Make your own free website on Tripod.com

Afonrere YORUBA Gbode

Irohin Lakotun

Abawole Home Bonvenido Bonvenu | Igbelaruge Yoruba | Irohin Lakotun | oloyenewsgbode.tripod.com | Konyin, opon-itewe titun wo'ja agbaye | Irohin | Irohin | Iforowero Interview Page | Ikede | Photo Album Page | Leta Mailbag | E kowe si wa lori ero okan yin tabi nipa Yoruba: afonrereyoruba@yahoo.com E seun | Archives | New Page Title

 Idibo ti n bo ni Naijiria: Awon omo Naija loke okun pe ejo 

Ki i se ohun ti a ni lati so mo pe pataki ni ibo ti n bo yii je fun gbogbo omo Naijiria nile loko lodo ati lehin odi. 

Eyi lo mu ki awon omo orile-ede naa to wa ni oke okun maa se akitiyan lati ri pe awon ni anfaani lati di ibo nibikibi ti o wu ki awon wa. Kiko eti Ogbonyin si arowa yii  ti je ki awon omo orile ede naa bii meloo kan gbero ati pe ajo ti n se konkari eto idibo naa INEC lejo.

Lara awon to ti fi owo si ejo pipe yii ni 

1. ODIDI, Isa; Okunrin omo aadota odun ti n gbe Kanada; Omo bibi ipinle Kano ni i se

2. BELLO, Akeem; Omo odun metalelogoji ti n gbe Amerika (USA); Ipinle Ogun ni won ti bi.

, 3. ALUKO, Mobolaji E.; Omo odun mokanlelaadota ti n gbe Amerika, USA; Ipinle Ekiti lo ti wa.

 4. OBI, Uzoma C. ti i se omo odun ketadinlogoji. Ipinle Imo lo ti wa sugbon Amerika lo n gbe bayii

 AKINSANYA, Adeoye je omo odun mejilelogota, Ipinle Ogun ni oun ti wa sugbon Amerika ni o wa lowo yii na.

6. Omo-oba MALU, Stephen T. je omo odun mokanlelaadota, 51 Amerika lo wa sugbon omo bibi ipinle  Benue ni.

7. AWOJOODU, Lekan naa je eni okanlelaadota odun. Amerika lo n gbe bayii bi o tile je pe Ipinle Osun lo ti wa.

8. SILVA-OPE, Kolawole, E. Omo bibi ipinle Eko ni Kolawole ti i se omo okandinlogoji odun. Amerika ni oun naa n gbe.

9. ADEWUSI, Victor O.A., naa n gbe Amerika. Odun metadinlaadota lo ti pe loke eepe. Ipinle Ekiti lo ti wa. 

10. OKEKE, Alex I., Omo Ipinle Anambra to n gbe Amerika ti i si se omo odun mokandinlaadota ni Okeke.

11. Omo odun merinlelogbon ni Yemi OKE ti oun naa n gbe  Kanada; Omo ipinle Ogun ni.

12. Ipinle Delta ni NAMMOR; Tony O. ti wa si Amerika ti n gbe lowo bayii. Omo odun merindinlogoji ni

13. OGBUAKU, Ochi C., je omo odun metalelogbon 33. Dubai lo n gbe bayii.

14. ONYEMAECHI, Uzoma; naa je omo odun mokandinlogoji. Amerika ni n gbe.

15. Oluremi aya AJIBEWA, je omo odun merinlelogoji (44) Orile-ede Ilu Oba Geesi (United Kingdom) lo n gbe. 

16. Omo odun mokanlelaadota ni DADA; Emmanuel, A.; Amerika lo n gbe. Omo bibi ipinle Ekiti ni.

17. Segun AJIBULU, tii se omo odun mejilelaadota naa wa lati Ekiti. Amerika ni n gbe.

18. SERIKI, Surajudeen, ti oun naa n gbe Amerika je omo odun mejilelaadota. Ipinle Eko (Lagos) lo ti wa.

Ile-ise Agbejoro ti Femi Falana to wa ni ilu Ikeja, Eko ni Naijiria ni o ba won n se alagbawi ni ile ejo.

Awon olokada n beere iranwo ijoba

Ojo ti fee de bayii. Bi ojo ba si ti de, riri ni ile ibi ti a n gbe awon alupupu wa si maa n ri. Eyi lo je ki a maa ra owo ebe si ijoba ibile wa, Olorunsogo pe ki o ran wa lowo lati re ori ibi ti a n gbe alupupu wa si”.

