Ademola A. Popoola, oga pataki kan ni owe yii je ni ile-eko giga Fasiti ti Obafemi Awolowo to wa ni Ile-Ife.

Ojogbon (Iyaafin) Jadesola Akande to ti fi igba kan je lalkoso Fasiti ti Ipinle Eko ni alaga ijokoo naa.

ayeye idanilekoo yii ni yoo je ekejila iru re lati odun 1984 ti o ti bere

LILO EDE ABINIBI FUN EKO IMO -IJINLE (Sayensi)

Ede Yoruba wuyi pupo lati ko eko imon-jinle)

Lati owo J. F. Akindele

Olotu,
Ki n to bere alaye mi, mo ni lati kan sara si yin fun ise ribiribi ti n se laarin awa omo Yoruba.

Mo fe fi ori webusaiti yi gba awon eniyan wa ni iyanju nipa oro kan ti o waye tele ri sugbon ti a ko ri ibi ti ati le e jiroro nipa re. Eyi ni lilo ede abinibi fun kiko awon omo ileewe ni eko imo-ijinle (sayensi), imo-ero (technology), ati eko isiro (mathematics).

Ni nkan bi odun meloo kan sehin, Oloye (Ojogbon) Babs Fafunwa daba wipe o ye ki a maa fi ede abinibi ko awon omo wa ni awon ileewe wa. Kii se wipe a kii se eleyi rara, sugbon ni inu awon nnkan bi eko isiro, ati imo-ijinle, o di dandan ki a ko awon omo ni ede Geesi ki a to bere sii ko awon omo. Oloye Fafunwa ri i wipe ki awon omo wa to bere sii ko awon eko wonyi, awon egbe won ni awon orile ede ti a ti n fi ede binibi tiwon ko won yoo ti ni ilosiwaju ju awon omo tiwa lo. Ki o ma dabi eni pe eleyii ko ni seese larin awon omo wa, Oloye Fafunwa se asewo (experiment) kan. Asewo yi ni kiko (teaching) awon omo
ileewe alakobere titi de ile eko giga pelu edee Yoruba. O ri i wipe awon ti o lo ede Yoruba yi ko kuna ninu iwe kiko ati iwe kika.

Lehin eyi, awon ojogbon die se akitiyan lati ri i pe a tele igbese Oloye Fafunwa, sugbon lehin odun die, gbogbo ipa won ku die ka a to.

Kiko awon omo ileewe pelu ede abinibi je nnkan ti o je mi logun pupo. Die ninu awon akitiyan temi gegebi onkowe (author) ni wipe mo ko iwe atumo-ede (dictionary) kan, Modern Dictionary of the Yoruba Language, fun awon ti won ni ife lati ko iwe imo-ijinle. Lehin eyi, mo se alaye awon oro imo-ijinle ninu awon iwe miran ti mo ti ko. Sugbon, kini anfaani t'o wa ninu pe ki a maa ko awon omo ileewe wa pelu ede abinibi? Ki l'o si je awon ifaseyin ati awon isoro ti o wa ninu igbese yi?

Amo, ki n to bere sii dahun awon ibeere wonyi, mo fe ki e gba mi laye lati so bi ede Yoruba funrare ti se. Eyi ni yoo fi han gedegbe boya o ye tabi ko ye ki a maa fi ede Yoruba ko awon omo wa ni eko imo-ijinle. Ona meta ni ede Yoruba ti a n so lonii ti se. Ona kinni je ede ti awon obi wa ti n so lati atetekose (eyi ni Yoruba ti ko je amulumala (Pure Yoruba Language). Eleyi ko ipa bi aadorun ninu ogorun (90%) ninu edee wa.

Ona keji je ede ti o se wa lati ile Larubawa (Arabic) ti a si ti gba gegebi ede Yoruba (Eleyi ko bi ipa marun-un ninu orun (5%) ninu ede Yoruba.

Ona keta je ede awon Geesi ti a ti gba bi ede tiwa. Awon eleyi ko ipa marun-un ninu ogorun-un (5%) ti o ku. Bi a ba fi oju inu wo o, a o rii wipe ede wa ko ni amulumala ti o po rara. Bi a ba ni ki a fi ede wa we ti awon Geesi, a o rii wipe ede Geesi je amulumala awon ede to po pupo. Boya ni a se le ri ede agbaye kan ti ko ni ipa ninu edee Geesi.

Idi ree to fi je pe bi omo ilu Geesi funraare (British person) ba fe mo itumo awon oro kan ninu ede Geesi, o nilati wa iwe atumo-ede ti Oyinbo si Oyinbo (English to English Dictionary) lo. Paapaa bi a ba fe ko ede Geesi ni akoyege, o di didan ki a tun ko ede awon Faranse, Itali ati ti awon Jamani (French, Italian and German). Ede Geesi soro pupo lati ko ati lati mo. Sugbon ede Yoruba ko ni abawon iru eleyi. Ede Yoruba je ede kan ti o
je ede pipe. Ko si wipe a n wa iwe atumo-ede Yoruba si Yoruba (Yoruba
to Yoruba Dictionary) lati mo nnkan ti a n so. (Mo se awon alaye yii ni
kikun ninu Yoruba, Modern Practical Dictionary ati Dictionary of the Yoruba Language.)

O fi han wipe ni kete ti omo ba ti bere sii so ede Yoruba ni o ti setan lati lo ede yi fun nkankinkan ti a ba fe ko o.

Nitori idi eyi, ede Yoruba suwon ju ede Geesi tabi edekede miran lona pupo lati fi ko awon omo ni ede imo-ijinle ati imo-ero (teknoloji).

 Ninu akosile ti n bo, emi a gbiyanju lati se asaro lori awon anfaani ati isoro t'o wa ninu igbese yi.

E se pupo Olotu

Fakinlede JFAKINLEDE@aol.com Falana yoo jeri pe Abdulsalami mo nipa iku Abiola

Yoruba bo won ni iyan odun meta le jo’ni lowo. Bee gege ni oro n ri bo fun olori-ede Naijiria tele, Ogagun(fehinti) Abubakar Abdulsalami.

Idi ni pe igbejo yoo bere lori esun ti awon kan fi kan-an pe o lowo ninu iku Oloye Moshood Kasimaawo Olawale Abiola ati aya re Alhaja Kudirat Abiola. Awon omo Yoruba atata meji yii lo si orun osan gangan lasiko ti Abdulsalami fi je olori ologun ati olori orile ede Naijiria laarin odun 1998 si 1999.

Ninu ejo ti awon ajafun-eto omoniyan meji Omowe Arthur Nwankwo ati Arabinrin Hafsat Abiola pe si ile-ejo kan ni Ariwa Illinois ni orile ede Amerika, olupejo fi esun kan pe Abubakar Abdulasalami ati ijoba re mo si, won si se okunfa iku to pa awon eni meji ti a wi yii. Eyi nikan ko, olupejo tun so pe ijoba Abdulsalami te eto omoniyan loju won si se ipalara fun awon Naijiria.

Nigba ti igbejo waye ni ojo ketadinlogbon osu keta (osu Erena) odun yii niwaju Adajo agba Mathew F. Kelly, adajo yonda fun olupejo lati pe elerii wa. Okan lara awon elerii ti awon olupejo fe pe ni Agbejoro Femi Falana ti o fi ilu Eko se ibujokoo. Falana ko lee wa ni ile ejo ni ojo ti a wi yii.

Eyi lo faa ti adajo fi yonda fun lati wa jerii ni ojo kerin ati ojo karun-un osu karun-un (Osu Ebibi) ti n bo. Latari eyi, Falana ti o je Aare egbe agbejoro fun ile Afrika yoo lo jeri oro ni ilu Illinois ni ojo ti a wi yii.

A o se iranti pe ojo kerin osu kefa (Osu Okudu) odun 1997 ni awon amookunsika se iku gbigbona pa obinrin takuntakun n ni, Kudirat Abiola. Ojo keje osu keje (osu Agemo) odun to tele (1998) ni won se iku pa oko re, Moshood Abiola ninu tubu ti won fi si ni Abuja.

Abiola ni eni ti awon omo Naijiria di ibo yan ninu ibo manigbagbe to waye ni ojo kejila osu kefa (osu Okudu) odun 1993. Ibrahim Badamosi Babangida ti o je aare orile ede yii nigbana fagile ibo pataki yii nigba ti won ri Abiola lo jawe olubori. Rogbodiyan to seyo latari eyi ko Naijiria sinu yooyo eyi ti a ko tii yo kuro nibe titi di oni.

Babangida fe taku si ori aga aare, sugbon awon Naijiria ko gba. Osan kan oru kan lo ko eru re kuro ni ile ijoba to fi ijoba fidihee ti Oloye Ernest Sonekan je olori fun de ile pelu erongba pe oun (Babangida) n pada bo.

Laarin bi osu keta ni Ogagun Sani Abacha gba ijoba lowo Sonekan ti oun si bere si i fi kannpa se ijoba le awon eniyan lori. Oun naa gbidanwo lati so ori aga aare ile Naijiria di oye ajewo fun ara re. O so Abiola sewon, o si bere sii pa awon eniyan to ba ti takoo paapaajulo awon Yoruba.

Adura awon omo ile yii lo gba nigba ti jagunjagun naa gbe emi mi ojo keje osu kejo odun 1998. Iku Abacha yii lo fi aye sile fun Abdulsalami lati di olori orile ede yii. Sugbon siwaju ki o to di olori, oun naa pelu awon ti n se ijoba, nitori oun ni olori ologun.

Awon arokan gbogbo wonyi lo fa fifura pe owo re ko mo nibi iku awon eni ti a wi yii. Ile ejo ni yoo so boya eyi ri bee tabi ko ri bee.

Bororo tu Abule Ajagba leba Oyo

Osan kan oru kan ni awon ara abule to wa ni ijoba ibile Atiba ni Ipinle Oyo fi sa kuro ni abule ti won ti n gbe ti won si n dako lati odun gbonhan. Nnkan bi ibuso mokanla ni abule yii je si ilu Oyo Alaafin.

Aarin inu osu Erena (Osu Keta) odun yii ni eyi sele.

Iwadii AfonrereYoruba fi han pe awon Fulani Bororo ti n da eran maalu kiri lo se okunfa ‘bolo-o-yaami’ yii. A gbo pe awon ara abule yii yari fun awon Bororo to n f eran je ohun ogbin ti won se wahala le lori. Oro naa di ija. Nibi ti eyi ti n lo lowo, eniyan meji gbe emi mi. A gbo pe nitori ihamora awon Bororo yii owo won fe ju ti awon ara abule lo. Sugbon eyi nikan ko ni o je ki awon ara abule naa sa.

A gbo pea won olopaa wa si abule naa lati wa mu awon ti won fura si pe won mo nipa bi awon Bororo kan se ku.

A gbo pe nnkan bii egberun mejo naira) ni won fi n gba iduro iru awon ti won ba mu bayii. Eyi lo je ki awon ti a wi yii fi abule naa sile. Se eni ti apa eni ko ba ka, Eleduwa laa fi sile fun.

Irohin fi to wa leti pe ilu Oyo ni awon eniyan wonyi gba lo.

A tun ri gbo pe awon eniyan ti n dide si oro naa.

Awon danadana maa n soro ni ona abule yii eyi ti o so Oyo po mo Iwo ni ipinle Osun. Awon ajajagbara Oodua (OPC) si gba adugbo naa sile. Sugbon a gbo pe lenu ojo meta yii ti o dabi enipe ijoba apapo ti ge OPC lori ni egbe naa ko ti le e se bii ti se tele dabi alara mo.

Awon abule to tun wa ni adugbo yii ni Araromi, Aba Eleni, ati beebee lo. Abule naa ko jinna si ilu Aawe. A o maa fi bi oro ba ti n lo to yin leti lola Oluwa. Ile Yoruba ko ni fo o, ase. Naijiria ko gbodo baje, bi eyi yoo se je bee, o di owo gbogbo wa.

Ajo N EPA n beere owo goboi lowo ara ilu

Ajo onina ijoba ti n je NEPA tele sugbon ti n je Power Holding Company nisisiyi ti gbero ati fi owo goboi le iye ti n gba lori ina lilo losoosu.

Eyi jeyo nibi arowa kan to pa si ajo ti se konkari  ina ijoba, National Electricity Regulation Cmmission (NERC) lati je ki oun (PHC) fi owo kun iye ti oun n gba lowo awon ti oje onibaara oun.

O se afikun owo lati bi i naira mefa fun odiwon ina lilo kan si nnkan bii naira mewaa si mejila.

Eyi ni pe nibi ti won ba ti n san nnkan egberun meji losu fun ina ijoba, won yoo maa san nnkan bi egberun mesan-abo si mejila.

Awijare ajo naa ni pe iye owo ti oun n san bayii fun ategun epo ti oun n lo ti gbowo lori. O ni iye owo it oun n san gbera fere lati nnkan bi egbeun merindinlogun milionu odiwon kan si nnkan bi ogbon milionu naira.

O ni yato si eyi, oun san ewa lenigba milionu naira (N210 milionu) fun ajo NERC..

O ni awon inawo wonyi ti je ki owo ti oun n na losoosu le si pelu nnkan bi eedegbefa milionu naira o din die (N657 m) le si iiye owo ti oun n san losu fun oniruiru enawo.

A o woye pe bi owo ti NEPA n gba lowo ara ilu

se n peleke si, bee ni o da bi enipe ise won n mehe si bi a ba ni ki a fi bi ara ilu se n ri ina  lo se.

Ni ibere odun to koja, egberun lona irinwo megawaati, eyiini odiwon ina,  ni o n ti ibi opo ina ajo naaa gbogbo jade si ara ilu lojumo bi tile je pe gbogobo ilu  niloo nnkan bii megawaati egberun lona mewaa.

Sugbon lati nnkan bi ipari odun to koja, eyi jo ajorehin gidi.  NNkan bi egberun megawaati lona igba pere ni ajo NEPA n fun ara ilu. Eyi lo fa lilo ti ina oba se maa n lo gbari lakoko yii.

Eyi lo faa ti opolopo awon ti ise won je mo ti ina ijoba se n gbe owo lewo bayii, afi bi won ba ra ero amunawa (jenereto) loku.

O si ni iwonba asiko ati iwonba ise ti jenereto le se mo.

Ilu Idiko ni Oba titun

Ni ehin-o-rehin, Akintaro gori aleefa

Ai ko ni emi irewesi, sise aforiti, kadara Olohun ori-inu eni ati iyipada to de si isakoso ijoba Ipinle Oyo ti mu Omowe Joshua Adewuyi Akintaro de ipo ye ko ti wa lati bi odun meji sehin.

Ipo yii ni ti alaga Ila Oorun Ibarapa.

Ao se iranti pe Akintaro lo ja ewe olubori nibi ibo ijoba ibile to waye ni ojo ketadinlogbon odun 2004.

Sugbon awon alagbara kan ko lati je ki o se ijoba. Idi pataki ti eyi fi waye ni toripe o je omo egbe Afenifere (Alliance for Democracy, AD). Se egbe Alaburanda (Peoples Democratic Party, PDP) ni n se ijoba ni Ipinle Oyo.

Nnkan bi oori eemetala ni Akintaro gba idajo are ni ile ejo. Sibe gomina ana, Sineto Rashidi Ladoja ko lati bura fun gege bi alaga.

Aibura fun alaga yii tile wa lara esun ti won fi kan gomina ana naa, ti o fi di pe  won roo loye.

Ibura fun alaga naa wa lara igbese ti gomina titun ni Ipinle Oyo, Otunba Christopher, Adebayo Alao Akala koko gbe, ni kete to gori aga gomina.

Tilu tifon ni awon eniyan ilu Idiko ati awon ololufe won gbogbo fi se ayeye iwuye oba titun fun ilu naa laipe yii.

Onidiko titun naa ni Alayeluwa, Oba Emmanuel Odebode Olaosebikan, Aferebiodan Keta.

Idile oye Aferebiodan ni oba titun naa ti wa. Ilu Eko lo si ti wa tele gege bi adasesi pataki kan ki o to di pe o gun ori ite.

Inu osu kesan-an odun  2004 ni Onidiko ana, Oba Joshua Ogunbode Oluronbi Keji  re ibi agba ma a n re. Eyi lo je ki awon afobaje ati awon ara ilu bere akitiyan ati yan Onidiko titun.

Olori afobaje to jawe oye le oba titun naa lori, Oloye Amsat Adegoke gba adura fun emi gigun, alaafia ati oore igbagbogbo fun Onidiko titun naa.

Bi ilu, ijo ati orin se n lo ni awon ara ilu n wari fun oba titun naa. Eni to saaju ni alaga igbimo ilu, Oloye  Ashiru Aderoju.

Nigba ti o n soro nibi ayeye naa, alaga ijoba ibile Iwajowa, Honerebu Yakubu Adebisi, eni ti igbakeji re, Honerebu Thomas Ogundele soju, so pe  idunnu gbaa lo je pe aga Onidiko to sofo di ohun ti oba titun gori re la i se itajesile.

O je eje ijoba lati fi owo sowopo pelu oba titun naa lati ri pe idagbasoke de ba ilu Idiko ati ijoba ibile Iwajowa lapapo.

Ara awon oba Oke ogun to peju-pese nibi ayeye naa ni Sabiganna ti Iganna, Oba David Atoyebi, Alokolodo II; Amunjio ti Ijio, Oba Gabriel  Adegoke;  Onitile ti Itasa, Oba Micheal Oyediran;  Alayegun ti  Ayegun, Oba Emmanuel Oyedepo Alao ati Gegun ti Ayetoro-Ile, Oba Lamidi Afolabi.

Lati itosi ati iwaju ni awon eniyan jankan-jankan ati wa sibi ayeye naa.

Onigbeti se ayeye odun meji lori aga

Ojo ketadinlogbon osu Kinni odun yii ni Onigbeti ti ilu Igbeti, Alayeluwa, Oba Oyekan Oyebisi Afasegbejo Keji pe odun meji lori ite gege bi oba.

Ojo isinmi to telee, tii se ojo kokandinlogbon ni kabiyesi se ayeye naa.

Ayeye yii bere pelu eto idupe lowo Eledumare ni mosalasi gbogbo ni ojo keedogbon. Awon elesin ibile naa ba Kabiyesi yo, nigba ti esin igbagbo waye ni ile ijosin anglikan to wa ni Oke Abe ni ojo ti a wi yii.

Lati ikoko ati ibaaba ni awon eniyan si ti wa sibi ayeye naa.

Lara awon oba alaye to wa sibe ni a ti ri Olokaka ti Okaka, Onisanmbo ti Ogbooro, Iba ti Kisi, Eleyinpo ti Ipapo, Alepata ti Igboho ati awon eni jankan jankan bee.

Die lara awon oba pataki pataki ni Oke gun

 1.  Okere ti Saki

 2.  Aseyin ti Iseyin

 3. Iba ti Kisi

 4.  Onigbeti ti Igbeti

 5. Are Sando ti Ofiki    

 6. Ajoriwin ti Irawo     

 7. Alepata ti Igboho     

8. Alado ti Ado-Awaye

9. Alamodu ti Ago-Amodu

10. Alawaye ti Awaye

11. Amuniji ti Ijio

12. Baale ti Okaka

13. Baale ti Sepeteri

14. Baale ti Otu

15. Baale ti Isemi-Ile

16. Baale  Komu

17. Baale   Igbojaye

18. Baale Ito ti Ofiki

19. Baale Agere ti Ofiki

20. Baale ti Igbope

21. Eleyinpo ti Ipapo

22. Elero ti Ilero

23. Onjo ti Okeho

24. Onigboho ti Igboho

25. Ona-Onibode ti Igboho

26. Onitede ti Tede

27. Aare ti Ago-Are

28. Onisanbo ti Ogbooro

29. Onilua ti Ilua

30. Oloje ti Oje-Owode

31. Sabiganna ti Iganna

Imaamu-agba ilu Sepeteri pa ipo da

Iba se pe a kii ku laye, a o ba ba Muhammed (s.a.w.) A o ba ba Muhammeda ni waka tabi orin ti awon Musulumi ilu Sepeteri n ko laipe yii latari ipapoda Imaamu agba ilu naa, Alhaji Hammad Gbadamosi.

