Make your own free website on Tripod.com

Afonrere YORUBA Gbode

Soyinka, Elebuibon fowo si ede abinibi ni ile igbimo asofin
Abawole Home Bonvenido Bonvenu | Igbelaruge Yoruba | Irohin Lakotun | oloyenewsgbode.tripod.com | Konyin, opon-itewe titun wo'ja agbaye | Irohin | Irohin | Iforowero Interview Page | Ikede | Photo Album Page | Leta Mailbag | E kowe si wa lori ero okan yin tabi nipa Yoruba: afonrereyoruba@yahoo.com E seun | Archives | New Page Title

Enter subhead content here

Soyinka fowo si lilo ede Yoruba ni ile Igbimo Asofin

 

Ojogbon Wole Soyinka ti so pe ohun to dara gbaa ni ki awon asofin wa maa lo ede abinibi lati maa fi se eto nibi ijokoo won.

Ile eko giga Fasiti Obafemi Awolowo to wa ni Ile Ife ni Soyinka ti so oro yii nibi apero kan ni ipari ose to koja.

A o se iranti pe awon ile igbimo kan ni ile Yoruba ti mu ede Yoruba kun ede Oyinbo lati maa  fi seto nibi ijokoo won.

Lara awon ile asoju-sofin wonyi ni ti Eko, Oyo ati Osun.

Onigege ara naa, Soyinka, so pe ona pataki lati mu iwuri ati agbega ba ede abinibi ni lilo ede naa lati fi se eto ijoba – lafiikun si lilo ede wonyi ni ile eko ati bee bee lo.

 

Elebuibon fe amugbooro asa ibile

 

Awise ilu Osogbo, Oloye Ifayemi Elebuibon ti ke si awon omo bibi ile Yoruba nile ati ni idale lati dekun ati maa fi ede ati asa won tayin.

Ilu Ibadan ni Elebuibon ti pe ipe yii nigba ti o n soro nibi ayeye Odun Ose Meji eyi ti awon elesin ibile ti ilu Ibadan se agbekale re.

Ile Asa Ibile to wa ni Mokola, Ibadan ni idanilekoo ti waye nibi ti Elebuibon ti fi ero okan re han.

 O so pe ki awon obi ri pe won n so ede Yoruba si omo won ninu ile “nigba to je pe ede okeere ni won yoo fi maa ko awon omo wonyi ni ile iwe.”

O so siwaju pe ohun to dara ni bi awon ile igbimo asofin bii meloo kan ni ile Yoruba ti fi enu ko lati maa lo ede naa lenu ise won.

Elebuibon so pe awon omo orile-ede miiran gege bi India, Saina ati bee bee lo kii tiju ede tabi asa won.

“Mo lo si ofiisi ore mi kan ni Chellarams laipe yii. Mo ri ti o so imo ope si abawole ofiisi naa. Mo beere pe bawo lo se je. O ni ara asa awon ni. Sise bee je ara isora. Nje meloo ninu wa lo le se eleyii ni ile ki a to so pe ofiisi wa? Oju yoo ma ti w ape awon to ba ri iru nnkan bayii yoo so pe a n se ebo. Bee, ebo wa loto, igbagbo ati asa wa loto.”

 

Enter supporting content here

AfonrereYORUBA: Fun ipolongo, imugbooro ati ilosiwaju Yoruba kaakiri agbanla-aye. E-mail: afonrereyoruba@yahoo.com