Iwonyi ni gbolohun ti o ti enu awon omo egbe Olokada to wa ni Orita Ile Seriki/Baba Mogba ni ilu Igbeti jade lasiko ti won n be Oloye Gbode lowe pe ki o ba awon ke si ijoba ibile Olorunsogo to wa ni ipinle Oyo lati ba awon se kannkere si ori ibi ti won n gbe alupupu won si ni gbogbo igba ti won ba n duro lati gbe ero.

Nigba ti o n soro siwaju, alaga egbe naa ni idi Pandoro, Ogbeni Lamidi Aremu ti adape re n je Eeyan’re so pe lapo ara won ni awon ti mu owo ti awon fi tun ibudo naa se.

“Bakan naa ni a ko ara wa jo lati ko yepe ati yanrin ti a fi fe aye naa sehin, ki o ma baa di pe awon eniyan to fe gun okada wa yoo maa fi emi we ewu ni egbe titi”.

Ni idahun si ibeere kin ni nnkan pato ti won fe iranlowo le lori, agbenuso won kan ti oruko re n je Agoro naa so pe sise pepele oni konnkere ni awon n fe. “Eyi ni ko ni je ki ile naa maa gbe alupupu wa subu bi o ba di pe ojo de”

Koko ni orin, ijo ati aso wiwo ni ile Yoruba 

Awise ti ilu Osogbo, Oloye Yemi Elebuibon ti so pataki orin, ijo ati ilu ninu asa ati esin Yoruba.

Ilu Ibadan lo ti so oro naa nibi ayeye kan ti ile ise Olokoowo Oodua se agbateru re. Ojo’Bo, ojo kerinla osu Ope (osu kejila) odun 2006 ni ayeye naa waye. Ayeye yii ni won pe ni ‘Isafihan Ijo ati Ewu Yoruba’. Gbongan ajo olokoowo Oodua Investments to wa ni Ibadan ni awon tolori telemu ti se ayeye naa.

Nigba ti o n ki awon alejo kaabo, alaga igbimo to se konkari ayeye naa, Oloye Lekan Alabi so pe ayeye naa n waye lati ri pe ina asa awa Yoruba ko jmo ajorehin. O ro olukaluku lati ri pe a ko fi owo tembelu mu asa wa.

Giiwa Agba fun Ajo Olokoowo Oodua lapapo, Ogbeni Jimoh Ibrahim kin oro Alabi so pe ajo Oodua se eto yii lati fi ta awon agba Yoruba ji ati lati je ki awon odo ri ewa to wa ninu asa wa. O wa ro awon eniyan lati ri pe fifi asa ati ede yii ko omo di ohun agbe dide.

Okan lara awon eekan-ilu to tun je agbasaga to wa nibi ayeye n Oly Olşęgun Olusola gbe oriyin fun Ogbeni Jimoh lati ile-ise Oodua. O si ro won pe ki won ma se kaare lati ri pe asa ati ede Yoruba di ohun amuyangan. O ni eni to ba so asa re un, so orirun re un niyen.

Ninu iwe apilekoo re, Awise Yemi Elebuibon soro lori aye pataki ti ijo, ilu ati orin wa ni ile Yoruba.

  so pe lara orin abalaye ni sakara, apala, juju ati fuji ti jade. so siwaju pe orisirisi ilu lo wa ni ile Yoruba. Lara won ni gudugudu, dundun, bata                    aaĘęCŞşỌọ ′ ` 

 ati omele. ni awon oba ni won n lu dundun fun nigba to je pe awon Onisango lo n jo bata tele. se afiikun re pe ijo jijo maa n mu ara pe.

Lara awon aso ti Yoruba n ran ti won si n wo ni kijipa, alaborun, dandoogo, gariye, oyala, buba ati dansiki. O ni bi aso isere se wa beeni aso imurode wa.  Elebuibon se afomo re pe Alaaran ni won n pe idile awon ti n hun aso ni ile Yoruba ki o to di asiko yii ti ise naa ti wa fun teru tọmọ.

Lara awọn agbasaga to wa nibe ni Oloye (Iyaafin) Abiọdun Duro Ladipọ, Basọrun Seinde Arogbọfa, Ogbeni Owamoyọ, Ogbeni Adeolu Ojo, Tayọ Farinu ati Abimbọla Olaọje.