Ojo kejidinlogun osu Kinni odun yii ni baba je Olohun nipe. Irohin to te wa leti so pe baba ko se aare ti. Se iku ko dajo, arun ko d’osu. Ki Oluwa Eledumare mase je ki a se aisan. ki Oba Alawurabi mase je ki a fi ojo olojo lo, ase.

A tile gbo pe Alhaji Gbadamosi yii kannaa lo siwaju irun ni ale ojo to fi wole sun ti ko ji si aye mo.

Ojo naa gan-an ni won si ti te baba si iboji ni ilana esin  Musulumi.

Se Oluwa ko dari iku jin enikookan.

E je ki won o ka wa tomotomo, tiletile nibi eto ikaniyan ti n bo yii

COIN fun awon omo Oke ogun l’ami eye

Yoruba bo, won ni eniyan yin-ni yin-ni k’eni se omiran. Bee gege ni oro yii ri laarin awon agbateru igbimo Egbe ti Idagbasoke Agbegbe Oke ogun je logun (Council of Oke ogun Indigenes, COIN) nigba ti won gbero lati yin awon omo agbegbe naa bii meloo kan lawo.

Gege bi alaga egbe naa, Amofin (Diakoni) J. Adeniji Ige se fi to onirohin Oloye Gbode leti, erongba egbe naa lati gbe igbese yii wa fun mimu ori awon eni ti oro kan ati awon miran naa ya.

“A gbero lati ye won si ki won le mo pe enikeni ko fi oju pa akitiyan won fun idagbasoke ile wa re rara. Se ku ise ni i mu ori osise ya. A fe ki awon eniyan mo pe  agbegbe Oke ogun naa ni awon eniyan to see mu yangan. Awon eniyan to ti kopa, ti won si n kopa nipa idagbasoke agbegbe wa ati ti orile ede yii. Koda a ni awon to je pe ki i se orile ede yii nikan ni owoja ise ribiribi ti won n se mo.”

 Amofin Ige so pe isori meta pataki ni awon ti o n gba eye nibi ayeye to n waye ni ilu Iseyin  pin si.

Akoko ni awon to ti sise fehinti lai ba oruko ile ati agbegbe Oke ogun ti won ti wa je.

Ekeji ni ti awon to ni igbega lenu ise won. Igbega nibi ise to laami laaka.

Iketa ni ti awon to kopa ribiribi nipa bi agbegbe Oke ogun se di ohun ti eniyan le mu yangan. Ti ko si pe oju a ti ni lati so pe ‘omo Oke ogun ni mi!’

Iwonyi ni oruko awon to gba ami eye nibi apero to n waye ni Ahoro Manor,eyi to wa ni ona to wo ilu Iseyin bi a ba n bo lati Ado Awaye.

Ojo kerin osu keta odun 2006 ni ayeye ati apero yii waye.

Oruko awon eni eye naa ni:

Olori Yetunde Gbadebo

Ojogbon Joshua Dada Adeniyi

Ajagunfehinti Amos Adedeji

Ojogbon Segun Gbadegesin

Baba A. F. Kilanko

Ojogbon Segun Odesina

Ojogbon (Iyaafin) F.A. Adeyoyin

Alagba Sanusi Adesope

Adajo-agba Olu Ariwoola

Oloye Adebisi Adesola

Ajagunfehinti A. B. Togun

Diakoni N.A. Oshin

Omowe Francis Ayandele

Alhaja Falilat Fitilayo Akande

Ojogbon D.A. Oyeleye

Ojogbon Yissau Kehinde Yusuf

Oloye J. Dayo Ayinla

Dokita Titi Ipadeola

Iyaafin (Oloye) Tayo Ogundare

Ogbeni Lade Bonuola

Ojogbon Peter Aborisade

Oloye Gboyin Alabi

Ojogbon A. Ilori

Omowe Silas O. Akinfenwa

Ogbeni Debo Adesina

Ogbeni Sunday Adelakun

Omowe John diran Olabisi

Oloye (Alhaji) Raji Bomodeoku

Oro Sunnukun

Ibo ni bilionu mejo owo epo wa ti Naijiria fi n jiya bayii?

Atejade kan lati odo ajo ti n gba owo wole fun ijoba apapo (Federal Inland Revenue Service) so pe billion mesan-an o din die naira (N878.6 billion) ni oun gba fun ijoba apapo lati odo awon ile-ise ti n wa epo ni Naijiria ni odun 2004 nikan.

O tun so pelu idunnu pe owo ti yoo wole fun odun 2005 ti a wa yii gege bi owo ori lati ibi epo bentiroo yoo je tirilionu meji abo o le die naira (N2.680 trillion). O ni eyi daju nitori pe ni osun merin akoko odun yii, oun ti ri oji le nirinwo bilionu naira (N402.99 billion) gba wole. Oun si ti san owo naa si apo ijoba apapo.

Ajo ti n se konkari epo oyinbo ni Naijiria wayii o (Nigerian National Petroleum Corporation, NNPC) kede pe igba bilionu o le mejidinlogbon ni oun n fi kun iye ti epo oyinbo n ba wa ki ile-epo gbogbo to le maa ta jala kan ni ogota aabo naira (N228 Billion). Ni osun mejila ti I se odun kan ni ajo NNPC n se iranwo owo ti a wi yii o.

Wayii o, bi a ba yo  bilionu 228 naira kuro ninu bilionu 878.6 naira to wole ni odun 2004, ijoba si tun ni owo goboi (650.6 bilionu) nile.

Ohun ti o n ko wa lominu ni pe ki ni faa ti ijoba ko le yo owo yii ninu owo ori ti n wole yii ki owo si wa ni nnkan bi naira meedogun fun jala kan? Se bi owo ori epo ti a wi yii ko ti i kan ere ti ijoba n ri lori epo to n ta ni abele ati eyi ti n ta si oke okun – paapaa julo ni asiko yii ti epo n ta bi kaasinnkan (d.d.r.m.d.r) ni oja agbaye.

A o tun woye pe owo odun 2004 to kere ni a tun lo nibi isiro ti a si soke. Bee ni o tun je pe owo ti a wi yii ko kan eyi ti ijoba n ri lati ona miran gbogbo. Afokansi awon eniyan ni pe ijoba to be ni ife awon ara ilu lokan yoo maa wa irorun awon omo orile ede ni – ki i se pe ki o maa gun le eto ti yoo maa mu inira ba ara-lu gege bi fifi owo le ohun amayederun.

Owo ti ijoba apapo labe akoso Aare Olusegun Obasanjo fi pamo si asunwon okeere (foreign reserve) bayii ti di bilionu metadinlogbon dola. ($27 billion). Eyi je tirilionu meta o le eedegbaarin ati ogorin naira (N3.780 trillion).

O dabi enipe ijoba ni dabi bale ti o feran lati ki ounje wa ni aka (d.m.) bi o tile fe ti ebi n pa awon omo inu abule. Ki ni ona abayo o, eyin omoran?

 

Awon omo Yoruba n se akin nibi igbekale irawo atowoda (Satellite)

Bi awon ti oro kan lagbaye se n se amujinle imo ofurufu ati anfaani to wa ni oju-orun (United Nations’ Week for Space Research and Benefits), o je ohun iwuri pe omo-bibi Oodua lati ilu Oka Akoko ni Ipinle Ondo, ile Naijiria, Ojogbon Robert Ajayi Boroffice wa lara awon ti a o ma ranyin oruko won laipe lojoojumo.

Idi abajo ni pe ajo ti Ojogbon Ajayi Boroffice n se oludari re ti a mo si Ajo Apapo ti n se awari-imo nipa Oju Orun ati Idagbasoke re (National Space Research and Development Agency, NASRDA) n ko oko oju-orun (Satellite) ti yo je akoko iru re ni ile alawodudu.

Eyi nikan ko. Oko oju-orun tabi Irawo Atowoda Nigeria-Sat 1 ti ajo yii n se agbateru re fun orile-ede Naijiria paapaa wa lara ona otun ti won fi se iwadii si isele iji lile-omiyale to waye laipe yii ni Amerika ti won pe oruko re ni Katirina ati Rita.

Se ni odun 1999 ni ajo agbaye (United Nations) ya ojo kerin si ojo kewaa osu Owara (4 – 10 October of every year) soto gege bi ojo amugbooro ipolongo imo oju orun.

Ojo ketadinlogbon osu Owawa, idunta (September 27, 2003) ni won se ifilole oko oju-orun yii ni Russia loruko Naijiria.

Ise pataki ni oko oju-orun ti a tun le pe ni irawo atowoda yii n se latari pe a le fi mo ese ti opolopo isele yoo gbe. Fun apere, odo nla to fe ya, igba ti ojo yoo ro ati ibi ti yoo ro si, bi ojo naa yoo se po to ati bee bee lo. Irawo atowoda yii tun le fi igba ati ibi ti oda yoo ti da, ibi ti ile yoo ti ri tabi oke ti yoo fo pelu bi yoo se fo han. Oko oju-orun yii tun le je ki omo adarihunrun mo ibi ti awon alumooni pataki wa ninu ile ati iru ewo ni. Lara anfaani ti irawo atowoda yii tun ni nipe o le se afihan ibi ti ogun ti n sele.

Gege bi apere, ikaniyan bawo-ni-yoo-se-ri (trial census) ti Naijiria se laipe yii fi ibi ti ile wa han. O tun le se iranwo lati mo iye awon eniyan to wa ninu ilu kookan.

Oko oju-orun Naijiria Akoko (Nigeria-Sat 1) yii je okan lara irawo atowoda ti n se iwadii ofo (Disaster Monitoring Constellation Satellite, DMC) eyi ti awon orile-ede bii meloo kan jo ni ajose le lori. Awon orile-ede yii ni Saina (China), Naijiria, Oljiria (Algeria) Toki (Turkey) ati Ile Geesi (United Kingdom).

Aare Olusegun Obasanjo pa ase meji pataki fun ajo ti Ajayi Boroffice n dari. Ekinni ninu ase meji yii ni pe orile-ede wa gbodo le se irawo-atowoda tire o pe ju titi osu kejila odun ti n bo. Ase keji ni ti pe omo Naijiria gbodo le maa fo ni ofurufu ni ona ti ode oni (astronaut) ki a to ri odun mewaa si oni – eyiini titi odun 2015.

Ajayi Boroffice fi n daniloju pe erongba Aare yo se lona mejeeji. O so pe oko oju-orun keji fun Naijiria (ti yoo je akoko ti o se funraare) yoo gun oju orun ki odun ti n bo to pari lagbara Eledumare. O fi kun pe ki a to ri odun mewaa si oni, omo bibi Naijiria yoo ti maa ba awon oyinbo fagagbaga ni oju orun.

Lowo bayii, ojilenirinwo milionu dola ($440 million) ni owo ti Naijiria n ri lati ibi irawo atowoda to ni soju orun. Awon orile-ede Afrika ti won n je anfaani oko naa ni won n san owo naa gege bi owo eya.

Ojogbon Gabriel Ajayi ati Abimbola Alale naa wa lara awon omo Yoruba to n se gudugudu meje nidi ise irawo atowoda ati imo ayelujarawon yii. Oke oke ni omo Yoruba ati orile-ede Naijiria yoo maa lo, ase.

Ijoba Oyo yoo bere sisin eran Efon nitori wara (miliiki)

Gomina Rashidi Ladoja ti Ipinle Oyo ni orile-ede Naijiria ti kede pe ijoba oun yo bere osin efon (buffalo).

Gomina to so oro yii ni ilu Ibadan so pe ijoba oun n dawole osin eranko yii latari wara to po lara eran naa. O ni gege bi iriri lati ile India se fi han, jala wara olomi mefa ni efon (r.d.) kan n pese lojumo nigba to je pe jala meji pere ni maalu n pese lojumo. Maalu ni eran ti awon eniyan n sin pupo fun eran jije ati wara ti won n ri ni ara re.

Eran osin bi ewure paaapaa a maa pese wara, sugbon ti maalu lo po ju. Ni bayi sa, awon alase ti so pe efon yoo di sisin latari ati se alekun wara ti awon omo ipinle Oyo ati orile-ede Naijiria yoo ma ri lojumo.

Wahala sele ni ilu Ilorin

Fun bi ojo merin ni osu Owawa to koja (September 25 –29, 2005), ekun, ipohunkeke ati ofo ni o gbode kan ni agbegbe Idi Ape ni ilu Ilorin ti i se olu-ilu Ipinle Kwara.

Idi abajo ni ti ile jijo ati eniyan pipa to waye ni agbegbe naa latari ede aiyede to be sile laarin Eemia (Emir) ilu Ilorin ati awon afobaje meta ni ilu naa. Ija ti a wi yii gbona debi pe olopa olokun kan (corporal) Obatayo Obatoke ba isele naa rin nigba ti awon emi bii mewaa miran naa tun je Olohun nipe.

Ni pato, talo ni ase lati yan eniyan si ipo Mogaji Are ilu Ilorin lo fa yanpon-yanrin yii. Lehin ti Mogani ana, Alhaji Lawal Alasa gbe’se, idile fa Alhaji Saadu Sulaimon kale gege bi Aare titun. Gege bi asa, won we lawani fun Mogaji Are titun na ni ojo kerinlelogun osu Owawa (24/9/2005).

Sugbon Eemia (oba) ilu na fi elomiran, Alhaji Shuaibu Zubair je oye yii kan naa ni ojo keji. Ibi ti Alhaji Zubair ti n jo bo wa sile ni ija ti be sile laarin awon omo ehin re ati awon omo ehin Alhaji Sulaimon.

Ile Gomina ana ipinle naa, Alhaji Muhammed Lawal fara gba ninu isele buruku yii, tori pe won so ina si ile naa, ati ibi ti baba re to je Mogaji Are to gbese fi se aafin.

Awon idile n so pe awon lo ni ase lati yan Mogaji Are. Won ni ohun to kan Eemia nibe ni ki awon fi oro naa to leti ki o si fi ase si. Mogaji Are lo duro gege bi oba awon Yoruba ni ilu Ilorin.

Ohun ti n da howuhowu sile bayii ni ipilese ni bi igba odun sehin. Eyi ni igba ti Aare Ona Kakanfo kefa ti yoo je ni ile Yoruba ni igba naa ti oruko re n je Afonja Layalopo (m.d..m.d)  da ase Alaafin igba naa, Aole koja. Aigboran yii mu ki Alaafin Aole Aroganganloye gbe ogun dide lati tako Bode (oruko ti Ilorin n je nigba naa). Afonja be olori awon Hausa-Fulani ti n gbe ilu naa, Alufaa Alimi fun atileyin. Pelu atileyin awon Hausa-Fulani yii, Afonja segun awon omo-ogun Aole ti i se Alaafin kokanlelogbon ti yoo je ni Oyo. Sugbon Alimi pada yegi fun Afonja funraare, o si gba ijoba lowo re. Lati igba naa ni akoso ijoba Ilorin to bo sowo awon Hausa-Fulani.

Ilu Sokoto ni Oke Oya ni ase si ti n wa nigbakugba ti won yoo ba je Eemia titun. Bayii lo se je iran awon Gambari lo n joba nibe titi di oni.

Sugbon lati nnkan bi odun meloo sehin, awon ogidi Yoruba ti n gbe igbese lati so Ilorin di ara ile Yoruba ponbele. Ona kan pataki ti won n gba lati se eyi ni jije oba. Won so pe oba ni won n je ni ile Yoruba ki i se Eemia (Emir). Atipe awon iran Afonja to (to wa ni Idi Ape lonii yii) lo ye ko ma je oba naa. Awon ni won n je Mogaji Are.

Eni ti yoo je oye yii ni n da rogbodiyan sile lowo bayii. Awon omo ile n fe Sulaimon nigba ti Eemia si fi Zubair je. 

Se bi ojo meloo sehin, Eemia ti Ilorin, Alhaji  Sulu Gambari ro awon afobaje meta loye. Awon meteeta naa ni Alhaji Abdul Kareem Buhari ti i se Baloogun Gambari, Alhaji Shuaibu Mahmud ti i se Baloogun Alanamu ati Baba Isale ti ilu Ilorin, Alhaji Saka Alesinloye.

Awon Oloye meta yii so pe awon naa ro Eemia naa loye. Iwadii fi han pe ohun to wa ni isale riro ara eni loye yii ni oro owo ninu.  Eyi jeyo ninu iwe ehonu ti awon Oloye meta yii ko si Aare Olusegun Obasanjo ninu osu keje odun yii. Won so ninu iwe ehonu won naa pe Eemia n jokoo le owo ti n wole ti o si ye ki gbogbo awon Oloye letoo si.

Awon kan ni igboro n woye pe ija ti o sele naa ni owo oselu ninu. Won so pe iromi ti n jo fun awon to n da ranpon-yanrin sile n be labe omi.

Gomina atijo, Muhammed Lawal tile fi esun  kan pe Gomina Bukola Saraki to wa lori aleefa bayii  lo ran won pe ki won wa sun ile oun. Sugbon agbenuso fun ijoba Ipinle naa, Alhaji Raheem  Adedoyin ti i se komisanna fun Eto Irohin ati Oro Abele so pe ko si ododo ninu oro ti Lawal so.

Ajodun Olokun Omidan Olokun yoo gba moto ayokele kan

Igbese n lo lowo lati ri pe Ajodun odun Olokun ti odun yii kese jari.

Ojo kokandinlogun osu Belu  (19/11/2005) ni ajodun naa yoo waye.

Irohin to te AfonrereYORUBA lowo fi han pe ajodun odun yii ni yoo je eleekarun-un iru re.

Ajo Oodua (eka ti Gani Adams) ni o n se agbateru ajodun naa lati bi odun mefa sehin ti eto naa ti bere. Lara eto ti yoo tun waye nibe ni gbigbe ade le Omidan Olokun lori. Eyi je ara eto lati ri pe ajodun naa fanimora.

Moto ayokele ni eni ti o ba jawe olubori gege bi Omidan Olokun yoo gba. Eni to ba se ipo keji yoo gba eedegbejo naira (N150,000) nigba ti eni to ba se ipo keta yoo gba oke marun-un naira (N100,000).

Arabinrin Nneka ti o wa lati ile Yibo ni o gba ade naa lodun to koja. Akekoo eko esebi-oogun (Kemisiri, Chemistry) ni arabinrin naa je ni ile-eko giga Fasiti Eko (UNILAG).

Awon iko omolehin Olokun (Yemoja) lati ipinle bi Edo, Delta, Ebonyi, Abia, Imo, Anambra yoo dara po mo awon elegbe won ni ile Yoruba. Lati ipinle Eko, Oyo, Ogun, Ondo, Ekiti, Osun, Kogi ati Kwara ni won yoo ti kopa nibi ajodun naa.

 

 

 

 

Epo tun gbowo lori: Omo Naija r'ogo  Obj tun gbe ajaga nla le omo Naijiria lori

 

Inu’fo aya’fo ni awon omo orile-ede yii wa bayii nipa pe won ko le so paato igba ti won yoo bo lowo ajaga alekun owo epo nigba gbogbo  eyi ti o ti di baraku lenu igba ti Ajagunfehinti Olusegun Obasanjo di Aare orile-ede yii.

Se lenu odun mefa ti Aare Obasanjo ti di aare orile-ede yii, o ti di igba meje ti o ti fi owo le epo.

A o se iranti pe ogun naira (N20) ni jala epo wa ni odun 1999 ti Obasanjo ati awon emewa re gba ijoba.

