Tunde Odunlade fi ona dara, Abiodun Koya fako yo
Oloju-ona kan tii tun se onkorin, Omo-oba Tunde Odunlade tun gbe Naijiria niyi nibi ayeye pataki kan to waye ni ilu Washington
D.C. ti i se ibujokoo ijoba ile Amerika.
Ayeye yii waye ni ojo'Bo ojo keedogbon osu karun-un odun ti a wa nibe yii.
Ogunlogo awon eniyan lo wa sibe pelu asoju Akowe Ajo Agbaye Kofi Annan ati Aare ile Amerika, George Bush.
Odunlade se afihan awon ise-ona to se ni Naijiria ati ni ile Amerika nibi.
Ojo ti a wi yii ni won n se asekagba 'Ose Afrika' to ti bere ni ojo kokanlelogun osu karun-un.
Omo Oodua kan, Abiodun Koya naa gbe Yoruba ati Naijiria pelu alawodudu laruge nibi ayeye yii nipa kiko orin oriki (anthem) ile
Amerika ati ti ile alawodudu wa Afrika nibe. Gbogob eniyan lo patewo pelu idunnu nipa ona ara ti arabinrin yii fi ko oriki
orile wonyi.