Ajo Osere Ipinle Oyọ (Oyo State Cultural Troupe), Ajo Osere Duro Ladiipo, awon omo ile iwe Alakobere Seven Day, ti IDC ati ti ile eko giga Adeyemi (Adeyemi College) wa lara awon to fi ijo, ilu ati orin da awon eniyan lara ya nibi ayeye naa.

Ajo OPC yoo se Apero nla fun iran Yoruba

Ajo ajijagbara omo Oodua (ti a mo si Oodua Peoples Congress, OPC) ti n gbaradi fun eto apero kan to fe se fun gbogbo omo Yoruba ni ojo kejila osu kinni odun 2007.

Ilu Ibadan ti i se olu-ilu Ipinle Oyo ni apero naa yoo ti waye, gege bi irohin to te wa lowo lati odo oludasile ajo naa, Dokita Frederick Fasehun.

Ojo iwaju Yoruba, paapaa julo lehin ti Oloye Olusegun Obasanjo ba fi ipo aare orile ede Naijiria sile ni apero naa yoo da le lori. Koda akori apero naa, ‘Nibo ni Yoruba n lo?’ fi eyi han.

Fasehun so pe ki omo Yoruba to tun je aare ni Naijiria yoo to ogoji ọdun. “O se pataki ki a mọ ibi ti a o wa ki o to di asiko ti a wi yii.”

Fasehun ni ona bi ile Yoruba yoo se wa ni ipo amuyangan to fi je pe ipo aare ni Abuja ko ni nnkankan fun wa mo ni apero naa yoo da le lori.

“A gbọdọ di ara wa ni amure ni ona ti yoo fi je pe a ko ni naani Aso Rock ni nnkan bi ogoji odun si asiko yii.”.

Ninu oro miran, Alagba Fasehun so pe ajo OPC yoo se eye fun Aare Olusegun Obasanjọ fun sise gudugudu meje yaaya mefa. Idi abajọ ni pe Obasanjọ ti se ohun ti olori orile-ede yii kankan ko se ri.

Lara ohun ti Fasehun mu enu ba gege bi aseyọri Obasanjọ ni asunwon owo okeere Naijiria to je pe ọọdun milionu dola pere ni Obasanjo ba ninu re nigba ti o de.  “Sugbọn ni bayii, o ti so owo naa di nnkan bi bilionu metadinlaadota (lati $3 milionu si $47 bilionu).

Eyi ni Fasehun se so pe Obasanjo ye ni eni ti o ye ki Yoruba se ayeye ‘kare omo odo rere’ fun. Ojo keji ojo apero ti a wi tele, eyiini ojo keta osu kinni odun 2007 si ni won fi ayeye naa si.

Amugbooro n de ba ede ati asa Yoruba kaakiri agbaye

Ni Naijiria ti i se orirun iran Yoruba ati ni idale (kaakiri agbaye) ni akitiyan ti n lo lwoo lati mu amugbooro ba asa ati lilo ede Yoruba.

A o ranti pe lati orile-ede Geesi (Briteeni) ni Omidan Omolara Wood ti se eto aagbkale egbe kan ti n je Tiwantiwa. Egbe naa to bere pelu eta woro omo-egbe ti gbopon bayii. Ilakaka egbe yii ni lilo ede Yoruba lati maa fi irohin to ara eni leti ati lati fi se itakurọsọ. Kaakiri opo ibi ti omo Yoruba ati awon to ni ife si lilo ede Yoruba ni won si ti n da si Tiwantiwa.

Egbe titun kan naa tun wa ti oruko re n je Ajo Igbimo       (AYOG). Omọwe Francis Akindele ni o se idasile re. Ona fifi oju akọmọna se iwadii nipa ede ati asa Yoruba ni ajmo naa wa fun. Awọn to ni orukọ ninu eto Eko Yoruba, ati awọn ti o je eekan ọmọ Yoruba -  koda bi ise ti wọn yan laayo ki i se ede Yoruba – ni wọn wa ninu egbe yii. Lara awon ti o ti fi idunnu won han si egbe yii ni a ti ri awon agba-ojo Yoruba bii Ojogbon Dapo Adelugba, Ojogbon Bamgbose, Ojogbon Olatunji, Ojogbon Akin Isola, Ojogbon Wale Tomori, ati beebee lo.