Ni bi a se n soro yii, o ti gbe owo jala epo kan de ogota o le marun-un. Aadorin naiara ni opolopo n ri epo naa ra.Ojo kerindinlogbon osu yii ni awon ti n ra epo de ile epo ti won ri pe jala epo ti gbera lati aadota naira si aadorin naira.

Ariwo ta, awon eniyan si n fi ehonu han.

Lehin eyi ni ajo ti n diye le owo epo (PPRA) se ipade ti o si se ikilo pe awon ti n ta epo ko gbodo ta epo ju ogota o le marun-un naira  lo.

Ohun ti o tun wa n je ikaya fun ara ilu ni oro ti n jade lati odo ajo ti n se konkari epo inu ile ni Naijiria (Nigerian National Petroleum Corporation, NNPC) ti o so pe o see se ki owo epo tun le si laipe latari owo ti epo tun gbe lori ni oja agbaye.

Irohin to kan ara ilu ku ni ojo’Ru so pe jala epo robi kan ti di aadorin o le’kan dola ni oja agbaye.

Bi epo ba si ti gbowo lori bayii ni oja agbaye ni awon alase ni ile Naijiria naa ma a n gbe owo le iye ti awon ara ilu gbodo ra epo naa ni ile yii.

Bee si ni goboi ni owo ti ijoba n ri lati ibi ekunwo yii. Sugbon awon omo Naijiria ko ni ori ki awon olori won lo ekunwo yii fun idagbasoke ati ifokanbale awon ara ilu. Kaka bee, ajekun iya ni alekun owo yii n mu wa fun awon to wa ni orile-ede ti o je pe oun  ni o wa ni ipo kefa lara awon ti n wa epo ni gbogbo agbaye.

Eyi waye latari ikede re lose to koja pe ijoba n padanu owo to ju milionu mefa losoosu nitori iye owo ti o n ta epo kere jojo si iye ti oun fi n gbe epo naa wole lati oke okun.

Irohin to te Oloye Gbode lowo se afihan re pe jaala epo bi i milionu merinla 14 milion barrels) ni Naijiria n pese fun lilo labele. Sugbon eyi ko to iye ti a nilo. Nipa bayii, ijoba fi aye sile fun gbigbe jaala milionu merindinlogun (16 million barrles) wole lati oke okun. Eyi fi han pe nnkan bi ogbon jaala (30 million barrels)  epo ni a n lo losu ni ile Naijiria.

Lowo bayii, nnkan bi i dola  mokanlelaadorin  (nnkan bi N9,585) ni won n ta jaala epo tutu (crude oil) kan ni oja agbaye. Epo tutu  ni eyi ti ijoba Naijiria ati awon oloko-owo nlanla n wa ninu ile wa ti won si n ta ni oja agbaye. Epo tutu yii ni won maa n fo ti won yoo yo awon eroja epo gege bi kerosinni, epo ti moto n lo, girisi, ike ati beebeelo nibe. Giga soke ti owo epo tutu je ni oja agbaye yii ni ijoba apapo - nipase ajo NNPC  - fi fe gbe owo le iye ti won n ta epo fun ara ilu. Sugbon ijoba ati ajo re ko mu enu ba ekunrere owo goboi  ti o n ri gba latari owo ti o gori iye ti  n ri gba nibi tita epo wa si oke okun.

O n se awon eniyan ni kayeefi pe o dabi enipe ijoba yii feran ati ri pe nnkan nira fun ara-ilu. Ohun to mu won so bee ni pe bi epo ba won, nnkan gbogbo naa ni yoo gbe owo lori ni igboro. Fun apere, iru nnkan ti ara ilu n ra ni bi i naira mewaa tele ni o n di bii naira meedogun si ogun naira ni kete ti nnkan bii naira marun-un si mewaa ba ti gun iye ti won n ta epo.

Nigba ti won n ba Oloye Gbode soro, Ogbeni Ebika Anthony, Ogbeni Moshood Erubami, Ogbeni Wale Oladele ati Oloye Nathaniel Owoade to ba onirohin wa soro ke si ijoba pe ki o mu lara ekunwo ti o n ri lati ibi epo ti n ta si ita fi kun iye ti yoo san dipo ti yoo fi tun ni ki ara ilu wa san ekunwo fun epo ti won n ra.

“Inira ti po ni ilu tele. Fifi owo kun iye ti ara ilu n ra epo yoo tubo mu ki nnkan gboro si ni. Awon ijoba orile-ede yoku ti a mo maa n ko di ohun gbogbo to ba le mu ki ara ni awon eniyan won ni. Sugbon o da bi enipe ijoba tiwa nibiyi feran lati  maa gbe igbese ti n di ajaga to wuwo le awon eniyan lori”

Owo ti Naijiria ni ninu asunwon ti n ko owo to ri gba lati oke okun si le ni bilionu metala dola ($13 Billion). Milionu lona milionu ni bilionu kan. Bilionu dola je tirilionu naira. Owo goboi gbaa ni eyi je. Iye ti a wi yii ko kan iye ti n wole fun ijoba apapo lona miran gbogbo. Sibe afi ki owo epo maa lo soke loorekoore lo dabi enipe o je ijoba yii logun.

O ti to bi igba meje bayii ti ijoba ti Ogagun Olusegun Obasanjo n se akoso re ti fi owo le iye ti won n ta epo lorile-ede yii lenu igba to gori aleefa.

Arun sobia yoo dopin ni Ipinle Oyo

Gomina Rashidi Adewolu Ladoja ti Ipinle Oyo ti so pe arun sobia yoo di ohun ti ko ni gbori mo rara ni Ipinle Oyo lati nnkan bi odun meji si asiko ti a wa yii.

Ilu Ibadan ni gomina ti so oro yii lojo’Ru to koja nigba ti n gba alejo olori orile-ede yii nigbakan ri, Ogagun Yakubu Jack Gowon.

Gomina Ladoja gba alejo Gowon eni ti o siwaju iko ti n se konkaari bi arun sobia ko se ni i yo wa lenu mo ni orile-ede wa.

Global 2000 ti n doju ija ko sobia  ni oruko ti ajo ti Gowon lewaju re yii.

Ajo naa se abewo si ijoba ibile meji ti arun yii ti n fi oju awon eniyan gbole ni Ipinle Oyo.

Awon ijoba ibile naa ni Oorelope ati Ariwa Ibarapa.

Ni Ibarapa ati Igboho, Gowon ati awon ti won jo kowo rin be awon agbegbe ti arun yii ti n soro wo.

Olori orile-ede yii tele naa si fi iwuri han latari igbese ti awon ijoba ibile ti a wi yii n gbe lati ri pe arun buruku yii ko yo awon eniyan lenu mo.

O kan saara si ijoba ibile Oorelope fun kangan gidi ati kangandero ti ijoba naa gbe fun awon eniyan ti o wa ni abule ti arun sobia ti gbogo.

O tun gbe osuba fun awon ijoba ibile mejeeji ati ijoba ipinle Oyo fun eto ilera lati ri pe arun yii ko di eyi ti n ja kale.

  Gomina Ladoja fi idi re mule pe ni ibere odun yii ti oun fi eto pataki lele lati doju ija ko arun sobia ni oun ti so pe opin yoo de ba arun naa ni ipinle yii o pe ju titi odun 2007, eyiini, odun meji si asiko ti a wa yii.

Alaga ijoba ibile Oorelope, Aposu Agba Sunday Adeola fi imoore ijoba re ati ti awon eniyan ijoba ibile naa han fun afisokan ajo Global 2000.

O ni o je nnkan iwuri pe ajo naa mu eto ilera awon eniyan ni okunkundun.

O si fi idi re mule pe ijoba oun ko ni te ti lati ri pe ilera awon eniyan je nnkan ti won ko fi owo yepere mu.

Gomina Ladoja se apeje pataki fun Ogagun Gowon ati awon emewa re ni ile ijoba to wa ni Agodi.

Opo iranbwo ni ajo na se adehun lati se fun awon adugbo ti arun sobia ti n ba won finra.

Odo Oke ogun yoo se idanilekoo

Idanilekoo olodoodun ti Egbe OYCOF maa n se yoo waye ni 24/9/2005.

Ile Asa Ibile, Cultural Centre, Mokola, Ibadan ni yooo ti waye. Oludanilekooo ni Ojogbon Dibu Ojerinde, Oludari ajo ti n se eto idanwo NECO. Ago mewa owuro ni yoo bere. Gbogob eniyan la pe.

 

Intaneeti wo ilu Igbeti

A dupe Oluwa, a dupe Eledumare ni gbolohun ti n ti enu awon eniyan jade ni ibere osu kejo odun ti a wa yi.

 Iredi ope yii ni ti sisi ero itakun agbaye ti won n pe ni Intaneeti ni ilu naa.

Ohun meeriyiri ni intaneeti yii je ni gbogbo agbegbe naa.

Se ni gbogbo agbegbe Oke ogun, Ilue Saki nikan ni anfaani yii wa.

Alayeluwa, Alepata ti ilu Igboho Oba Johnson Oyeyiola ni o si ile-ise naa nigba ti Onigbeti ti ilu Igbeti je olugbalejo pataki nibe.

Alepata gbe osuba nla fun Omo-oba Oluwasina Oyebisi ti o je oludari ile-ise ti a wi yii.  fun ogbon-inu, oye, laakaye ati ife ilu eni ti  o ni; eyi ti o je ki o wa si ile-ise naa si ilu Igbeti.

Kabiyesi ro tonile telemu lati fi ti Sina se awokose.

 Nigba ti oun naa n  soro nibi ayeye naa, Honerebu Olumuyiwa Ojekunle ti n soju agbegbe Irepo/Olorunsogo ni ile Igbimo Asojusofin Ipinle Oyo so pe ohun moriya ni  igbese pataki yii je fun Igbeti ati agbegbe re.

O gba adura pe iwaju ni opa ebiti oludari ile ise naa ati ti ilu Igbeti yoo maa lo.

Awon to wa nibe gbogbo lo dupe pe iru nnkan idunnu bayii se oju awon.

Won ni ire nlanla ti bere si i wo ilu pataki naa lenu igba ti Oba Oyekan Oyebisi gori aga gege bi Onigbeti, Afasegbejo Keta.

Pelu Intaneeti yii, ibikibi ni eni to wa ni Igbeti le rannse si kaakri agbaye, ibikibi ni oun naa si ti le gba ise. Bakannaa awon to n se idanwo bi i ti WAEC, NECO, JAMB ati beebee lo ko ni lati lo si Ogbomoso, Ilorin, Ibadan  ki o to di pe won mo bi oro ti n lo.

Opolopo iwadii ni a tun le se lori intaneeti.

Epo yoo tun gb'owo lori

Lati N52 si N63

Ajo ti n se konkari epo inu ile ni Naijiria (Nigerian National Petroleum Corporation, NNPC) ti n ko aya awon ara ilu soke nipa ete re lati tun fi owo goboi kun iye ti won n ra epo oyinbo. O fe gbe owo jaala epo kan lo soke lati naira mejilelaadota (N52) si metalelogota (N63).

Eyi waye latari ikede re lose to koja pe ijoba n padanu owo to ju milionu mefa losoosu nitori iye owo ti o n ta epo kere jojo si iye ti oun fi n gbe epo naa wole lati oke okun.

Irohin to te Oloye Gbode lowo se afihan re pe jaala epo bi i milionu merinla 14 milion barrels) ni Naijiria n pese fun lilo labele. Sugbon eyi ko to iye ti a nilo. Nipa bayii, ijoba fi aye sile fun gbigbe jaala milionu merindinlogun (16 million barrles) wole lati oke okun. Eyi fi han pe nnkan bi ogbon jaala (30 million barrels)  epo ni a n lo losu ni ile Naijiria.

Lowo bayii, nnkan bi i dola marun-un le laadota (nnkan bi N7,975) ni won n ta jaala epo tutu (crude oil) kan ni oja agbaye. Epo tutu ni eyi ti ijoba Naijiria ati awon oloko-owo nlanla n wa ninu ile wa ti won si n ta ni oja agbaye. Epo tutu yii ni won maa n fo ti won yoo yo awon eroja epo gege bi kerosinni, epo ti moto n lo, girisi, ike ati beebeelo nibe. Giga soke ti owo epo tutu je ni oja agbaye yii ni ijoba apapo - nipase ajo NNPC  - fi fe gbe owo le iye ti won n ta epo fun ara ilu. Sugbon ijoba ati ajo re ko mu enu ba ekunrere owo goboi ti o n ri gba latari owo ti o gori iye ti  n ri gba nibi tita epo wa si oke okun.

O n se awon eniyan ni kayeefi pe o dabi enipe ijoba yii feran ati ri pe nnkan nira fun ara-ilu. Ohun to mu won so bee ni pe bi epo ba won, nnkan gbogbo naa ni yoo gbe owo lori ni igboro. Fun apere, iru nnkan ti ara ilu n ra ni bi i naira mewaa tele ni o n di bii naira meedogun si ogun naira ni kete ti nnkan bii naira marun-un si mewaa ba ti gun iye ti won n ta epo.

Ninu oro re, Oloye Nathaniel Owoade to ba onirohin wa soro ke si ijoba pe ki o mu lara ekunwo ti o n ri lati ibi epo ti n ta si ita fi kun iye ti yoo san dipo ti yoo fi tun ni ki ara ilu wa san ekunwo fun epo ti won n ra.

"Inira ti po ni ilu tele. Fifi owo kun iye ti ara ilu n ra epo yoo tubo mu ki nnkan gboro si ni. Awon ijoba orile-ede yoku ti a mo maa n ko di ohun gbogbo to ba le mu ki ara ni awon eniyan won ni. Sugbon o da bi enipe ijoba tiwa nibiyi feran lati  maa gbe igbese ti n di ajaga to wuwo le awon eniyan lori"

Owo ti Naijiria ni ninu asunwon ti n ko owo to ri gba lati oke okun si le ni bilionu metala dola ($13 Billion). Milionu lona milionu ni bilionu kan. Bilionu dola je tirilionu naira. Owo goboi gbaa ni eyi je. Iye ti a wi yii ko kan iye ti n wole fun ijoba apapo lona miran gbogbo. Sibe afi ki owo epo maa lo soke loorekoore lo dabi enipe o je ijoba yii logun.

O ti to bi igba meje bayii ti ijoba ti Ogagun Olusegun Obasanjo n se akoso re ti fi owo le iye ti won n ta epo lorile-ede yii lenu igba to gori aleefa.

 

'Yoruba, e se ara yin lokan'

Awon omo Yoruba nile, loko, lodo ati lehin-odi ni won ti ke si pe ki a ye ri ara wa gege bi Ekiti, Ijesa, Egba, Oyo ati beebee lo. Kaka bee, ki a ri ara wa gege bi iran kan soso ti o se lati ara Oduduwa.

Ojogbon Niyi Osundare lo pe ipe yii lojo Bo to koja nigba ti n fesi si oro ti Oloye Gboyega Mabinuori Latoosa so.

Ibi ayeye ti won fi n se imoriri ipo titun ti ijoba ipinle Oyo yan Ojogbon Akinwunmi Isola ni itakuroso yii ti waye. Mabinuori, ti i se Arole Aare Latoosa so pe Ibadan ni olu-ilu Yoruba latari pe ilu naa lo ti je olu-ilu agbegbe iwo oorun atijo (western region). Ati pe ilu naa lo ye ki gbogbo Yoruba maa wari fun lojo gbogbo.

Sugbon Osundare ti i se ogbontagi akewi ti o niyi kaakiri agbaye ni oro ko ri bee. O gba pe ilu Ibadan ti n ko ipa pataki  ni ile Yoruba ati ni orile-ede Naijiria. Koda ilu naa ko ipa to joju nipa gbigbe ile Afrika lori soke. Apere ni ti ero mohunmaworan (telifisan) to je ibe lo koko sole si ni gbogbo ile Alawodudu.

Osundare so pe bi o tile je pe looto ni pataki ilu Ibadan latari awon nnkan ti a wi yii ati omiran, sibe ohun ti o ye ki a maa fi okan ro, ki a si maa sise le lori bayii ki i se ilu wo lo ju ilu wo lo.

"Bi a o se dagba soke lapapo lo ye ki a maa sanna re, ki i se bi ilu kan se ju ilu kan lo."

Bi igba ti awon omode n sere ni oro wa yoo da bi ohun ti o n je wa logun ni ilu wo lo ju ilu wo lo dipo ki a maa soro lori ona wo ni a o se gbori soke ninu ohun meremere ti a fi n se aye ode oni ati ti ola.

Egbe osere Ebiks Tiata lo se agbateru ayeye iwuri fun Isola ti a wi yii. Ninu oro ikini kaabo re, Otunba Bayo Adebowale ti i se oludari ile-iyawekawe igberiko ajogunba ile Afrika (African Heritage Research Library) so pe ise takuntakun ni Isola n se. O ni oruko re wa lara awon omo ile Afrika meje ti oun gba pe won yoo gba ami eye Nobel laipe ojo. Lara awon to tun da oruko won ni Chinua Achebe,  Ngugi wa Thiongo, Femi Osofisan, Nurudin Farrah, Niyi Osundare.

Oludari Ebiks Tiata, Ogbeni Ebika Anthony so pe oun se agbekale ayeye naa fun idi meji pataki. Akoko, lati fi iwuri wa han fun yiyan ti ijoba yan arakunrin naa gege bi alaga igbimo ti n se amojuto ajo agbasaga ipinle Oyo (Oyo State Council for Arts and Culture). Eekeji, lati je ki alaga naa mo pe awon to wa ni idi asa ati ere idaraya wa lehin re. Ireti wa si ni pe ko ni ja wa ni tanmaa.

Adari-eto lojo naa, Ogbeni Jare Ajayi so pe ohun edun-okan lo je pe owo yepere ni awon to n dari ijoba fi n mu ohun to je mo ise ati asa wa. Eyi naa ni won gbe de ibi eto eko ti won (ijoba) dagunla re. O pe ipe fun ayipada.

Komisan-na Oyinloye Faniran eto irohin ati asa  to wa nibe se ileri pe ijoba ipinle Oyo ti setan lati se igbende asa Yoruba.

Lara awon otookulu to tun wa nibe ni Alhaji Adegboyega Arulogun ti oun naa ti je komisan-na ni ipinle Oyo ri, Yeye Akilimali Olade Funnua, Ogbeni Laolu Ogunniyi, Iyaafin Ayo Adeyemi, Ogbeni Alade ti i se oludari eka asa ni ile-ise eto irohin ati asa labe ijoba ipinle Oyo, Dokita Tony Marinho, Dokita Duro Adeleke, Dokita M.A. Adeeyo, Ogbeni Mashood Folorunso, Ogbeni Rotimi Babatunde, Iyaafin Yinka Owolabi ati bee bee lo. Aya Akinwunmi Isola, Bolatito paapaa wa nibe.

Osundare gbayi ni Pariisi

Ayeye pataki kan ni ajo UNESCO se fun onkowe omo Naijiria kan, Ojogbon Olaniyi Osundare lenu loolo yii ni ilu Pariisi.

Iredi ayeye naa ni kiko jade iwe ewi re ti won sese tumo si ede Faranse.

Awon eniyan jan-n-kan jan-n-kan kaakiri agbaye ni won wa nibe. Paapaa julo awon asoju ijoba olorijori, awon onkowe, awon akewi, awon ontewe ati awon osere.

Ogbeni Yemi Lijadu lo se agbateru ayeye naa. Ayeye naa je iwuri fun oga agba kan ni UNESCO ti o je omo ile Yoruba, Ojogbon Micheal Omolewa.

Nigba ti o gbo pe ile Amerika ni awon onkorin -binrin Lijadu (Lijadu Sisters) ko lo, Osundare kedun pe orile-ede Naijiria maa n dagunla awon to n fi ogbon-inu ati oju-ona gbe nnkan jade lati gbe asa ati orile-ede naa laruge.

A o se iranti pe orin awon Lijadu Sisters ti a wi yii je agbo-gbadun fun opolopo odun ni bi odun meedogbon si odun mejila sehin.

Nibi ayeye ti Pariisi yii, ko si asoju ijoba Naijiria nibe, bi o tile je pe asoju awon ijoba orile-ede miran wa nibe.

Niyi Osundare di eni ti aye mo nipa awon ewi arojinle ti n ko.

Lara awon iwe re to ti fi gba ami eye kaakiri agbaye ni Eye of the Earth, Midlife, Moonsongs ati bee bee lo.

Ile Eko Giga Yunifasiti Ibadan ni o ti n sise oluko. Sugbon aigbora-eni-ye laarin onkowe naa ati awon oludari ile eko giga naa nipa idi pataki kan ti Osundare fi ni lati maa lo si oke okun ni ida kookan mu ki ojogbon naa o fe fi ise sile.

Koda ni ipari osun yii ni yoo ka iwe apilekoo idagbere (Valedictory Lecture) ni ile eko Yunifasiti ti a wi yii.

Lenu ojo meta yii, opolopo awon ojogbon ti imo ati iriri won se koko lo ti di pe won ni lati fi ile eko giga Fasiti Ibadan sile fun idi kan tabi omiran. Lara won ni Ojogbon Dapo Adelugba, Ojogbon Dan Izevbaye, Ojogbon Isidore Okpewho ati bee bee lo.

 Elesin Abalaye yoo se Ipade Gbogbogboo ni Brasiili

Akojopo Egbe Elesin Ibile Kaakiri Agbaye yoo ko ninu osun kejo odun yii.

Ilu Rio de Janairo ni orile-ede Brasiili ni apaero naa yo ti waye. Eleekasan-an iru re ni apero olodun meji meji yii yoo je.

International Congress of Orisa Traditional Culture ni oruko ti won n pe egbe elesin ibile naa.

Ipenija ti esin ibile Yoruba n koju kaakiri agbaye ni apero naa yoo gbe yewo, ati ona ti awon omo egbe se le koju awon ipenija naa.

Irohin to te Afonrere lowo so pe awon olufokansin esin Yoruba to aadorun-un  (90 million worshippers) kaakiri agbaye. Eyi ni awon ti n bo Orisa olorijori to je pe ile Yoruba ni orirun awon Orisa naa ti se. Irufe awon Orisa wonyi ni Sango, Obatala, Yemoja, Ogun, Bantuque, Santeria, Voodoo ati bee bee lo.

Awon orile-ede ti awon esin yii ti gbile ni Brasiili, Kiuba, Trinidad ati Tobago, Haiti, Jamani, Ile Geesi ati Amerika pelu Naijiria.

Ewu ti n se yo ni ile Naijiria

Ewu n be loko Longe, Longe paapaa, ewu ni. Eyi ni o se alaye nnkan ti n lo lowo ni orile-ede Naijiria latari idunkooko ti n waye lati enu awon odo to wa ni agbegbe esekuku-odo Oya (Niger Delta).

Oro ijaya yii ko sai se lori ihale awon odo ti a wi yii pe bi awon ti n se apero ni Abuja ko ba gba ki awon maa gba ida kan ninu merin ninu owo ti n wole lori alumooni ile awon, sunmomi lo ku ti awon yoo maa gbe.

Sunmomi iru eyi ti won n wi yii aseku'pani ni (suicide bombing). Idi ni pe eni ti yoo gbe sunmomi naa ko ni i ko bi oun paapaa ba ku nibi ti o ti lo se iku pa 'awon ota' ti n gbegi dina ohun ti won n ja fun. Awon omo Larubawa ni won n se iru nnkan bayii julo, paapa lenu igba ti oro ija Palestine ati Isreli bere. Eyi tun le koko si lenu igba ti Amerika so Iraaki (Iraq) di amusere won. Awon ajijagbara a so ado-iku (bombu, bomb) mo'ra tabi ara moto. Won a lo si awujo awon ota ti won fe se lose. Gbau! ado iku yii a dun, a si pa opolopo eniyan, nigba ti opo a fi ara pa.  Eyi gan-an lo fa igbe ti awa n ke bayii. Ohun to dara ni ki sunmomi ma bere. Bi o ba ti bere, ki i mo enikan. Adura wa ni Afonrere ni pe ki awon ti oro kan tete wa nnkan se si oro to wa nile, ki o mase buru de ibi pe sunmomi gbigbe yoo wo Naijiria. Lowo bayii, a ni opo nnkan ti a n ba yii ju pe ki a tun da omiran kun.

Ni ipari ose to koja ti i se ibere osu keje odun 2005 ni awon eni ti a wi yii se ipade kan. Iredi ipade naa ni aigbo-ara-eni ye ti o sele nibi apero  apapo ti ijoba seto re ni ilu Abuja. Ninu oro ti Arabinrin Hilda Dokubo ti i se agbenuso won so lehin ipade naa ni awon odo yii ti fi igbaradi won han lati bere sunmomi gbigbe bi awon ara Aarewa ba ko jale lati je ki awon ese-kuku fi owo mu ida kan ninu ida merin oro won, gege bi apere ti n jade nibi apero Abuja se fi han - eyi ti o da aigbora-eni ye sile.   Aigbora-eni ye yii sele latari owo oya ti awon esekuku-odo Oya n beere fun, eyi ti awon asoju lati apa Aarewa so pe faabada, eyi ko gbodo waye!

Se awon esekuku-odo Oya n beere fun idaji owo ti n wole lati ibi alumooni ti n jade lori ati labe ile won. Ariwo so nibi apero yii nitori awon kan - paapaa awon ara Oke Oya - fi aake kori pe agbedo! Eyi lo fa pentuka to waye nibi apero naa. Ojo kokanla osu keje ni won tun fi ipade si. Sugbon olukaluku omo Naijiria lo mo pe laala yoo lu bi ipade naa ba tun ko.

Idi ni pe ida metadinlogun ninu ogorun-un ti apero ni yoo ma bo si owo awon alalumooni ti o fa pentuka ko ti i ni iyanju. Se awon esekuku-odo ti din iye ti won n bere ku si ida meedogbon ninu ogorun-un pelu alaye pe ida marun-un marun-un gbodo maa gori re lodoodun fun odun marun-un ti ajemonu naa yoo fi je aadota ninu ogorun-un.

Ibi ti oro naa yoo ja si, owo Oluwa ati awon ti o wa ni idi eto apero lo wa.

 

Igbale Osun Osogbo di Ajogunba Agbaye

Igbale Osun to wa ni ilu Osogbo, orile-ede Naijiria ni Ajo ti n mojuto eto Eko, Imo Ijinle ati Asa ni Agbaye (UNESCO) ti so di okan lara awon ajogunba gbogbo araye (World Heritage Site).

Ohun tabi agbegbe ti ajo yii ba so di ajogunba agbaye bayii di ohun amuyangan, ohun itoju, ohun igbelaruge ti awon eniyan yoo maa lo be wo loore koore.

Iru ibi ti a wi yii je ibi ti awon ti n rin irin-ajo afe (tourists) maa n lo nigbakuugba.

Ohun imuyangan gbaa lo je fun orile-ede ti Ajo Agbaye ba ri nnkan to see pe ni ajogunba gbogbo araye lodo won.

Ki i se igba gbogbo taabi orile-ede gbogbo ni iru nnkan yii wa. Nipa bayii, nnkan iwuri gbaa lo je fun awa Yoruba ati fun orile-ede Naijiria pe iru nnkan amuyangan yii wa laarin wa.

Bi a ti n yo ayo idunnu yii, o ye ki a ranti sa pe awon nnkankan ro mo idagbasoke ti igbale Osun Osogbo ni yii. Lara re ni pe isakoso igbale naa bo sowo ajo agbaye. Bibo si owo ajo yii yoo mu itoju ati idagbasoke to niyelori ba igbale naa. Sugbon yoo din bi awon ara ilu se le wo igbale naa ku gidigidi. Se gbogbo  ida lo ni oju meji.

A gbodo se iranti pe ajodun odun Osun Osogbo ti tun ko. Ojo keedogbon osun yii ni ayeye yoo bere. Iwo Popo ni won yoo fi side.  Aarin inu osun kejo ni asekagba yoo waye nibi ti Ajo UNESCO yoo ti se ikede ti yoo si tewo gba isakoso igbale naa.

Omo Yoruba ko ni rehin, Ire lojo gbogbo, ase.

Jegede safihan ise-ona ni Londoonu

Onise-ona kan to je omo bibi ile Naijiria lati ilu Ekiti, Ogbeni Emmanuel Taiwo Jegede n se afihan ise-ona re ni ilu Londoonu ti i se olu-ilu orile-ede ile Briteeni.Orin/Asa Yoruba ni Londoonu

Yato fun awon Aworan Afowoya, Ogbeni Jegede tun je Agbegilere (sculptor) ati Olusotan (r.d.d.d). A bi won ni Ekiti ni 1943, won si ko nipa eso sise labe Akerejola, agbegilere ni iluu won. Won tun ko ise lowo Osagie Osifo, Agbegilere ile Edo, ati ni 'Yaba College of Technology ni ilu Eko'. Gbogbo ise eso Emmanuel Taiwo Jegede gbe asa ilee Yoruba jade, paapaa, asa oriki ti ilu Ekiti. Ni Ojo Abameta (Satide) 16 July, agbegilere Jegede yoo se ere pelu itan ati ijo fun wawon omode laarin omo odun marun si merindinlogun (5-16 years). 
E Ma Gbagbe: Ifihan naa yoo wa fun wiwo titi di 13 August. Eyi naa je ara Afrika 05. www.africa2005.com

Orin/Asa Yoruba ni Londoonu

Egbe onilu (r.m.d) ati onijo (r.m.m) ti won n pe ni EWAJO yoo da ilu, orin ati ijo sile ni awon ibi itaja (d.r.d) kaakiri ilu Londoonu. Won da EWAJO sile lati gbe eso (d.m) orin ati asa (d.d) Yoruba ati ti
ile Afrika han. E le ri EWAJO ni awon ibi-itaja (r.r-d.r.d) wonyi:-
1. Surrey Quays - 3rd July
2. Lakeside Thurrock - 30th July

3. Brent Cross - 6th August
4. theCentreMK - 19th - 21st August
5. Whiteleys - 3rd September
Awon Eto Ifihan (Exhibitions) yoo wa nile lati aaro di irole ni awon ibi itaja naa. Ere idaraya yoo bere ni aago mejila (12pm) osan. E oo ri ijo lorisirisi, ilu, orin hipu-hoopu, awon onilu gangan, itan-siso, awon opidan (d.d.m, ajo-wo-le abbl.
*EWAJO wa lara awon eto ajoyo (d.r.d) lori asa ile Afrika ti o n lo lowo ni ilu Londoonu - ti won n pe ni Africa 05.
 
<http://www.ewajo.com>

 

 

Taiwo Olaniyi di asoju UNESCO

Ajo ti n se konkari eto Eko, Imo Ijinle ati Asa ni Agbaye (UNESCO) ti yan ogbontagi onise-ona omo Yoruba kan, Oloye Taiwo Olaniyi (ti gbogbo aye mo si Twin Seven Seven) gege bi asoju re nipa asa ati ise-ona.

Ilu Paris ni orile-ede Faranse ni ayeye yii ti waye ninu osu Karun-un odun yii.

Gege bi Oludari Agba UNESCO, Ogbeni Koichiro Matsuura se wi, Olaniyi gba oriyin lati je asoju ajo pataki yii latari ise takuntakun to n gbe se nipa ise-ona ati asa.

Omo bibi ilu Osogbo ni ipinle Osun ni Oloye Olaniyi i se. Ise ona bi aworan yiya si ara patako, aso, kaadi, ati beebee lo ni o n se. Bee ni o n ko orin pelu ohun adidun ti Eledumare fi jinki re. Ere ori itage paapaa wa lara ona ti Twin Seven Seven fi n da araye laraya.

Ise owo onise-ona naa wa ni opolopo orile-ede agbaye nigba ti ise wonyi si ti gbe oun paapaa de origun mereerin orile alaaye.

A o se iranti pe Ojogbon Wole Soyinka naa ti gba iru oriyin yii ni bi odun meloo sehin. Eyi wa lara bi o se je pe akowe onigege ara naa fi je jakunmo ti ki i se eran ibi kan soso mo.

Olaniyi ki i se aimo oloko ni ile Naijiria. Ohun iwuri lo si je fun awa Yoruba ati ile Naijiria pe omo wa kan tun gba iru ogo yii.

Ajewo ni iru oye bayii niwon igba ti eni ti won ba fun ko ba ti hu iwa ibaje. Awon asoju awa Yoruba wonyi, omoluabi ni won, abawon ko si ni i kan lu aso ala won lagbara Eleduwa.

Yoruba satilehin fun Guusu Naijiria

Awon asiwaju ile Yoruba ti so pe ko ye ki ariyanjiyan wa rara lori alekun owo amusowo ti n kan agbegbe ti won ti n wa alumooni inu ile ni orile-ede Naijiria.

Eyi waye latari fanfa ti n lo lowo lori aba ti awon ara agbegbe guusu (South-South) mu wa si ibi Apero ti n lo lowo l'Abuja. Aba won ni pe ki agbegbe kookan ni eto si ida meedogbon ninu ogorun-un ninu owo ti won ba pa lori alumooni ti won ba mu jade lati agbegbe naa. A o se iranti pe agbegbe ti a wi yii ni won ti n wa epo, eyi ti orile-ede Naijiria fi n se agbeji-ara bayii. Epo ti won n wa ni adugbo yii ti so ile won di 'koseegbe' nipa pe ise oko ko see se lori ile naa, bee ni eja ko si ninu odo won - se oro epo naa ati ina ti n jade lala lati ibi ategun epo ko lee fi aye sile fun nnkan abemi lati ye nibe.

Eyi lo mu ki awon eniyan naa ke gbajare pe o ye ki owo to joju maa te awon lowo lati fi maa wo egbo ti epo yii n da si awon lara. Aba akoko tile ni pe ki awon ni eto lori gbogbo owo to ba n wole, ki awon kan maa san owo-oya fun ijoba apapo. Sugbon nigba ti won fa oro naa lo, fa a bo, won gba pe ki o je aadota lori ogorun-un. Eyi ko tun te awon ti won jo wa ni Apero lorun. Nigba yi ni awon ara guusu naa ba ni koburu, nigba ti awon fe ki a si tun dijo wa po gege be orile-ede kan, awon gba pe ki owo amusowo awon je idakan ninu idamerin (25 %). Amo sa, won fi kun pe eyi yoo maa le ida marun-un marun-un ni odun kookan titi odun marun-un ti n bo nigba ti owo ti n bo si awon lowo yoo je aadota ninu ida ogorun-un.

Awon ara oke oya (ile Aarewa) fi aake kori pe eyi ko lee se e se. Pelu agidi ni won fi gba pe ki ida metadinlogun maa bo si owo awon ti a wi yii. Sugbon awon guusu ko jale pe bi ko ba pe ida meedogbon, awon ko ni i gba. Oro yii lo je ki apero naa di asoro.

Ojo Kokanla osu keje ni won fi ipadabo won si ni Abuja. Ero ijoba to gbe apero naa kale ni pe nigba ti yoo ba fi di ojo ti a wi yii, inu olukaluku yoo ti ro. Se won ko ni ye ba ara won soro bonkele ni asiko ti won fi tuka yii.

Ninu ipade ti awon gomina ile Yoruba ba awon asoju won nibi Apero naa se ni ilu Ibadan lojo Aje, ojo ketadinlogbon, osu Okudu (June), ko si ohun kan to yapa nipa pe ki awon asoju naa se atilehin fun awon ara guusu lori ohun ti won n beere.

Afenifere, Egbe igbimo Yoruba (Yoruba Council of Elders) ati Yoruba Parapo to fi mo awon egbe keekeekee miran nile Yoruba ati awon abenugan gbogbo lo n so pe ibi ti awon guusu duro si lori oro owo-amusowo yii ni awon wa.

Bi a ba ro oro naa, a o ri pe ohun ti awon guusu n beere fun yii, ki i se ti ara won nikan. Won ko so pe ki iye ti awon n beere wa lori epo nikan, sugbon lori ohunkohun ti n ti agbegbe kookan jade ti orile-ede wa si n ri owo lori re. Niwon igba to je pe ko si adugbo kan ti Oba-Onikee ko se nnkan fun, o je pe ko si bi adugbo kan ko se ni i je anfani yii - afi eyi to ba n se ole.

Lara amumenu awon guusu ni pe owo ti n jade lati ibi omi-oju awon ni ijoba olorijori to ti n waye ni Naijiria ti fi n toju ile Hausa (Aarewa) nigba ti iya si n je awon.

Afojuri omo Naijiria lowo olopaa de gongo

Ibi ti awon agbofinro, paapaajulo awon olopaa, yoo ba awon omo Naijiria de, Olohun lo ye o. Eyi da lori ona ti won fi n fi iya je eni ti won ba gbamu yala lori eto tabi lona aito.

Fifi agbara gba ni loju yii de gongo ni ilu Abuja laipe yii (Ojo kokandinlogbon osu Okudu, June) nigba ti awon olopaa ti a wi yii fi iya ainiye je Oga Olopaa ana, Ogbeni Tafa Adebayo Balogun.

Irohin to te Afonrere lowo fi han pe gbangba waalia ni awon olopaa mejo to woso ati awon meji ti ko woso olopaa ti fe fi tipatikuuku mu Balogun lehin igbejo ojo naa. Ai tete fi ara bale di ero ahamo ni o mu ki awon olopaa naa ko lilu bo Balogun. Won luu titi o fi daku niwaju opo eniyan. Sugbon awon eniyan yii ko ri nnkankan se nitori pe awon olopaa naa gbe ibon lowo gege bi a ti wi tele.

Irohin tun fi kun pe nigba ti won lu oga olopaa naa wo inu oko, o jabo nibi ti o ti n ja raburabu, ati pe moto te e lese. A ko ti i mo bi ese naa ko ro.

Awon onwoye so pe eyi fi han gbangba iru itu ti awon olopaa n fi omo Naijiria pa lojoojumo.

Se igbejo n lo lowo lori bi awon olopaa se ro ibon lu awon onisowo mefa kan ni agbegbe Apo, Abuja lori esun pe adigunjale ni won. Sugbon awon alajogbe awon alaisi naa ati eri ti n jade bayii fi n han pe iro ni awon olopaa pa; awon eniyan naa ki i se ole.

Nigba ti eni to dari awon olopaa naa lo se ise ibi yii ri pe agbe ti n si mo awon lori, o ti na papa bora.

Looto ni ajo ti n sejo lori iwa ibaje (EFCC) ti Ogbeni Nuhu Ribadu n dari gbe Balogun lo si ile-ejo latari obitibiti owo ti won ni o ji ko. Sugbon ile ejo ti da sile (gba beeli re) pe ki o maa wa je ejo lati ile. Ile-ejo yii lo wa ti awon osise ajo ti a wi yii tun fi fe e mu pelu tipatikuuku.

Gbogbo eniyan ni n ko haaa. Ki i se pe won ni Balogun ki i se odaran - ileejo ni yoo fi idi eyi mule. Idi 'haa' awon eniyan ni pe bi won ba le fi iya je oga olopaa tele bayii, iru itu wo ni won ko lee fi eniyan lasan pa. O tun je kayeefi pe won le se iru nnkan bayii lai naani pe gbogbo araye n wo awon.

N je iru iwa bayii ko ni i maa fun awon to n so pe eranko ni awa alawodudu ni oro so bayii? O ye ki a ye ara wa wo.