Akitiyan Ojogbon Toyin Falola to wa ni ile eko giga kan ni Texas, orile-ede Amerika ye ni fifi enu ba. Ise takuntakun ni ojogbon yii n se lati ri pe idagbasoke de ba ohun gbogbo to ro mo igbesi aye adulawo. Gege bi a si se mo, okan pataki ni iran Yoruba ninu awon iran ti amo si Alawodudu.

Ni Naijiria funraare, orisirisi akitiyan lo n lo lati ri pe ina asa ati ise Yoruba to jo ajorehin tele di agbedide. Lara akitiyan yii ni ti egbe kan ti a mo si Yoruba Studies Association, Egbe Akomolede Yoruba, ati ti Olokoowo Oodua eyi ti o fi idi kale si Ibadan.

A o ranti pe awon enikookan ati ile-eko giga naa n gbiyanju. Opo eniyan lo da egbe osere, ile ise irohin ati eka kiko Yoruba sile paapaa ni Amerika ati ile alawofunfun, Yiroopu.

Ni ojo aipe, a o gbiyanju lati daruko iru awon egbe ati ogba ti n se akitiyan wonyi.

Idunnu wa ni pe igbiyanju wonyi ti n ni apere. Opọ eniyan ni o ti n gba pe nnkan amuyangan ni ede ati asa wa. Akitiyan wa yii paapaa ti mu ki awọn iran miran naa bere sise ikede ati gbe ede ati asa won naa laruge.

E ma je ki ako okan aare. Iwaju ni opa ebiti waa yoo ma re si, ase.

Fiimu Kiriji

Igbaradi ti bere lati atunso gbe so itan ogun Kiriji to sele ni ile Yoruba ni nnkan bi ogorun odun o le die sehin. Atunso itan yii yoo wa ninu fiimu agbelewo eyi ti egbe kan ti oruko re n je Kiriji Cultural Foundation n gbero re.

Olobo to so AfonrereYoruba so pe ilu Imesi-Ile, Ipinle Osun ni won yoo fi se orisun fiimu yii. Sugbon gbogbo ibi ti owoja ogun yii de ni won yoo se ise de bi yiya aworan fiimu naa ba bere.

Afonrere Yoruba ri gbo pe Oloye Adebayo Faleti, ogbontagi pedepede n-ni, ni Oluforolo fun fiimu naa nigba ti Omowe Yemi Farounbi ni olugbejade fiimu naa.

‘Kiriji’ ni oruko ti won fun ogun gbogbogboo to ja kaakiri opo ile Yoruba ni ipari igbadinlegberun meji si ibere ogorundinlegberun odun (18th to 19th centuries). O to bi odun meedogbon ti ogun yii fi ja kaakiri. Awon agbegbe ti ogun yii ti fi ese mule julo ni ibiti a mo si Ekiti, agbegbe Ipinle Osun ati Ondo lonii yii. Sugbon lati igun mereerin ile Yoruba ni omimi ogun yii ti ja nitori pe o mu emi ogunlogo eniyan lo, o si mu akude ba eto oko-owo.

Oun ni ogun to le koko to si pe ju ni ile Yoruba gege bi awon onpitan enu loolo yii se fi han wa.

Adura wa ni pe ogun to ti se ko ni gberi mo, ase.

Ile iyawe-kawe (Laibiri) Amerika n wa fiimu Yoruba
 
Olobo ti ta wa pe awon ajo ti n mojuto Gbongan Iya'we-kawe (Laibiri) ti Ile Igbimo Asofin orile-ede Amerika n fe Fidio ti o ni ise Yoruba ninu.
Iru ise ti a wi yii ni eyi ti o n se ifihan asa, ise, ede, ati ohun gbogbo to je mo iran Yoruba ati bi won se n gbe ile aye won. Aworan yii le wa ninu fanran (tape), CD ati bee bee lo.
Enikeni to ba ni ohun to je mo iru nnkan bayii le kan si ile ise ti a wi yii.
Egbe apapo Omo Yoruba ni agbegbe Ariwa Amerika papaa le se iranwo fun eni ti o ba ni fanran ti a wi yii. E le kan si egbe ti a wi yii lati ipa akowe apapo won, Ogbeni Dapo Odunlami.
E le kan si afonrereyoruba@yahoo.com paapaa.
Ire o.

 Idibo ti n bo ni Naijiria: Awon omo Naija loke okun pe ejo 

Ki i se ohun ti a ni lati so mo pe pataki ni ibo ti n bo yii je fun gbogbo omo Naijiria nile loko lodo ati lehin odi. 