 

E so imo Yoruba di dandan ni ile iwe

Ipe pataki kan ti lo si awon ti oro kan lati so kiko ede ati asa Yoruba di dandan kaakiri ile-iwe to wa ni ile Yoruba.

Ipe yii wa lara aba mesan-an ti egbe kan ti n je Yoruba Parapo gbe jade lehin ipade olodoodun re to waye ni ilu Ibadan laipe yii.

Gege bi o ti wi, kiko omo lede abinibi yoo je ki oye ye omo; ki i se nipa ede yii nikan sugbon nipa asa awon eniyan re ati nipa bi a se n gbe ile-aye. Egbe naa so pe o se pataki ki ede Yoruba naa di ohun ti a ngbe gege bi won se n gbe ede Geesi laruge bayii.

Ohun miran ti egbe naa fi enu ba ni ai se deede gbogbo to gbogo lorile ede Naijiria bayii. Egbe Yoruba Parapo ke si ijoba Obasanjo, ti ipinle ati ti ijoba ibile gbogbo lati ji giri nipa bi won se n se akoso agbegbe won. Egbe naa woye pe ilu le pupo bayii ni ona ti a fere ma i ti ri iru re ri. "O ye ki ijoba wa nnkan se si oro yii ni kiakia".

Aba naa tun soro lori ojo iwaju iran Yoruba. O pe ipe fun eto ijoba eyi to fi aye sile fun agbegbe kookan lati le maa dari oro ara re ni iyato si eyi to je pe Abuja ni gbogbo ase ti n wa bayii.

Egbe yii woye pe a gbodo ji giri lati ri pe eto ikaniyan ti n bo yii ko di ohun ti won yoo fi tu wa je.

O ke si Aare Obasanjo lati gba pe iwe ofin Konstusan Naijiria ti odun 1999 ko pe. Latari eyi ko je ki a se apero to feserinle nibi ti a o so oro nipa ibagbepo wa ati bi iwe ofin titun yoo se je atona rere.

Yoruba Parapo da aba ojo ketalelogun osu kesan-an gege bi ojo ti o ye ki a ya soto nile Yoruba lati maa se ajodun irepo. Iredi ojo yii ni lati ko ara wa jo. Bi o tile je pe ilu orisirisi lo wa nile Yoruba, "a ti wa po, a si jo n se asepo fun ojo pipe debi pe a ti okan-naa. Ise wa, asa wa, ede wa; bakan naa ni".

Nipa ojo ti a wi yii, Aare egbe naa, Ojise-Olorun Bolanle Gbonigi so pe a ko le so pato ojo ti ile Yoruba bere. Sugbon a o se iranti pe ojo ketalelogun osun kesan-an odun 1886 ni ogun Kiriji to gba ile Yoruba kan fun odun merindinlogun pari. Ojo ti a wi yii ni awon ologun naa fi owo si iwe pe 'ija pari'. Ija naa si pari lati igba naa. Gbonigi so pe ogun ti a wi yii fe tu ilu, Oluwa lo se mo.

Lati gbogbo ipinle ti Yoruba wa ni awon eniyan ti wa sibi ipade naa. Awon Yoruba to wa ni ipinle Kwara, Kogi, Delta ati Edo papaa ran asoju wa.

E se ayewo eje nitori aisan roogun-roogun

Awon ti n se owo omo ati awon odokunrin-odobinrin ni won ti ki nilo lati se iwadii ipin-eje won lati le dena arun roogun-roogun.

Awon onisegun oyinbo to pe ipe yii so pe arun yii n le kun ni orile Naijiria latari bi awon eniyan ko se naani ohun to se pataki lati se ki o to di pe won yoo se owo omo pelu ara won.

Ile-Eko Isegun to wa ni Yunifasiti Ilorin ni awon onisegun oyinbo yii (Association of Resident Doctors) ti se apero won laipe yii.

Iwadii ipin-eje ti a wi yii ni won fi n mo boya idapo okunrin ati obinrin ti won fe ni asepo yii le mu ipin-eje ti won mo si es-es, SS (Sickle Cell), wa ninu omo to ba ti inu idapo naa waye. Bi eyi ba ri bee, omo ti a wi yii ti gbe arun roogun-roogun wa lati orun niyen. Arun ti a wi yi, agbaana ni. Ko si see wo ni awosan.

Ipin-eje okunrin ati ti obinrin lo n fi iru omo ti yoo ni iru arun yii han. Ona merin pataki ni ipin-eje le pin si. O le je AA tabi AS tabi SC tabi SS. Bi okan ninu awon to fe se owo omo ba je AA ti enikeji je eyikeyi ninu ipin meta to ku, ko sewu. Sugbon bi okan ninu won ba je AS ewu wa bi eni naa ba fe eni ti o je SC tabi SS. Oribande ni ki omo ti SC ati AS ba bi mase je alaisan roogun-roogun eyi a tun n da pe ni arun-eje.

Iyemeji ko tile si, gege bi awon oni isegun oyinbo ti wi, pe bi SS ati SS ba loyun funrawon, roogun-roogun alaisan ni won yoo bi.

Won ni iwadii fi han pe aisan yii ni ikarun-un ninu awon aisan gbemi-gbemi ti n ba awon eniyan finra ni ile wa. O wa se'ni laanu pe ariwo aisan Eedi (HIV/AIDS) ko je ki ijoba ati awon ara ilu ko ibi ara si aisan roogun-roogun yii.

Won ni didena aisan yii rorun bi a ba fi okan wa si.

Ona ati dena re ni ki a mo iru ipin-eje ti olukaluku je ki a to ba aeyi ti yoo di omo.ra wa se ere ife

E ye gbo'wo loju popo

Olopaa da ase Obasanjo koja

Bi o tile je pe ijoba apapo ile Naijiria ti ke si awon olopaa lati siw o mimaa da moto duro gba okoo naira lowo awon onimoto, sibe oju titi tun kun fun awon alaso dudu wonyi.

Bi o tile je pe o pe ti awon omo Naijiria ti n pariwo pe awon agbofinro yii n fitina awon loju popo, ijoba ko ko ibi ara si oro naa titi ipari osu to koja. Ohun to mu ijoba ji giri ni irinajo ti Aare orile-ede yii, Ogagun Olusegun Obasanjo se lo si Netherlands. Bi awon oludokowo yoo se wa da ise sile ni Naijiria wa lara ohun to ba lo.

Nibi ti o ti n ba awon omo orile-ede ti a wi yii soro ni awon won-onni laa mole fun pe o le soro fun awon lati wa da oko-owo sile ni Naijiria. Idi ni pe awon olopaa to n gbe'gi dana loju popo ko se bee lati fi da aabo bo awon eniyan. Kaka bee n se ni won n lo aso orun won ati ibon ti won n gbe lowo lati fi dun ikooko mo awon eniyan gba owo lowo won. Awon eniyan ti a wi yii so pe ona aito gbaa ni awon olopaa fi n lo owo gba mo awon to n koja lowo. Won ni bi won ba tile ri pe ajoji ni onitohun, oran de. "N se ni won a fun onitohun danin-danin.".

Oro yii jo Aare Obasanjo lara. Logan lo pase fun Oga-Agba awon olopaa, Ogbeni Sunday Ehindero lati tu gbogbo iko olopaa to wa loju ona jakejado ile Naijiria ka ni eye-o-soka.

Ose bii meta lehin ase yii, igbokegbodo wa se afihan pe awon olopaa ko ti i mu ase naa se.

Onigbeti kilo nipa sisi ipo lo

Oba Alayeluwa kan ti fa gbogbo awon to wa ni ipo alase lati mase si ipo ti won wa lo rara.Onigbeti ti ilu Igbeti, Oba Oyebisi Oyekan, Afasegbejo Keji lo se ikilo yii nigba ti o jawe oye le Ogbeni Olawale Olayanju gege bi Elerugba ilu naa lose to koja lohun-un.

Gege bio ti wi, ipokipo to wu ki a wa, fun igbega awon ara-ilu lo ye ki a lo ipo naa fun.

Latari eyi lo se ro Oloye Elerugba titun naa ati awon to wa ni ipo ase yala ti ibile ni tabi ti oloselu lati fi eso so nitori pe

"Oluwa lo n gbe eniyan de ipo. Gbogbo ohun ti a ba si se ni Oba Alawura yoo beere lowo wa, bi ojo ba pe."

O sdo siwaju pe ohun to se koko nipa ipo lilo ni lati fi se eto ati imunu-eni dun fun opolopo eniyan to wa ni ayika wa.

Onigbeti naa fi da awon ara ilu loju pe oun ko ni segbe rara ninu isakoso ilu naa, o si ro awon to wa nipo kaakiri lati ja iru ewe yii fi se oro.

Nigba ti o n soro, Elerugba titun naa, Oloye Amos Olawale Olayanju dupe pupo lowo Eledumare ati Onigbeti fun eru oye pataki ti oun je yii.

Olayanju mu idaniloju wa pe oun ko ni fi igba kan bo okan ninu gege bi oloye ilu beeni oun yoo si ba Kabiyesi fowo sowo po lati ri pe ilu Igbeti n goke agba.

O ni eru agba ni, oun si lero pe gbogbo awon to je ki iwuye naa see se ko ni ye maa ti oun lehin. Se agbajo-owo la fi n soya.

O dupe lowo awon ebi, ara ilu ati Oloye Oladeebo fun ilakaka won. Bee lo dupe awon to wa ba oun se eye lati ibaba ati lati ikoko.

Awon oloye ilu gbogbo lo wa nibi ayeye naa.

Lara awon to tun wa nibe ni Honerebu Muyiwa Ojekunle, Ogbeni S.A. Oni, Alagba Busari Ogunsile ati Oloye Muraina Odebode (Baba Isegun).

Awon miran ni Iyaafin Awaawu Oje Dananu, awon elewe-omo (Ewepeju), awon awako, (NURTW) ati beebee lo.

Owongogo ounje ni Naijiria

Baale, Mogaji ati iyawo je amala lo sorun

"Hee, iru kileyi? Olohun ma ma je ki a jeun daran o".Gbolohun wonyi lo gba enu awon eniyan ti o gbo isele idagiri to waye ni Alapa ni ijoba ibile Asa, Ipinle Kwara ni oru-moju ojo Aje si ojo Isegun to koja.

Se awon ara abule naa ji pelu igbe ti n jade lati ile Daodu ilu naa Alhaji Shuaibu Akanji Oniso, eni ti o gbe emi mi pelu okan lara awon iyawo re Belaawu Iya Elekuru.

Daodu yii lo je Baale abule ti a wi yi, eyi to wa ni oju ona Ilorin si Igbeti to je olu-ilu ijoba ibile Olorunsogo ni ipinle Oyo.

Korikosun olori abule naa kan, Alhaji Akanji to ba ore re je ninu ounje ti iyawo re se paapaa ba isele naa rin.

Gege bi awon ti oro se oju won se wi, amala ni Iya Elekuru ro ni ale ojo Aje to si seto re fun oko re ati alejo re.

Obe ewedu ati eran ni won fi je ounje ajesun naa.

Loru ni inu bere si i ko won, nigba ti ile yoo si fi mo, elemii ti gba a. Iku awon eni meta yii lo je ki o di ogbon eniyan to ti je Olohun nipe latari ounje jije ni ipinle Kwara ninu odun yii nikan.

Awon kan ni adugbo Tegbesun,Ogidi ni ilu Ilorin ti i se olu-ilu ipinle Kwara yii lo side isele buruku yii ni inu osu kinni odun yii.

Eko ni won mu tan pelu moinmoin ni oko laaro ojo ti a wi yii, ni inu ba bere si i lo won. Bi eniyan bii marun-un lo ku nibi isele yii. Ile iwosan ti won tete ko awon eniyan naa lo lo je ki emi to sofo nibe mo niba.

Ni inu osu kerin odun yii ni obinrin kan pelu awon omo re bii meta naa tun padanu emi won lehin ti won je amala tan.

Ijoba ti gbe eni to ta elubo ti won fi ro amala naa, bi o tile je pe onitohun n bura pe oun ko fi nnkankan sinu elubo naa.

O tun to bi ona meloo kan ti iru isele yii ti waye. Se ohun to dun lo ye lati maa ka, eyi ti a ka yen ti to.

Oro naa n se olukaluku ni kayeefi debi pe ajo ti n mojuto sise deede oogun ati ohun jije-mimu (Nigerian Drug Law Enforcement Agency, NDLEA) ati ijoba ipinle Kwara ti gbe igbimo kan dide lati se iwadii ohun to n fa isele buruku yii.

Awon onwoye so pe ati ara ilu ni o, ati igbimo ti ijoba gbe dide ni o, o se pataki lati fura si ona ti a fi n pese awon nnkan ti enu n je bayii.

Ohun kan to foju han ni pe owongogo nnkan ni Naijiria lode oni ti mu ki iyato de ba ona ti awon baba wa fi n se itoju ounje ki o to di jije - gege bi a se ba laye.

Fun apere, o loju iru awon ege ti eniyan le je. Ki i se gbogbo gbaaguda ni a gbodo fi bo enu.

Koda, eyi ti o see je pelu gbodo ri itoju to peye ki o to di pe yoo se e je, bi eniyan ko ba fe fun ara re - ati awon elomii - ni iwo je!

Gbogbo wa la kuku mo pe omi ege ni oro ninu pupo - yala eyi ti a n je ni o, tabi ‘ko gbodo kan’nu’. O kan je pe oro inu gbaaguda kogbodo kan’nu po ju ti inu ‘isu nikan-kiyan’ lo ni.

Oro inu ege yii lo maa n je ki awon mama wa - ati awon baba wa - o bo ege daadaa, ki won sa ko gbe lati ri pe opo ninu oro yii lo ti sanjade ko to di pe won a gba pe o se e fi i se elubo.

Yato si eyi, won a tun kuu lehin ti won ba loo tabi gun tan, won a si fi omi to ho daadaa ro, ki o to di jije.

Eni to ba n gba oju titi koja lati ilu kan de omiran ni ipinle Kwara ati Oyo yoo ri bi awon eniyan se n sa elubo won si egbe titi.

Ewure a to si, awon ti n lo le ha kelebe si bi ito ko ba de’be.

Bakan naa, iru elubo naa ko lee gbe gege bi eyi ti a sa si ori apata.

Awon ijoba ibile ti oro awon eniyan won je logun a pese aye isalubo pelu simenti fun awon eniyan won lati le dekun sisa elubo si eba ona. Sugbon meloo iru re la ri?

Ona bi i meeerin pataki ni iyato ti fi ba ona ti won fi n se eto ege nisisiyi bi a ba fi oju bi won se n se e tele wo o.

Ekinni, awon ege kan ti awon baba wa ka kun eewo ni awon elemii ti n je bayii latari owongogo ohun ti a n mu bo’nu. Se won ni bi ohun ti a nje ba tan, ki ohun ti a ki i je ma se afara.

Eekeji, opo ko ni suuru lati gbe gbogbo igbese to ye ni gbigbe nibi itoju ege ki o to di pe o di jije. Iredi a i le gbe gbogbo igbese wonyi ko si se lori a i si ohun miran ti enu yoo je fun asiko ti a o maa duro lati fi se ohun gbogbo to ye. Se ege ko dabi isu, ti a kan ki bo ina ti a o si maa je lo.

Ohun ti a le pe ni idi keta ni pe ai ri ounje gidi je pelu opo idaamu ti mu ki ajesara ti ki i je ki eniyan tete gbe aisan kere ninu ago ara. Nipa bayii, akolu kekere to ye ki nnkan ti awon oloyinbo n pe ni imuniti (immunity) tabi adena-aisan o ta danu bi igba ti eyin-die ta omi danu ni apa iwonba adena-arun yii ko le e ka mo.

Ohun kerin to n je ki iku ‘ona-ofun’ o maa wopo bayii ni ai si eto iwosan to peye to lorile-ede Naijiria.

Bi eniyan ba je iwo, ki i se oju-ese ni i pa’ni. Paapaa julo, iwo ti o je mo ti ounje.

Bi iru eni bee ba tete ri iwosan, ti won po ounje naa kuro ninu re, akuko orun yoo fo onitohun ru.

Sugbon kini n sele ni ilu wa bayii? Ona ile-iwosan jinna si awon eniyan. Ni ibomiran ti ile iwosan wa, awon ti o mose le ma si ni enu ise lasiko ti alaisan niloo won. Bi awon yii ba wa lenu ise, won le ma ri irinse ati ina ijoba sise bo ti to ati bo ti ye. Bi won ba ri eleyii, ti won se awari ohun to fa ailera alaisan, oogun nko? Opolopo igba lo ti je pe a i ri oogun lasiko lo se iku pa awon emi ti won ko ba si wa laaye bayii. Ki Oluwa ma je ki a fi ojo olojo lo, ase.

 

SPEB yoo seranwo fun agbegbe ti n fe ile-iwe

 

Ajo ti n mojuto ile-iwe alakobere ni Ipinle Oyo, SPEB ti setan lati se atilehin fun adugbo-kadugbo to ba da ile-iwe alakobere sile.Alaga ajo naa, Ojogbon Taoheed Adedoja lo fi idi oro yii mule nigba ti o n ba onirohin soro ni ile Akede, Ibadan lose to koja.

Gege bi o ti wi, bi awon eniyan naa ba ti ko iwe si ajo oun, awon yoo yan olubewo lo sibe. Bi olubewo yii ba ti so pe ko sewu, eto dida ile-iwe sile naa bere niyen.

Sugbon o fi kun oro re pe igbese naa yoo ya, bi awon adugbo to n fe ile-iwe ti a wi yii ba pese ile lori eyi ti ajo naa yoo ko ile si. ‘Bi won ba se iranwo nibi ile paapaa, ko buru’ ni ohun ti o tun fi gbe oro re lese.

Adedoja ko sai se alaye pe awon oluko ti ajo oun sese fun nise ko gbodo ni isoro ibugbe. Idi eyi ni pe idaji awon ti ajo naa gba ni ijoba ibile kan je omo-bibi agbegbe ibi ti won gba won si.

O so yanya pe awon alaga ijoba ibile ti fi da oun loju pe awon yoo se iranwo lati ri pe awon oluko ti won ba gbe wa si adugbo awon ko ni isoro ibugbe.

Awon omo Yoruba ni Ipinle Kogi n beere fun Ipinle Okun

Awon odo kan ni ipinle Kogi ni orile-ede Naijiria ti pe ipe fun dida ipinle Okun sile. Awon odo naa so pe ibi ti awon wa nisisiyi ko je ki eto ti awon to si maa to awon lowo.

Ninu iwe apileko won si ajo Apero ti n lo lowo ni Abuja, awon odo naa so pe awon ijoba ibile marun-un ti Okun wa ni Ipinle Kogi ati awon Okun yooku ni Kwara, Ekiti ati Ondo ni ki ijoba so di ipinle kan eyi ti oruko re yoo maa je Ipinle Okun.

Won so yanya pe Yoruba ni awon. Atipe awon to je bi olori agbegbe naa ti won n ka agbegbe naa mo ile Hausa n  je ki awon padanu pupo. Idi ni pe awon Hausa ko ka awon kun ara won nigba ti ai ni ajosepo pelu ile Yoruba ko je ki ohun to ye ko je ti awon lati ibe maa te awon lowo.

"Ko si eni to gbo oruko bi i Awoniyi, Adeyemi, Olusola, Olayemi ti ko ni mo pe oruko Yoruba gedegbe ni won. Ki ni wa de ti awon ti n je oruko wonyi n ka ara won kun ara ariwa? A n beere eyi latari igbese awon olori agbegbe naa gege bi Oloye Sola Saraki, Oloye Sunday Awoniyi ati bee bee lo."