Eyi lo mu ki awon omo orile-ede naa to wa ni oke okun maa se akitiyan lati ri pe awon ni anfaani lati di ibo nibikibi ti o wu ki awon wa. Kiko eti Ogbonyin si arowa yii  ti je ki awon omo orile ede naa bii meloo kan gbero ati pe ajo ti n se konkari eto idibo naa INEC lejo.

Lara awon to ti fi owo si ejo pipe yii ni 

1. ODIDI, Isa; Okunrin omo aadota odun ti n gbe Kanada; Omo bibi ipinle Kano ni i se

2. BELLO, Akeem; Omo odun metalelogoji ti n gbe Amerika (USA); Ipinle Ogun ni won ti bi.

, 3. ALUKO, Mobolaji E.; Omo odun mokanlelaadota ti n gbe Amerika, USA; Ipinle Ekiti lo ti wa.

 4. OBI, Uzoma C. ti i se omo odun ketadinlogoji. Ipinle Imo lo ti wa sugbon Amerika lo n gbe bayii

 AKINSANYA, Adeoye je omo odun mejilelogota, Ipinle Ogun ni oun ti wa sugbon Amerika ni o wa lowo yii na.

6. Omo-oba MALU, Stephen T. je omo odun mokanlelaadota, 51 Amerika lo wa sugbon omo bibi ipinle  Benue ni.

7. AWOJOODU, Lekan naa je eni okanlelaadota odun. Amerika lo n gbe bayii bi o tile je pe Ipinle Osun lo ti wa.

8. SILVA-OPE, Kolawole, E. Omo bibi ipinle Eko ni Kolawole ti i se omo okandinlogoji odun. Amerika ni oun naa n gbe.

9. ADEWUSI, Victor O.A., naa n gbe Amerika. Odun metadinlaadota lo ti pe loke eepe. Ipinle Ekiti lo ti wa. 

10. OKEKE, Alex I., Omo Ipinle Anambra to n gbe Amerika ti i si se omo odun mokandinlaadota ni Okeke.

11. Omo odun merinlelogbon ni Yemi OKE ti oun naa n gbe  Kanada; Omo ipinle Ogun ni.

12. Ipinle Delta ni NAMMOR; Tony O. ti wa si Amerika ti n gbe lowo bayii. Omo odun merindinlogoji ni

13. OGBUAKU, Ochi C., je omo odun metalelogbon 33. Dubai lo n gbe bayii.

14. ONYEMAECHI, Uzoma; naa je omo odun mokandinlogoji. Amerika ni n gbe.

15. Oluremi aya AJIBEWA, je omo odun merinlelogoji (44) Orile-ede Ilu Oba Geesi (United Kingdom) lo n gbe. 

16. Omo odun mokanlelaadota ni DADA; Emmanuel, A.; Amerika lo n gbe. Omo bibi ipinle Ekiti ni.

17. Segun AJIBULU, tii se omo odun mejilelaadota naa wa lati Ekiti. Amerika ni n gbe.

18. SERIKI, Surajudeen, ti oun naa n gbe Amerika je omo odun mejilelaadota. Ipinle Eko (Lagos) lo ti wa.

Ile-ise Agbejoro ti Femi Falana to wa ni ilu Ikeja, Eko ni Naijiria ni o ba won n se alagbawi ni ile ejo.

Koko ni orin, ijo ati aso wiwo ni ile Yoruba 

Awise ti ilu Osogbo, Oloye Yemi Elebuibon ti so pataki orin, ijo ati ilu ninu asa ati esin Yoruba.

Ilu Ibadan lo ti so oro naa nibi ayeye kan ti ile ise Olokoowo Oodua se agbateru re. Ojo’Bo, ojo kerinla osu Ope (osu kejila) odun 2006 ni ayeye naa waye. Ayeye yii ni won pe ni ‘Isafihan Ijo ati Ewu Yoruba’. Gbongan ajo olokoowo Oodua Investments to wa ni Ibadan ni awon tolori telemu ti se ayeye naa.

Nigba ti o n ki awon alejo kaabo, alaga igbimo to se konkari ayeye naa, Oloye Lekan Alabi so pe ayeye naa n waye lati ri pe ina asa awa Yoruba ko jmo ajorehin. O ro olukaluku lati ri pe a ko fi owo tembelu mu asa wa.