Won mu wa si iranti pe ni odun 1999 ti Oloye Sunday Awoniyi du ipo alaga egbe Pindipi (Peoples Democratic Party, PDP), awon agba egbe naa (ti o fi kan Aare Obasanjo) ko je ki eyi see se. Idi ti won mu wa nigba naa ni pe eni ti n dije fun ipo aare loruko egbe naa ko le wa lati agbegbe kan ki alaga egbe naa tun wa lati agbegbe yii kan naa. Ohun ti won n so ni pe Oloye Olusegun Obasanjo, Yoruba ni lati agbegbe guusu-iwo oorun, Oloye Sunday Awoniyi naa, Yoruba ni.

"Ohun ti won n so ni pe okan naa ni Obasanjo ati Awoniyi. Eyi fi han gedegbe pe a n tan ara wa je ni bi a ba n pe ara wa ni Aarewa."

Latari eyi ni won fi so pe jije alaga Igbimo Iforikori Arewa  (Arewa Consultative Forum) ti Oloye Awoniyi ati ajo Arewa ti Oloye Olusola Saraki sese da sile dabi  itanra-eni je.

"Lasiko ti o ba te awon ara ile Hausa lorun, won a ni ara won la je. Sugbon lasiko to ba di pe o ye ki a gba eto wa, won a ni Yoruba ni wa".

Aropo gbogbo nnkan wonyi lo mu ki awon odo agbegbe naa so pe ki awon ni Ipinle ti won ki atunto si de ba ile Naijiria lona ti awon Okun yoo fi darapo mo iran Yoruba yooku to wa ni iwo-oorun guusu orile-ede naa. Ilu Kaba ni won fe ko je olu-lu ipinle titun naa.

 

Tinubu ke gbajare lori igbese awon Yoruba kan

Oshiomhole ni ewu n be

Gomina Ahmed Bola Tinubu ti Ipinle Eko ti ke gbajare wipe awon omo Yoruba naa lo tun fe maa gbe igbese ti n se akoba fun ile Yoruba.

Gomina so oro yii nigba ti n ba awon onirohin jomitoro oro gege bi ayeye iranti Ibo OjoKejila osu  Okudu (June 12) odun 1993 eyi to waye ni ilu Eko ni ipari ose.

O ni iyalenu lo je pe Aare Obasanjo to je omo bibi Yoruba le se iru nnkan ti n se lowo bayii. Paapaa julo latari ipa ti awon gomina ile Yoruba (labe asia egbe Afenifere, AD) ko ki Obasanjo ba lee ri aare se leekeji.

Pataki ninu igbese yii, gege bi Asiwaju Tinubu se so ni ebe ti Obasanjo ati awon agbagba Yoruba be awon gomina ipinle mefeefa ile Yoruba pe ki won ma ti i di ibo si ijoba ibile ni odun 2002. "Won ni bi a ba di ibo yii nigba naa, egbe PDP ko ni yan Obasanjo fun ipo aare ni odun 2003. Idi ni pe bi a ba di ibo yii, egbe AD ni yoo wole kaakiri ile Yoruba gege bi o ti waye ni odun 1999. Awon omo egbe PDP yoo fi eyi se awawi. Won a ni ko ni omolehin ni ile re, nitori naa ko to gege bi eni to ye lati gbe asia egbe naa."

Tinubu soo  di mimo pe yato si pe Obasanjo be awon Gomina AD mefeefa lori oro yii, o tun be elebe lopolopo si awon. "A ro oro naa siwa sehin, a gba latari pe bi PDP ko ba mu Obasanjo, won ko ni mu Yoruba miran. O si san ki Yoruba lo ipo naa leemeji ki o to tun yi lo si ibomiran. Awon agbaagba Yoruba titi o fi kan awon asiwaju Afenifere ni Obasanjo be ki won ba wa soro. Eyi lo je ki a gba. Eyi lo je ki a se ipolongo ibo fun, lai mo pe gbogbo bi awa se n gba aawe re, osan ti wa lo n je. O dale, gbogob wa ni a si mo ohun ti i sele si eni ba da'le".

O kabamo pe kaka ki Obasanjo mo riri ohun ti awon se fun, n se ni o san'na iparun awon. Eyi lo faa ti egbe PDP fi ja gbogbo Ipinle Yoruba gba pelu ipa mo AD lowo. Won gbiyanju lati gba Eko paapaa, eegun lo ju eegun lo.

Yato si eyi, Tinubu ni ohun ti n se ohun ni kayeefi ni ese  ti Obasanjo gbe lori owo ti o ye ki awon ijoba ibile to wa ni ipinle Eko gba lati inu asunwon apapo. Owo naa ti le ni okoo bilionu naira.

O ni ko si idi ti o fi ye ko se eyi. Sugbon lehin to se bee, ti ile-ejo to ga julo ni orile-ede yii si so pe ko ni eto lati se bee, ko si idi to fi ye ki Obasanjo tun fi aake kori pe owo naa ko ni je sisan.

O bu enu ate lu awon agbaagba omo PDP ti won je omo-bibi Eko ti won n ti Obasanjo pe ko gbodo san owo naa.

O tun so siwaju pe iha ti awon omo egbe yii ko si ijoba Eko ki i se ti oselu rara, bikose ti ota ponbele. O ni gbogbo ona ni won fi n gbogun ti ijoba oun ati ipinle Eko. O toka si ikede ijoba apapo pe oun ti naa owo bi egberin bilionu naira (about N800 billion) lori ipese omi. "Bi owo yii ti po to yii, kobo ninu re ko wa si Ipinle Eko. Ohun ti won n fe ni ki ijoba wa ma le se ohun kankan, ki awon ara ilu bere si fi ehonu han, ki won maa so wa loko, ki Aare le so pe oun yan ajele fun Ipinle Eko"

Asiwaju Tinubu ni ewu to wa ninu iwa ti Obasanjo n hu yii ni pe aibowo fun ile-ejo "aibowo fun ofin ni ewu to ga julo fun iduro sinsin ijoba tiwantiwa".

Latari eyi lo fi so pe bi ijoba tiwantiwa (democracy) yii ba forisanpon (ki Oluwa maje ko waye) Obasanjo ati egbe PDP ni yoo ni ebi re.

Aare agbarijo awon osise (Nigeria Labour Congress), Ogbeni Adams Aliyu Oshiomhole kabamo pe ijoba apapo le hu iru iwa bayii si ipinle kan.

Nigba ti o n soro nibi akojopo awon osise losu to koja, Oshiomhole so pe bi Aare Obasanjo ati ijoba apapo ba le da ase ile ejo to ga ju koja bayii lori oro to je mo ijoba ipinle, ewu nla gbaa lo je fun orile-ede wa, nitori pe bi ejo ba da ijoba po pelu ara ilu, ijoba ko ni i naani ase ti ile-ejo ba pa. “Ewu nla gbaa ni aibowo fun ase ile-ejo ati ofin ile wa je fun eto alaafia ati eto iselu”.

 

Ipa ti asa Yoruba ko ninu idagbasoke ijo Aguda (Katoliiki, Catholic) ni Amerika

Ipa ti esin Yoruba ko nipa idagbasoke ijo Aguda (Catholic, Katoliiki) ni Amerika

Lati owo Enrique Gozanlez, Uruguay*

 

O je ohun edun-okan pe opo ko ti i mo riri ipa ti asa ati esin iran Yoruba (eyi ti o fi ese won’se pelu awon elegbe re lasiko ti owo-eru fi n lo lowo) ko ninu amugbooro esin Aguda (Katoliiki, Catholic) ni Amerika. Paapaa julo bi a ba wo iru isoro ti awon eru wonyi koju nigba ti won n fi tipatipa ko won bo lati ile Afrika. Ki i se  igba gbogbo ni won n gba awon eru wonyi laye lati se esin ati ajodun won. Igba ti eyi ba waye, awon to leru wonyi n fi juuju bo awon eru wonyi loju lori ohun to je mo orin, ijo ati ilu won. Fifi tipa so eniyan di omo-ijo  Aguda (Katoliiki) so lilo ede ati asa awon omo ile Afrika to wa ni igbekun eru yii di eewo. Nipa bayii, gbigberi asa wonyi wa lowo bi ajose ba se wa laarin won si pelu eto esin ajo Aguda. Eyi lo je ki eto kan ti a mo si Aguda Alawodudu (African Catholics) je gbigbende. Latari eyi ni asa alawodudu ko se je titeri  patapata lasiko owo eru, ti asa naa si di ohun ti o n ti owo iran kan de iran to tele.

Lona miran ewewe, o mu iyato ba bi asa yi se ri nibi ti o ti se wa, bee ni  o si ri titi di asiko ti a wa yi. Bi o tile je pe asa yii ti ni amulumala ninu, sibe oun naa ni n se afihan asa ati ise iran alawodudu  bi won se n gbe igbe aye won ni Amerika.

Lasiko yii ti awon esin to sese n dide n fe yo owo kilanko esin Aguda kuro ninu awon asa olorijori, awuyewuye ko sai maa waye nipa ewo gan-an ni o je orirun awon asa wonyi ati pe ona wo tabi iru asa wo ni esin (ati asa) Aguda ti ko mora to si so di tie. Ohun to di fifa mora-eni-lowo bayii ni ibeere ti n je yo nipa Sango ati awon orisa yoku.

Nigba ti awon alawodudu to wa ni Amerika bere si i de laarin eedegbeta si oodunrun odun (500 - 300 years; 16th to 18th centuries) sehin, won bere si i se agbeyewo laarin awon orisa abalaye won ati orisa ijo Aguda ti won n pe ni Eni Mimo (Saints or Santo). Won woye pe orisa jagunjagun ti n je Ogun jo San Jorge (Jorge Mimo) ti ojo ajodun re si papo mo ojo ti won n se ajodun eni-orisa pataki ninu ijo Aguda Katoliiki yii - eyiini Jorge Mimo.

Amosa o, bi o tile je pe opo oro lo n je siso ti akitiyan si po nipa asa awon Alawodudu yii, iwonba eniyan lo ni imo nipa ise ati asa awon omo Afrika ni ile Amerika nibi. Koko awon asa wonyi, iyato

 Koko awon asa wonyi, iyato to wa laarin asa kan si omiran, ojo ati asiko ti won n se ajodun awon orisa wonyi lati eya kan si omiran. Bi a se so siwaju, die ninu awon alawodudu n fe ifowosowopo lori nnkan wonyi, ati latari mima a se awon esin ati asa wonyi bi awon to se won sile se se (Yoruba bo won ni e je ki a se bi won se n se e, ki o le ri bi o se ye ki o ri).

Laarin gbogbo eya Alawodudu to wa l'Amerika, awon asa to gbile ti aye si mo ju ni Kandomble, Batuku, Santeria ati Fudu.

Fudu je asa kan ti o ti erekusu ni aarin gbungbun Amerika, Haiti wa. Lati odo awon eya kan ti won n pe ni Jeje lo si ti wa. Ile Afrika ni awon Jeje yii wa.

Erekusu Kiuba (Cuba) ni Santeria ti wa ni tie. Isesi orisa yii jo ti Santo nigba ti isesi awon abore re si jo ti awon asiwaju ijo Aguda. Gege bi a ti ri asa yii laarin awon alawodudu to wa ni ibaaba (Africans in Diaspora). Ojogbon (Wande) Abimbola woye pe ona ti won fi n se Santeria ni Kiuba (Cuba) fara mo ona ti won n se awon orisa ile Yoruba pupo. 

Kamdombule - eyi ti ipari re jo didin agbara ku - ni a le topa re de ibi gbolohun meta kan; ipe, ajose ati ijo. Aarin gbungbun ati ariwa ile Brasiili ni esin yii ti se. O si fara pe Jeje, Angola ati Nago.

Awon Jeje to tele isesi awon kan to de si Amerika lati Abome atijo. Awon lo si se agbekale Fudu (gege bi a ti ri ka ninu iwadii Lissa, Nzazi ati bee bee lo).

Awon Angola je iran Bantu to wa lati agbegbe Angola ati Kongo (Congo). Angola yii fara mo Nkisse (gege bi Matamba, Dandalunda ati bee bee lo se wi); ati nitori ifarapa ati awon afojuri miran to sele nigba ti won n bo lati Angola si Brasiili.

Ohun ti a ri gbamu ni pe Yoruba ni orirun awon Anago - nipa asa ati esin won. Oniran-iran si ni awon eya yii: Ijesa, Ketu (awon yi lo po ju) ati bee bee lo. Awon eya yii (ti won n pe ara won ni orile-ede) Ketu, lo de gbehin lati Afrika si Amerika pelu asa won - paapaa julo Ossoossi.

Afojuwo asa yii fi han pe o jo bi won se n se e ni Afrika laye atijo. Awon orisa ibile Kandombule-Ago ni Esu, Logunede, Nana, Obaluaye, Orunmila, Osanyin, Osanla, Ossoossi, Osun, Osumare, Oya, Sango ati Yemoja.

Ile Brasiili ni Batuku ti se, ibe lo si ti tan de Uruguaye . Lati ibi ti o ti tan de Ajentina (Argentina) ati awon ibi to ku ni Guusu ile Amerika.

Ni ibere, Batuku lemii ati so awon eya otooto po lati le so won di okan.

Nipa bayii, iru iwuri bayii ti o jeyo ninu Batuku wa lati odo awon eya Yoruba ninu eyi ti a ti ri apere bi won ti  n se esin won.

Awon Orisa Batuku ni Esu-Bara, Ogun, Oya , Songo, Ode ati Otin, Oba, Osanyin, Sonponno, (Xapanan), Osun, Iemoja (Yemoja), Osanguiyan, Osalufa ati Orunmila.

Gege bi a ti woye, ko si okankan ninu awon asa tabi esin to wa ni Amerika ni o n se akoja bi won se n se esin ibile ni ile Yoruba lai ni amulumala. Ohun meta lo je ki eyi ri bee:

Akoko,  awon abore orisa wonyi ti ko ba won de Amerika.

 Idi miran ti eyi tun fi ri bee ni pipadanu imo nipa bi o se ye ki a maa bo awon orisa wonyi latari ipo eru ti awon eniyan naa wa

Idi keta ni gbigba ti awon olowo won ko gba won laye lati se esin won nigba ti won fi wa loko eru.

 

*Jare Ajayi lo se itumo apileko yii lati ede Spaniisi si ede Yoruba. Ogbeni Gonzaleesi ko o fun AfonrereYoruba ni fun imujinle imo wa nipa igbesi aye awon eniyan wa to wa ni ibaaba.

 E ho iho ayo Ape+Itewe (Keyboard) fun Yoruba ati awon ede miran ti jade

 Laipe laijinna, irorun to nipon yoo de ba bi a se le te iwe ninu ede gbogbo to wa ni orile-ede Naijiria ati ni ile Afrika lapapo. Idi eyi ni ti ape-itewe (keyboard) elede-pupo ti won sese gbe jade.

Ape-itewe yii ti won pe oruko re ni Konyin ni ege merindinlaadofa (106 characters). O fi meji le si eyi ti o wopo lode oni ti o je pe ede Geesi ati awon ede Yuropian nikan lo n ko.

Ohun iwuri pataki kan to tun wa ninu dida ape-ikowe yii sile ni pe okan lara wa ni gbongbo to wa ni idi re. Ki i se oluwo tabi atohunrewa rara. Oruko eni naa ni Ogbeni Olukayode Walter Oluwole.

Gege bi o ti wi, Konyin ti o pe ape-itewe naa wa lati gbolohun Yoruba 'ekan oyin' (drop of honey). O salaye pe ohun idunnu, nnkan adun lo je pe eniyan a le ba elede re soro ni ede abinibi lai si isoro nipa ami tabi nnkan miran to le di agboye lowo. O fi ti ara re se akawe pe lenu igba ti oun pelu baba oun n ko iwe si ara won ni ede Yoruba to je ede abinibi awon, agboye ati emi ife to ju ti atehinwa ti n gbile laarin awon.

O ni iru adun to wa ninu tito oyin la ni oun woye pe o wa ninu iforowero ni ede abinibi.

Odun mejo lo gba Oluwole lati fi ba ise naa de oju ami. Bi awada bi ere ni oun to wa di nnkan ribiribi yii bere. Se esun tere ni i di omi nla.

Gege bi o ti wi, oun pelu iyekan re kan ti o tun je omo ile-eko giga Lagos Boys High School pelu oun ni opo odun die sehin ti oruko re n je Ade Oyagbola ni awon jo pade ni ile itaja kan ni Amerika lodun mejo sehin. Oyagbola yii to je onimo nipa eto isiro owo (finance) lo gbun Oluwole ni kese pe kini se ti won ko le se nnkan nipa oruko awa Yoruba ti awon eniyan ki i ri pe daadaa latari ami ti won ko ri fi si lori ati labe.

Se ise imo-ijinle nipa ero (mecahnical engineering) ni Olukayode Oluwole ko.

"Eyi lo mu mi bere si i se akitiyan lati se nnkan nipa ohun ti Ade so yii".

Bi o se n gbiyanju yii, o woye pe o kuku san ki iru ape-itewe naa ma wa fun ede Yoruba nikan, nigba to tile je pe opolopo ede Naijiria lo je pe bi a se n ko won ko yato pupo sira won nipa ami.

Iyanju yii mu OLuwole de opolopo ile-eko giga Fasiti ni Naijiria, odo ajo ti  n se konkaari ede abinibi ni ile Naijiria (Nigerian Institute of Languages) to wa ni ilu Aba, awon ajo ati ile eko giga to wa ni Amerika, ile Geesi ati Jamani ti won ni nnkan se pelu imo ero ati ede Afrika.

Awon oyinbo si ran an lowo, paapaa julo omo Amerika-Juu kan ti o gbe owo die sile fun agbejade ape-itewe yii titi ti awon olowo miran (bi omo Naijiria) yoo fi se atilehin fun pipese ape naa lopo yanturu.

Pelu ape naa, eniyan le kowe ni ede Hausa, Igbo, Efik, Idoma, Ijo, Tiifi, Ibini ati bee bee lo.

Nnkan bi egberun meje abo (N7,500) tabi marun-un le laadota dola ($55) ni ape kookan bayi. Bi o ba di pe awon to nifon-leekannaa ba fi owo sile lati pese ape yii ni yanturu, owo re yoo wale jojo. Se ape ti o wa nita bayi ko ju bi egbeta si egberun naira lo (N500-N1,000).

 Ninu irinajo onirohin (AfonrereYoruba) yii si ilu Kano ninu osu Karun-un odun 2005, a ri ape-itewe ti o ni ede leta ede Oyinbo ati ti Hausa, sugbon ti Kayode yii, gbogbo ede to wa ni ile Naijiria ni o wulo fun.

Omo ilu Sagamu ni Olukayode Oluwole, sugbon ilu Eko ni won ti bi. O gbe ilu Abeokuta (ti won ti bi iya-iya re) fun bi odun meloo kan. O tun gbe awon ilu pataki kan ni ile Hausa gege bi Jos, Kaduna, Kano ati Abuja fun igba diedie.

Lehin to pari eko re ni Eko Boys High School, o lo si ile eko giga imo ero Lagos State College of Science and Technology. Lehin eyi lo gba ile Amerika lo ni odun 1981.

O ko ise ero tito (mechanical engineering) ni ie-eko Wenthworth Institute of Technology, Boston, Massachusetts. Lehin to sise osu fun igba die, o da ise tire sile eyi to pe oruko re ni BS International.

Ise ero komputa ati awon eroja re ni ile-ise yi da le lori.

Enikeji re, Ade Oyagbola naa ni ile-ise ti oruko re n je Lancor Technologies. Awon mejeeji lo fowosowo lati ri pe ohun to jo bi ala lodun mejo sehin di oun bayii. E o ri pe ire nla n be fun wa. Ki Oluwa je ki imo omo Oduduwa tubo maa rewaju, ase. Kayode, Ade ati eyin ti e n gbiyanju lati gbe iran Yoruba ati oruko Naijiria ani iran alawodudu ga, e ku ise, Edumare yoo ma fun yin se, ase.

Awon omo alawodudu n poora ni ilu Oyinbo

Ifonufoya ti gbaye kan-an bayii o, latari ogooro omo alawodudu ti won n poora ni orile-ede Biriteeni lenu bi odun meloo sehin.

Iwadii awon oloopa lori iku omokunrin kan ti won ri gbunduku ara re ni odo Thames ni odun 2001(won pe oruko re ni Boy Adam)  ti fi idi re mule pe laarin osu keje si osu kesan-an odun 2001 yii nikan, oodunrun omo alawodudu ti won je omo odun merin si meje ni won poora ni ile iwe won.

Eyi lo mu ki ile-ise otopinpin Geesi (Scotland Yard) woye pe o le to egberun iru awon omo bayii ti won n poora lodoodun.

Oloopa otelemuye kan, Will O’Reilly so pe iwaadi awon si ile iwe gbogbo fi han pe nnkan bi oodunrun (300) omo wewe ni awon ile iwe wonyi ko ri mo laarin igba ti a so soke yii.

O so pe laarin awon oodunrun yii, eyokansoso lo wa lati agbegbe Karibia eyiini ni guusu Amerika nigba ti awon to ku je alawodudu lati Afrika. Oga olopaa naa so pe pelu gbogbo akitiyan awon olopaa kaakiri ile ti oro yii kan, meji pere ninu awon omo to sonu yii ni won riri.

Opolopo omo ile Naijiria ti o fi kan ogunlogo  awon omo Yoruba lo wa ni ilu Oyinbo yii.

Osise ile ise irohin BBC kan, Angus Stickler daba pe boya die lara awon omo wonyin ni won ti pada si ile abinibi won. Sugbon awon kan n fe ki ijoba ile Geesi tubo de okun imujuto awon odo-weere le ju bi o ti wa bayii lo.

Okan lara awon oluko ile-iwe ipilese (Primary school) , Ogbeini Tim Benson, ninu oro tire so pe o le je pe opo ninu awon omo ti won ro pe won sonu yii ni o je pe won kan paaro ile-iwe ni.

“O le je pe awon ti won n gbe odo won paaro ibi ti won n gbe. Eyi lo je ki won fi awon omo naa si ile iwe miran. Awon le ma ro pe o ye ki awon so fun ile-iwe ti awon omo wonyi wa tele.”

Ni bayii, ijoba ti n kan-an nipa fun gbogbo eni ti o ba n toju omo ki o fi eyi to ajo ti n mojuto eto omo-ewe ati odo leti.

Oluwa ko ni je ki omo wa o ku, beeni won ko si ni i nu, ase.

Alaketu fee da ilu titun sile fun omo Yoruba

Lati odun ti n bo lo, awon alawo-dudu nibikibi lorile agbaye to ba ka ara won kun iran Yoruba yoo ni ibikan ti won yoo le maa toka si gege bi orirun won.

Biotile je pe iran awon omo Yoruba ti won ko leru lo si ilu Oyinbo ko mo paato ibi ti won ti se, eto pataki yii yoo fun won ni anfaani lati le fi owo soya toka si ibi ti won yoo pe ni ile gege bi awon Juu se n toka si Isreli lonii.

Olofinju ti ilu Ketu (Ketou) Olola Ade Musbau Olofinju to gba enu so fun Alaketu lo so eyi di mimo lenu looloo yii.nibi ayeye odun Oduduwa to waye ni ilu naa. Gege bi o ti wi, aala to wa ni aarin orile-ede Naijiria ati orile-ede Benin ni ilu titun yii yoo ti waye.

Oloye Musbau Olofinju so pe Igbale-aye ni oruko ilu naa yoo ma je. Odun ti n bo ni won yoo si fi ipile ilu naa le’le.

Ilu Igbale-aye yii yoo wa fun gbogbo omo Yoruba; paapaa awon to wa ni ile okeere bi i Amerika, Karibia, Yuroopu ati bee bee lo lati ri ibi ti won yoo ma toka si gege bi ile. Ogangan ibi ti ilu titun yii yoo wa bo si aarin Ketu ati ibi ti a mo si Oke-ogun ile Naijiria lonii.

Eyikeyi to ba fe ninu awon omo Yoruba lati ibikibi lorile agbaye le wa si ibe yala lati tedo tabi fun abewo lasan.

"Won le wa sibe fun eto iwadii nipa asa, ede ati ohun gbogbo to je mo Yoruba".

A o se iranti pe Orile-ede ti n je Isreli lonii di gbigbe dide ni odun 1948. Ibe si ni awon eya Juu tabi Isreli nibikibi lagbaaye n pe ni ile bayii.

Ile-Ife ni Alaketu ti o te ilu Ketu do i se. Okan lara awon omo Okanbi ti i se omo-bibi Oduduwa si ni. Oruko re naa ni won si n fi pe ilu naa titi di oni. Iwo oorun Naijiria ni isedale Yoruba. Awon eya Yoruba wa ni ipinle bi i mesan-an ni ile Naijiria bayii. Awon ipinle naa ni Ekiti, Eko, Kwara, Edo, Kogi, Ondo, Ogun, Oyo ati Osun. Awon Isekiri to wa ni ipinle Delta paapaa je Yoruba gege bi a se ri ninu isoro, asa ati ede won.

Awon ojulowo Yoruba paapaa wa ni orile-ede Benin (gege bi a se fi han lokee irohin yii) ati Togo; nigba ti opolopo to se atipo lo si awon orile-ede to wa ni isale yii lo ti so ibe di ile. Awon orile ede ti Yoruba wa, ti won si n so ede pataki yii ni Saro (Sierra Leone), Siniga (Senegal), Ghana, ati Liberia.

Yato si awon ti eru so irandiran won di ero ilu oyinbo, awon omo ile Yoruba ti gberegejige ni awon orile-ede bii Amerika, Ile-Geesi, Jamani, Iitali, Faranse, Haiti, Kiuba,(Cuba), Brazil ati beebee lo.

Itan adayeba fi han pe Ile-Ife ni aye ti se. Ibe si ni oju ti n mo wa. Se alagemo ati adie ni Obatala ati awon irunmole yooku lo lati fi tan yepe kaakiri ori omi; bayi ni ile se fe ti o si le ki omo adarihunrun ati awon eda miran gbogbo to le tedo sori ile.

Iwaju lojugun n gbe, iwaju la o maa lo, ase.

Alake titun gbodo gbe asa abalaye laruge - Nlado Egba

Oloye pataki kan ni ilu Abeokuta, Oloye Adewunmi Adefolu ti so yanya pe eni ti o ba pe ara re ni atunbi omolehin Jeesu ko le je oye Alake ti ilu Abeokuta.

Adefolu ti i se Nlado ti ilu pataki yii soro naa laipe yii nigba ti o n se apejuwe ara ohun ti won yoo wo mo eni ti yoo je Alake titun lara.

Gege bi o ti wi, eni ti ko ba ni le se eto gbogbo to ye ni ilu gege bi asa se laa kale ko gbodo gbidanwo pe oun fe je

alake.

"A gbodo se oro, egungun, Ogun ati awon ayeye gbogbo to ye ni asiko won. Lati ibere pepe, oba si ni baba isale fun gbogbo esin to wa ni ilu. Enikan ko lee de ori aleefa bayii ko wa so pe atunbi Jeesu (born-again Christian) ni oun; nipa bayii oun ko le se asa ibile nitori ebo sise ni."

Nlado tun fi kun oro re pe enikeni to ba fe du ipo pataki yii gbodo mo ohun to wa ni idi re. "Ki i se pe yoo de ori oye tan yoo wa so pe esin oun ko gba oun laye lati se kini kan. Ki onitohun yaa ro o daadaa ki o to ti orun bo o".

A o se iranti pe laipe yii, awon oba kan ni ile Yoruba so pe awon ti di atunbi ninu esin igbagbo. Awon kan ninu won gege bi Osile ti Oke Ona tile ko awon ere to wa ni aafin won jade gege bi apere pe awon ti kehin si awon irunmole wonyi nitori pe orisa ati didebo si Olorun ni won je, gege bi awon oba naa se so.

O see se ko je pe iru nnkan bayii ni Nlado ro to fi tete n ke tantan pe awon ko ni i gba iru re lowo oba to ba je ni Ake.

Odun to koja ni Oba Oyebade Lipede ti i ise Alake ana waja. Aadorun-un odun ni baba lo lori eepe ko do dagbere f’aye. Ki Oluwa de’le fun awon to ti lo.

Yoruba ni Idale (Yoruba in Diaspora) lodi si awon Gomina

Egbe awon omo Yoruba pataki kan ti a mo si Yoruba in Diaspora (Awon Yoruba ti n gbe Idale) ti fa awon ti n soju agbegbe iwo-oorun Naijiria nibi apero ti n lowo ni Abuja ati awon gomina agbegbe ti a wi yi lati ma se dale iran Yoruba.

Ikilo yi waye nibi apero kan ti awon omo egbe naa se ni ilu Londoonu (London) laipe yii.

Ninu atejade ti won gbe sita lehin ipade naa, Awon Yoruba ni Idale so pe ohun meji to je iran Yoruba logun ninu eto isakoso orile-ede Naijiria bayii ni awon gomina won fe bi danu sigbo nitori imo ti ara eni-nikan won.

Ohun meji ni won so pe o se pataki si iran Yoruba lasiko yii nipa oro oselu ile Naijiria. Nnkan meji yii naa ni:

~ Pipada si eto ijoba alagbegbe (regional government) ati

~ Eto isakoso elegbejegbe teekoto (Parliamentary system)

A o se iranti pe awon gomina ijoba PDP nile Yoruba ko fi ara ma igbese mejeeji yi eyi ti awon omo Yoruba to se apero ni Eko fenuko le lori (E wo Afonrere Yoruba fun ekunrere alaye lori oro yii).

awon to fi owo iwe ajoro lehin ipade Omo Yoruba to wa ni Idale se ni Londoonu yi ni Omowe Ayo Owoade, Ogbeni t. Akinola, Otunba M. Akinfolarin, Ogbeni i. Akinjobi, Ogbeni F. St James, Ogbeni R.O. Ajiboye ati Alhaji O. Musa.

Awon Asoju Yoruba gbe iwe apileko kale nibi Apero ti n lo l'Aabuja: Won n beere oloopa fun ijoba Ipinle (Lati owo Jare Ajayi)

Awon ti ijoba yan lati ile Yoruba lo si Ajoro lori atunse oro-oselu ati oro-aje ile Naijiria (National Conference on Political and Economic Reforms) ti n lo lowo ni ilu Abuja ti se agbekale iwe apileko kan eyi ti won pe ni ‘Erongba Guusu Iwo-Oorun’ ile Naijiria (South West Agenda).

Iyato wa ninu ohun ti iwe yii n so pelu ‘Erongba Yoruba’ ti awon omo Yoruba to se ajoro ni gbagede Onikan, Eko laipe yi fenuko le lori gege bi ohun ti gbogbo awon ti yoo ma soro loruko Yoruba gbodo maa fi se orin ko.

Pataki lara awon ohun ti apileko ti won gbe kale ni Abuja lojo Aje (11/04/2005) soro le lori ni iru eto ijoba ti o ye ki Naijiria gun le, gbigbe ofin ro, iye eka ijoba to ye ko wa, fifi oruko egbe oselu sile ati beebee lo.

Oju ewe merinlelaadota (54) ni iwe ti a wi yi gba, awon asiwaju asoju ipinle kookan lati ile Yoruba lo si fi owo si iwe apileko naa. Oruko won ati ipinle ti won ti wa ni Oloye S.K. Babalola (Ekiti), Alhaji Olufemi Lateef Okunnu (Eko), Omooba Bola Ajibola (Ogun), Ajagunfehinti Akin Aduwo (Ondo), Adajofehinti Bola Babalakin (Osun) ati Oloye Richard Akinjide (Oyo).

Koko ohun ti iwe naa n so ni:

Eto isakoso Eto ijoba aare apase-waa (Presidential system) ni won fi ara mo. Iru eyi ti a n lo lowo bayii. A o se iranti pe ijoba elegbejegbe tabi alajo tee koto (Parliamentary) ti won n lo ni ile Geesi (Britain) ni agbarijo awon Yoruba fi enu ko ninu apejo won to waye ni ilu Eko. Iru eto ijoba ti a wi yii ni Naijiria n lo tele ki o to di pe awon ologun gba ijoba ni odun 1966. Oye ti awon to n pepe fun pipada si iru eto yii wo ni pe ko fi aye sile fun fifi agbara ‘tani yoo bi mi’ sile to bi o se wa nibi aare-apase-waa.

Gbigbe ofin ro Iwe apileko awon ara Abuja bere fun olopaa onipele meji. Okan ti yoo je ti ijoba apapo ni yoo ma mojuto ofin ijoba apapo nigba ti olopaa ijoba ipinle yoo ma mojuto ofin ijoba ipinle.

Egbe Oselu Iwe naa so pe fifi oruko egbe oselu sile lodo ijoba ko gbodo ni kolofin kan. Eyi ni pe awon to ba ti ko ara won jo, ti won so pe egbe oselu ni awon naa ni ki ijoba yonda fun lati maa se ohun ti awon egbe oselu yoku n se labe ofin.

Sugbon awon egbe oselu wonyi ko gbodo gbojule owo lati odo ijoba fun akitiyan won. Won gbodo le da duro nipa sise eto owo laarin awon omo egbe won ni.

ase, awon to ko ara won jo naa gbodo ni oofiisi ni bi ipinle merinlelogun ati awon nnkan ‘gbodo ni’ miran.

Akapo ijoba Iwe naa tun n fe ki Akapo asunwon ijoba apapo (federal government) o wa yato si Akapo asunwon ijoba gbogbogboo (government(s) of the federation).

Kabiosi fun alakoso ijoba (Immunity) Ero awon asoju wonyi ni pe abala Iwe Ofin ti o soo di eewo lati pe aare, gomina ati igbakeji won lejo lori ohun ti won ba se niwon igba ti won ba wa lori aga ijoba gbodo je atunyewo. Won beere fun atunse abala yii ki o le baa see se lati ye won lowo wo bi won ba ti n si ipo won lo.

Asoju Loju awon asoju wonyi, egbe oselu to ba ni ibo to po ju ni ki o maa se akoso ijoba (winner-take-all arrangement). Ko gbodo si pe awon egbe yooku yoo ni omo egbe won ninu ijoba ni ibamu pelu bi won se tewon si lodo awon oludibo. Labe ijoba tee-koto (parliamentary), gbogbo egbe to ba ni ibo to joju die ni yoo ni asoju ninu ijoba. O kan je pe egbe to ni ibo to po ju ni yoo maa dari ijoba ni.

Eka ijoba Awon ara Abuja ko tun faramo ete ati pada si eto ijoba agbegbe onisori-n-sori (regionalism) eyi ti apejo ti ilu Eko fi owo si. Ero awon ara Abuja ni pe opon ti sun koja asiko ti a lo iru eto ijoba yen. Won woye pe ko si ohun to buru nibi eto ijoba ipinle ti a n lo lowo yii. Sugbon won gba pe ki ijoba ibile wa; ati pe ijoba ibile wonyi gbodo wa labe akoso ijoba ipinle ni.

O se pataki ki a ran ara wa leti pe awon to n pepe fun ijoba agbegbe ko so pe ki ijoba ipinle ati ijoba ibile pare. Won ni o ye ki Naijiria ni eto ijoba onipele merin; ijoba apapo/gbogbogboo (federal government), ijoba agbegbe (regional government), ijoba ipinle (state government) ati ijoba ibile (local government). Ni bayi, ijoba onipele meta la ni; apapo, ipinle ati ibile.

Awon elegbejegbe, ologbajogba ati awon eya orisirisi lo n fi iwe apileko (memorandum) rannse si ajo ti n se Apero ni ilu Abuja.

Eyin onkawe waa yoo seranti pe awon gomina ipinle kookan lo yan awon asoju mefa-mefa lo si ibi apero yii ti Aare Olusegun Obasanjo si yan bi aadota awon miran kun won. Irinwo ni awon ti n jokoo apero naa. Osu meta ni ijoba fun ijoko naa lati fi se ise re.

 

This text will describe the picture above.

Konyin, ape-itewe n wo oja agbaye

 

Lati owo Jare Ajayi

 

Laipe, ape-itewe (keyboard) eyokan-soso yoo le te iwe edekede to wu ki eniyan fe te ni agbaye. Iyan ede ti o ba je pe alifabeeti ikowe re da lori leta ti o je jade lati inu ede Latin. Ede Yoruba ati awon ede miran to wa ni ile Naijiria lo je pe iru alifabeeti ti a wi yii ni won n lo.

Ohun to je nnkan iwuri nipa oro yii ni pe awon omo Oodua ni won wa ni idi bi ape pataki yii se wa si aye ati bi yoo se di ohun ti mutumuwa n lo kaakiri agbaye.

Olobo to so Afonrere Yoruba fi han pe awon ede to je gbajugbaja gege bi ede Oyinbo (Geesi), Faranse, Jamani, Potugi, Giriiki, Latin, Sipaniisi, Rosia ati bee bee lo ni ape yii yoo see lo fun.

Ile-ise onimo ero ode oni kan ti oruko re n je Lagos Analysis Corporation (Lancor) ni o se agbejade ape yii. Ilu Boston ni orile-ede Amerika ni olu ile-ise yii wa. O tun ni eka pataki ni ilu Eko ni orile ede Naijiria.

Ogbeni Adejumobi Oyegbola ati Ogbeni Walter O. Oluwole   ni won je oludari ile ise ti a wi yii. Enikeeta won ti o je alabojuto ni Ogbeni George C.K. Van-Lare.

Ilu Eko ni won ti bi Ade Oyegbola nigba ti Walter je omo ilu Sagamu ni ipinle Ogun.

A o se iranti pe Afonrere Yoruba ti gbe oro jade nipa awon eniyan yii tele nigba ti a n soro nipa ape itewe won eyi ti won pe ni Konyin.

Pelu ape yii, eniyan le ko iwe ninu ede gbogbo to wa ni Naijiria – bi o ba ti je pe alifabeeti ede Latin ni ede naa fi n kowe.

alifabeeti ikowe ti o da lorii A B D ati bee bee lo gege bi Yoruba,  Igbo, Geesi, Faranse ni apere alifabeeti to da lori ede Latin ti a n so.

Orisi ona ikowe miran to wa ni agbaye ni ti Arabiiki, Sainiisi (Chinese), Japaniisi (Japanese to je pe o fi ara pe Sainiisi) ati bee bee lo. Omiran ni Heeburu Hebrew.

Lowo bayii, igbese ti n lo lowo lati ri pe ape titun yi bo si ori igba ni awon ilu nla-nla kaakiri agbaye.

A o mu ekunrere alaye nipa ile ise Lancor ati paapaa julo awon to se agbekale nnkan pataki yii wa fun yin laipe. E ku oju lona. Ire o.

 

OPA n mura fun ayeye odun kewaa

Egbe kan ti idagbasoke agbegbe Oke ogun je logun, Oke Ogun Progressive (USA) Incorporated n gbaradi fun ayeye odun kewaa ti o ti di dida sile.

Ojo kokandinlogbon osu kokanla (osu Belu) odun yii ni ayeye naa yoo waye.

Agbegbe Queens ni ilu New York ni ayeye naa yoo si ti sengere.

Awon omo-bibi agbegbe Oke ogun ni ipinle Oyo ni o da egbe yii sile. Gege bi alukoro egbe naa, Ogbeni Sunday Adegbola se fi to wa leti, ona ati ri pe, “ a ko ara wa jo, a si jo n se asepo, a si tun n jiroro lori idagbasoke enikookan wa ati ti ilu ti a ti wa” ni o se okunfa dida egbe yii sile.