Giiwa Agba fun Ajo Olokoowo Oodua lapapo, Ogbeni Jimoh Ibrahim kin oro Alabi so pe ajo Oodua se eto yii lati fi ta awon agba Yoruba ji ati lati je ki awon odo ri ewa to wa ninu asa wa. O wa ro awon eniyan lati ri pe fifi asa ati ede yii ko omo di ohun agbe dide.

Okan lara awon eekan-ilu to tun je agbasaga to wa nibi ayeye n Oly Olşęgun Olusola gbe oriyin fun Ogbeni Jimoh lati ile-ise Oodua. O si ro won pe ki won ma se kaare lati ri pe asa ati ede Yoruba di ohun amuyangan. O ni eni to ba so asa re un, so orirun re un niyen.

Ninu iwe apilekoo re, Awise Yemi Elebuibon soro lori aye pataki ti ijo, ilu ati orin wa ni ile Yoruba.

  so pe lara orin abalaye ni sakara, apala, juju ati fuji ti jade. so siwaju pe orisirisi ilu lo wa ni ile Yoruba. Lara won ni gudugudu, dundun, bata ati omele. ni awon oba ni won n lu dundun fun nigba to je pe awon Onisango lo n jo bata tele. se afiikun re pe ijo jijo maa n mu ara pe.

Lara awon aso ti Yoruba n ran ti won si n wo ni kijipa, alaborun, dandoogo, gariye, oyala, buba ati dansiki. O ni bi aso isere se wa beeni aso imurode wa.  Elebuibon se afomo re pe Alaaran ni won n pe idile awon ti n hun aso ni ile Yoruba ki o to di asiko yii ti ise naa ti wa fun teru tọmọ.

Lara awọn agbasaga to wa nibe ni Oloye (Iyaafin) Abiọdun Duro Ladipọ, Basọrun Seinde Arogbọfa, Ogbeni Owamoyọ, Ogbeni Adeolu Ojo, Tayọ Farinu ati Abimbọla Olaọje.

Ajo Osere Ipinle Oyọ (Oyo State Cultural Troupe), Ajo Osere Duro Ladiipo, awon omo ile iwe Alakobere Seven Day, ti IDC ati ti ile eko giga Adeyemi (Adeyemi College) wa lara awon to fi ijo, ilu ati orin da awon eniyan lara ya nibi ayeye naa.

Ajo OPC yoo se Apero nla fun iran Yoruba

Ajo ajijagbara omo Oodua (ti a mo si Oodua Peoples Congress, OPC) ti n gbaradi fun eto apero kan to fe se fun gbogbo omo Yoruba ni ojo kejila osu kinni odun 2007.

Ilu Ibadan ti i se olu-ilu Ipinle Oyo ni apero naa yoo ti waye, gege bi irohin to te wa lowo lati odo oludasile ajo naa, Dokita Frederick Fasehun.

Ojo iwaju Yoruba, paapaa julo lehin ti Oloye Olusegun Obasanjo ba fi ipo aare orile ede Naijiria sile ni apero naa yoo da le lori. Koda akori apero naa, ‘Nibo ni Yoruba n lo?’ fi eyi han.

Fasehun so pe ki omo Yoruba to tun je aare ni Naijiria yoo to ogoji ọdun. “O se pataki ki a mọ ibi ti a o wa ki o to di asiko ti a wi yii.”

Fasehun ni ona bi ile Yoruba yoo se wa ni ipo amuyangan to fi je pe ipo aare ni Abuja ko ni nnkankan fun wa mo ni apero naa yoo da le lori.

“A gbọdọ di ara wa ni amure ni ona ti yoo fi je pe a ko ni naani Aso Rock ni nnkan bi ogoji odun si asiko yii.”.

Ninu oro miran, Alagba Fasehun so pe ajo OPC yoo se eye fun Aare Olusegun Obasanjọ fun sise gudugudu meje yaaya mefa. Idi abajọ ni pe Obasanjọ ti se ohun ti olori orile-ede yii kankan ko se ri.

Lara ohun ti Fasehun mu enu ba gege bi aseyọri Obasanjọ ni asunwon owo okeere Naijiria to je pe ọọdun milionu dola pere ni Obasanjo ba ninu re nigba ti o de.  “Sugbọn ni bayii, o ti so owo naa di nnkan bi bilionu metadinlaadota (lati $3 milionu si $47 bilionu).