Lenu igba ti egbe yii di kikojo, opo nnkan idagbasoke lo ti gbe se. Pataki ninu eyi ni iranlowo owo goboi ti won n fun awon akekoo to wa ni ile-eko giga ni Naijiria. Egberun meedogbon naira ni won n fun akekoo kookan lodoodun. Akekoo bii metala ni n je anfaani yii lodun kan. Titi ti akekoo bee yoo si fi pari eko re ni ile eko giga ni yoo ma je anfaani naa niwon igba ti o ba ti n se daadaa ninu eko re. Odun bii merin sehin ni eto pataki yii ti bere.

AfonrereYoruba ri gbo pe egbe naa yoo maa se iranlowo fun awon omo egbe to ba jade ile iwe ni Amerika paapaa bere lati odun yii lo.

Lara awon to se agbateru egbe yii ni Alagba Tolani Ogundiran ti o je Aare egbe naa ki o to di oloogbe ni odun 2004, Ojogbon Segun Odesina, Alhaji Yekini Salami, Oloye R. Adedokun Atitebi, Diakoni Timothy Ayinla, Ogbeni Toye Okesola, Alhaja Yinka Atitebi, Oloye Yinka Ayedun, Ogbeni Sunday Adegbola, Alhaja Adunola Salami, Ogbeni Adejare Adeyemo ati Alagba Olaleye.

Lara awon ti won tun dijo n gbe egbe yii ro ni Iyaafin Ayinla, Ogbeni Ajiboye Omodewu,  Iyaafin Kikelomo Towobola, Ogbeni Oyetunde Adesola Ige, Iyaafin Oladiwura Okesola, iyaafin Foyeke Adeyemo, Ogbeni Akande, Iyaafin Oladokun ati Iyaafin Akande, Alhaji Mututau Towobola, Ogbeni Wole Oladokun ati awon jannkan jannkan miran.


Egbe omo Igbeti ni Amerika yoo sise idagbasoke si ilu won ni Naijiria

Awon omo ilu Igbeti to wa ni orile-ede Amerika ati Canada ti pinnu lati pawopo se ise idagbasoke to wu'ni lori si ilu naa.

Afenuko yii waye nibi ipade ti awon omo egbe naa ma a n se ni ibujokoo won ni Amerika.

Nibi iru ipade olosu metameta naa ti won maa n se eyi to waye ni ojo kewaa osu kefa odun yii ni ile Iyaafin Abiodun Ojo (omo Oladele ile Kooko, Igbeti), awon omo egbe fi enu ko lati fi ile won ti won sese ra ko gbongan idagbasoke ati ti igbafe.

Oju ona Doogo ni Igbeti ni ile naa wa. Ni nnkan bi odun ti n bo ni ise yoo bere lori ile naa gege bi erongba won.

Egbe fi ami eye da awon omo ti o ka iwe de ibi to ni apere nibi ipade naa. Lara awon to gba ami eye yii ni Segun Ayinla to gba iwe moyege digiri elekeeji (Masters degree) laipe yii. Elomiran ni Joke Odesina ati awon meji miran.

Lara awon to wa nibi ipade naa ni Diakoni Timothy Ayinla, aare egbe, Ogbeni Yemi Odesina, akowe egbe ati Ogbeni Sunday Adeyemi Omoloyin to je akapo egbe.

Awon miran ni Ogbeni Paul Ayoade Ogunbiyi, Ogbeni James Idowu, Diakoni Lydia Oludele, Iyaafin Ayinla, Ojogbon Segun Odesina, Iyaafin Idowu, Iyaafin Modupe Akinsuyi, Iyaafin Bimbo Odesina ati bee bee lo. 

ORO SUNNUKUN: Ibo ni aabo wa ni Naijiria bayii o?

 

Jijabo baalu Beelifiu (Bellview) laipe yii ni Naijiria ati Ghana, jijabo baalu Sosoliso, ijamba oju popo pelu aburu ti awon ole n se lojoojumo ti mu ewu to wa ninu igbesi aye ni orile-ede Naijiria  di ikaya bayii o.

Nigba ti baalu Beelfiu jabo ni ojo kokanlelogun osu kewaa odun yii, eniyan ogofa o din meta (117) lo padanu emi won ninu re. Bi o ba je pe oru ati abule kan ti won n pe ni Lisa Orile ni Ipinle Ogun ti isele yii se si ni ko je ki awon to wa sagbako naa ri iranwon, ki ni ki a ti so ti ilu Pota ti o je ojumomo ti o si tun je inu papako ofurufu (hiapooti) gan-an lo ti sele. Aadofa eniyan o din eyokan (109) ni a gbo pe o wa ninu baalu Sosoliso to jabo ni ojo kesan-an osu kejila ti a wa yii ni ilu Pota (Port Harcout) nigba ti eniyan bii meta pere ru isele naa la.

Awon omo ile iwe alakobere to n lo bi ogota lo ba isele ti Sosoliso rin. O je ohun edun okan pe oko panapana ko ri nkankan se nibe, bee ni awon eniyan si n wo bi baalu naa se n jona pelu awon to wa ninu re. Ori lo tun ko awon arinrinajo yo ni orile-ede Ghana nigba ti baalu Beelfiu miran se digbadigba ni ojo kejidinlogun osu kejila ti n pari lo yii.

Isele ijamba moto ninu eyi ti opo emi ti n sofo ni ona Ibadan si Ilorin, ona Ibadan si Eko ati awon agbegbe miran po debi pe iwe irohin ati redio oun telifisan ko lee ma so won lopo igba mo. Idi aabajo ni pe  ifoya yoo ti po ju fun awon ara ilu.

Bee naa ni oro ti awon adigunjale.

Se eyi ti n sele ni oju popo ni ki a so ni tabi ti aarin igboro. Se ti awon eyi to wa n ka’ni mo’le loru ni ki a wi ni, tabi ti awon ti n pade eniyan lona ati ninu moto ti won n fi ipa gba ohun-ini lowo eni la o rohin?

Laipe yii - paapaa julo lenu igba ti owo korensi titun elegberun kan (N1000) de - ise aburu awon gbomogbomo tun peleke si. O ni iye emi to ti run lori eleyiini.

Ni agbegbe Oke ogun, isele awon Bororo ati awon eya miran ti n dana pelu ipa ti n le kenka debi pe ati maa so oro nipa re lojoojumo yoo so adugbo naa lenu. Gege bi igba ti eniyan n rohin isele ole jija ni ona Lokoja ni.

Bi ese ko se see rin , ti oko oju popo lewu, ti ko si oko oju irin mo yii, ona wo ni a fe maa fi lo lati aye kan de ibo miran?

Awon to lowo ti irin won si je mo kiakia gbiyanju oko ofurufu. Sugbon kini a tun n ri nibi eleyii? Ijamba gbogbo igba.

Gege bi a si ti mo, ijamba oko oju orun ko dabi ti oko ile. Bi awon eniyan to wa nibe ko ba jona, ipaya ojiji yoo ti mu emi won lo ki o tile to di pe won ri iranwo kankan gba.

Se ese wa lo po to bayiii ni abi  ohun kan paato ti wo awujo wa ti n fa isele buruku wonyi?

Gege bi a ti ba ninu itan, bi oro ba n ri bayii laye atijo, ohun ti awon omo eriwo maa n pe si ni.

Bayii nko - n je awon ti o ye ko dide huya ka oro kun bayii? Nje won tile n fi han pe awon mo oro yii ni oran bi?

Nje won ni oye, ogbon ati ohun gbogob to ye ni ikawo lati fi koju ipeni-nija ti n sele yii?

Bi igbese ti awon olori wa ti n gbe lenu loolo yii yoo ba je apere fun wa, ko jo pe won mo riri ohun ti n sele. Bi won ba si mo, ko jo pe won setan lati se nnkan to ye nipa re. Bi o ba si je pe won n se nnkan nipa re - pe oro ko kan ti i lojutu ni - a je pe won ko kun oju osunwon niini.

Bi a ba si fi eniyan je oye awodi sungbon ti ko lee gbe adire, ki loku? Ki o fi ipo sile ni. Se akukuu-joye san ju pe enu mi ko ka ilu lo.

Ofo ti n ja lu wa yii ti to. Ki awon ti oro kan ta giji, bi bee ko, ki won ko angara won. Idagiri ko gbodo tun da wa nileyi mo o.

 

Sise ijoba eleeketa: Abuku to le kenka

Apere miiran nipa aisedeede Alawodudu

Ko je titun mo pe ete n lo lowo lati ri pe Ogagun Olusegun Obasanjo tun gbe igbese lati maa ba isakoso ijoba orile-ede Naijiria lo gege bi Aare lehin odun 2007.

Bi o tile je pe eni ti oro kan ko ti i so yanya pe oun yoo se tabi oun ko nii se, o ti n han pe ohun to jo bee wa ninu awon kan. Olobo to so Afonrere ni pe awon Oyinbo ati awon alagbara miran ni agbaye n woye oro ti n lowo naa pelu erin muse.

Won n so fun ara won pe 'a o wi?'.

Iredi abajo ni pe awon oyinbo gbagbo pe ko si eniyan dudu kan to le duro gege bi akin ki o gbe ifekufe aye ati ti ipo si egbe kan ki o si duro wamuwamu bi gbangba ba dekun ti kedere si bee wo. Won ni ko si eniyan dudu kan ti ko ni ohun ti o le ra a. Oloye Nelson Mandela to fi ipo Aare sile lai si titi gbon-on gbon-on je kayeefi fun awon to ti so pe 'Alailoju ti ni awon dudu'.

 

Idarudapo Egbe Afenifere: Ifasehin fun Ile Yoruba

 

Asiwaju ile Yoruba, Oloye Abraham Adesanya ti kede pe gbogbo iporogan ti n sele ninu egbe Afenifere gbodo dopin.

Ilu Eko lo ti pa ase yii nigba ti n kominu lori gbonmi-si omi-o-to ti n waye ninu egbe pataki ti o so gbogbo omo Yoruba po yii.

Se a o se iranti pe egbe naa ti pin si meji lowo bayii. Oloye Fasoranti lo n se asiwaju iko kan nigba ti  Oloye Ayo Fasanmi n se oludari ekeji.

Iporogan yii lo mu ki iko mejeeji kede riro ara eni legbe fun igba die. Fun apere, iko kan kede yiyo Oloye Fasanmi ati Ogbeni Yinka Odumakin loye, nigba ti iko keji naa ta pe oun yo Oloye Fasoranti ati awon miran kuro legbe.

Awon iko kan n so pe ete Ogagun Olusegun Obasanjo lati tun maa ba ijoba eleeketa lo lehin ti saa re ba pari ni odun 2007 lo fa sababi iporogan ti n waye ninu egbe Afenifere.

Awon to n so eleyii so pe iko Afenifere kan ko fi gbogbo ara lodi si ki Obasanjo tun maa se e niso. Apere eyi han ninu ipade ti won ba awon iko oloselu lati iha Ila Oorun ati Gusu orile-ede yii se laipe. Nibi ipade yii ni awon olukopa ti fi aake kori pe ipo Aare orile-ede Naijiria ko gbodo kuro ni guusu. Se awon ara oke Oya (to wa ni Aarewa) ti n logun pe ipo Aare gbodo pada si odo awon.

Awon oluwoye n so pe ete ti Obasanjo ati awon isongbe re n pa ni pe bi won ba ti fi idi re mule pe ki ipo Aare duro si iha guusu Naijiria, eyi yoo fun ogagun naa ni anfaani lati tun le so pe oun yoo tun maa ba ijoba lo. Eyi lo fa gbogbo kirakita lati se atunse si Ofin Konsitusan ile wa. Orisi ona metalelogorun-un ni won ti fe se atunse ti a wi yii. Ikan lara re ti won si tepele mo ni ti iye igba ti eniyan le lo lori aleefa ijoba. Nipa sise atunse ti a wi yii le fun Obasanjo laye lati tun maa ba ijoba lo.

Amo sa o, opo awon omo ile Naijiria ni ko gba. Won ni ete yii ko lee jo. Paapaa julo nigba to je pe asiko ti ajagunfehinti Obasanjo ti n se akoso wa ko fi bee rorun lo titi. Ki ni ohun pataki to tun fe fa ki o tun maa ba ijoba lo?

Awon ti o wa lehin Obasanjo ko dake sa o.  Won ni o se pataki  ki eto ijoba olori-jori ti Obasanjo gun le maa te siwaju. Won ko si fe ki enikan lasan gun ori aleefa, ki onitohun ma baa wa fagile awon eto naa.

Ni bayii, Oloye Adesanya, eni ti o ti fi akoso Afenifere sile latari ojo ogbo to ti de ba, so pe iwa omugo ati ika-inu ni yoo je fun enikeni lati so pe ki Obasanjo tun maa ba isakoso ijoba lo.

O so pe awon omo Yoruba ta ko Ogagun Sani Abacha nigba ti ko fe gbe ijoba sile. "E e wa tije ti a o so pe Obasanjo ko gbodo lo nisisiyi?"

Awon iko ti o lo se ipade pelu awon ara ila-oorun ati guusu n so pe awon iko ti Fasoranti to tako awon n se eleyii nitori pe won fe ba Igbakeji Aare Atiku Abubakar se po ni. Ona ti won si fe e fi se eyi ni nipase Gomina Bola Tinubu ti Ipinle Eko. Sugbon awon iko Fasoranti so pe iro to jinna si otito ni eyi.

Aigbora-eni ye yii ko sunwon nile Yoruba. Ifasehin gbaa si ni yoo je.

AfonrereYoruba ko ri idi ti o fi ye ki enikeni tun pe ipe fun itesiwaju ijoba Obasanjo lehin to ba ti lo saa re tan ni 2007. Akoko, ohun ti ofin la sile niyi. Eekeji, awa omo Yoruba ni a ma n pariwo pe awon kan fe taku si ile ise ijoba won ko fee lo. Kini de ti a o wa gba iru iwa buruku yii laye? Se nitori won bi Obasanjo ni ile Yoruba? Ojusaaju ni eyi - ti ko si ye omoluabi.

Sugbon ju gbogbo re lo, iru adun wo ni ijoba Obasanjo ti mu wa ni paato si orile-ede Naijiria ati ile Yoruba lati igba ti o ti n se akoso?

Awon nnkan wonyi lo ye ki a gbe yewo lati mo ibi ti a n lo.

 

 

Isakoso ijoba mehe pupo ni agbegbe wa nibi

 

Ogbontagi aja-fun-eto omoniyan kan, Ogbeni (Komureedi) Mashood Erubami ti ke si ijoba ipinle Oyo lati ji giri ki o si je ki awon ara ilu tubo je igbadun to wa minu ijoba tiwantiwa ju ti atehinwa lo.

Komureedi so oro yii ni ilu Ibadan latari  abajade iwadii irohin kan ninu eyi ti awon omoran kan ti se agbeyewo ise ti awon ijoba ipinle gbogbo ni orile-ede Naijiria se fun igbaye-gbadun awon ara ilu.

Ninu abajade iwadii ti a wi yii, ijoba ipinle Oyo ni o wa ni ipo karun-unlelogbon ninu gbogbo ipinle to wa ni orile-ede yii pelu Abuja. Ijoba Ipinle Taraba lo gbehin, nigba ti ijoba ipinle Bayelsa ko kopa ninu eto agbeyewo naa.

Sugbon ijoba Ipinle Oyo ti da hee abajade iwadii naa. Nigba ti o n ba Oloye Gbode soro lori oro naa, akowe-irohin fun Gomina Rasidi Ladoja, Ogbeni Adeola Oloko so pe abajade iwadii naa ki i se ohun ti eniyan le ka kun.

O mu wa si iranti pe iru iwadii yii to waye ni odun to koja gbe ipinle Oyo soke gidi.

“Se o wa je pe a sun lati igba naa, a ko se nnkankan mo ni? Se a ko se nnkan ni Gomina wa gba ami eye ‘o pegede’ eyi ti egbe awon oluko fun ni Abuja ati ni Ibadan?”.

Oloko so siwaju pe i i se agbejade ajo kankan ni ijoba Ipinle Oyo fi n se odiwon ise re.

“Awon eniyan Ipinle Oyo lo le so bi a se n se si. Bi eyin naa ba si lo wadii lenu awon eniyan nigboro, e o ri pe orin ‘e ku ise, e ku aseyori lotun-losi’ ni e o maa gbo ti won n ko ti Gomina ti Olohun fi jinki Ipinle Oyo fun ise takuntakun ti n se”.

Ijoba Ipinle Enugu labe akoso Gomina Chimaroke Nnamani lo wa ni ipo kinni, nigba ti ijoba abele olu-ilu orile-ede yii Abuja FCT wa ni ipo keji. Ijoba Ipinle Osun lo se ipo keta.

Ajo ti n se amojuto sise eto idagbasoke labe ijoba apapo orile-ede yii National Planning Commission pelu awon ajo kan lo se ni agbeyewo ti a wi yii. Egbe Alaburanda PDP ni n se ijoba ni Abuja, oun naa ni n se ijoba ni ipinle Enugu ati ni Oyo.

Awon ajo agbaye to pelu ajo-orile-ede wa lori agbeyewo yii ni Ajo ile Geesi lori Oro Idagbasoke, British Department for International Development (DFID), Banki Agbaye (World Bank), Eka Ajo Agbaye lori Oro Idagbasoke, United Nations Development Programme (UNDP);  Ajo ile Amerika ati ti  orile-ede Kanada fun idagbasoke ni Okeere, United States of American International Development (USAID) ati Canadian International Development Agency (CIDA).

Ohun merin pataki ni won fi se agbeyewo ni awon ipinle ti a wi wonyi. Nnkan merin naa ni eto isuna ati imulo re lona eto (budget and Fiscal Management) bi ise (Ijoba) se n jafafa to

(service delievery), eto iba-ara-eni soro lona ti ode oni (communication) ati sise ohun gbogbo laini kolofin ninu (transparency).

Ida mejidinlogota o le die ni ijoba ipinle Enugu gba ninu odiwon ogorun (57.22%) nigba ti ijoba ipinle Oyo gba metalelogun o le die (23.52%) ninu odiwon ogorun-un.

Ki i se Oloko nikan lo da hee abajade iwadii ti a wi yii. Amugbalegbeee gomina lori eto irohin, Omo-oba Ade Adekanmbi so pe abajade naa ko ni ese nile.

Ki i si i se ohun to ye ki eniyan le ponle.

E wo apoti to wa ni isale yii fun ipo ti ijoba ipinle kookan wa.

 

 Aseyin dagbere f'aye

 

Aseyin ti ilu Iseyin, Oba Ganiyu Abimbola Ariwajoye Keta ti re iwale-asa.

Ojo ketadinlogun osu kokanla odun yii ni Kabiyesi waja.

Ile adani re to wa ni ilu Eko ni oba ti dake.

Ojo Abameta, ojo ketadinlogun osu kejila ti a wa nibe yii ni won yoo gbe oku kabiyesi lati Eko lo si ilu Iseyin.

Basorun ilu naa, Oloye Raimi Oyegbemileke Adelodun Keji so pe gbogbo awon to ye ko mo nipa wiwaja oba, gege bi ijoba Ipinle Oyo ati ti ijoba ibile Iseyin, lo ti mo.

Olukaluku si ti n gbaradi fun isinku kabiyesi naa.

Kete ti won ba ti gbe oku de ni ayeye isinku yoo ko.

Ki Alayeluwa Ganiyu to joba, osise ile ifowopamo (banki) ni i se. Ilu Eko ni o si  fi  se ibugbe ki o to gun ori ite awon baba re. 

 

 

IWA RERE L'ESO ENIYAN - E je ki a maa se rere!

AfonrereYORUBA: Fun ipolongo, imugbooro ati ilosiwaju Yoruba kaakiri agbanla-aye. E-mail: afonrereyoruba@yahoo.com