Eyi ni Fasehun se so pe Obasanjo ye ni eni ti o ye ki Yoruba se ayeye ‘kare omo odo rere’ fun. Ojo keji ojo apero ti a wi tele, eyiini ojo keta osu kinni odun 2007 si ni won fi ayeye naa si.

Amugbooro n de ba ede ati asa Yoruba kaakiri agbaye

Ni Naijiria ti i se orirun iran Yoruba ati ni idale (kaakiri agbaye) ni akitiyan ti n lo lwoo lati mu amugbooro ba asa ati lilo ede Yoruba.

A o ranti pe lati orile-ede Geesi (Briteeni) ni Omidan Omolara Wood ti se eto aagbkale egbe kan ti n je Tiwantiwa. Egbe naa to bere pelu eta woro omo-egbe ti gbopon bayii. Ilakaka egbe yii ni lilo ede Yoruba lati maa fi irohin to ara eni leti ati lati fi se itakurọsọ. Kaakiri opo ibi ti omo Yoruba ati awon to ni ife si lilo ede Yoruba ni won si ti n da si Tiwantiwa.

Egbe titun kan naa tun wa ti oruko re n je Ajo Igbimo       (AYOG). Omọwe Francis Akindele ni o se idasile re. Ona fifi oju akọmọna se iwadii nipa ede ati asa Yoruba ni ajmo naa wa fun. Awọn to ni orukọ ninu eto Eko Yoruba, ati awọn ti o je eekan ọmọ Yoruba -  koda bi ise ti wọn yan laayo ki i se ede Yoruba – ni wọn wa ninu egbe yii. Lara awon ti o ti fi idunnu won han si egbe yii ni a ti ri awon agba-ojo Yoruba bii Ojogbon Dapo Adelugba, Ojogbon Bamgbose, Ojogbon Olatunji, Ojogbon Akin Isola, Ojogbon Wale Tomori, ati beebee lo.

Akitiyan Ojogbon Toyin Falola to wa ni ile eko giga kan ni Texas, orile-ede Amerika ye ni fifi enu ba. Ise takuntakun ni ojogbon yii n se lati ri pe idagbasoke de ba ohun gbogbo to ro mo igbesi aye adulawo. Gege bi a si se mo, okan pataki ni iran Yoruba ninu awon iran ti amo si Alawodudu.

Ni Naijiria funraare, orisirisi akitiyan lo n lo lati ri pe ina asa ati ise Yoruba to jo ajorehin tele di agbedide. Lara akitiyan yii ni ti egbe kan ti a mo si Yoruba Studies Association, Egbe Akomolede Yoruba, ati ti Olokoowo Oodua eyi ti o fi idi kale si Ibadan.

A o ranti pe awon enikookan ati ile-eko giga naa n gbiyanju. Opo eniyan lo da egbe osere, ile ise irohin ati eka kiko Yoruba sile paapaa ni Amerika ati ile alawofunfun, Yiroopu.

Ni ojo aipe, a o gbiyanju lati daruko iru awon egbe ati ogba ti n se akitiyan wonyi.

Idunnu wa ni pe igbiyanju wonyi ti n ni apere. Opọ eniyan ni o ti n gba pe nnkan amuyangan ni ede ati asa wa. Akitiyan wa yii paapaa ti mu ki awọn iran miran naa bere sise ikede ati gbe ede ati asa won naa laruge.

E ma je ki ako okan aare. Iwaju ni opa ebiti waa yoo ma re si, ase.

Ilu Wilmington ti o je ilu to tobi julo ni ipinle Delaware ni orile-ede Amerika wa lara awon ilu ti n se ayeye odun Osun gege bi won ti n se e ni ilu Osogbo to wa ni ipinle Osun, Naijiria.

Eyi jeyo nigba ti onirohin wa n fi oro wa agbateru eto yii lenu wo ni ilu Wilmington laipe yii.

Agbateru eto naa, Oloye Omowale Walker so pe ajodun yii bere lati bi odun mewaa sehin latari ajose to wa laarin ilu naa pelu ilu Osogbo. Inu osu Ogun - osu kejo odun oyinbo (August) - ti won n se ayeye naa ni Osogbo ni won n se ayeye naa ni Wilmington. Sugbon ojo kansoso ni won fi n see yato si nnkan bi odidi ose kan ti won fi n se e ni Naijiria.

Eti odo naa ni won a ti se pelu gbogbo eronja to ye. Se Oloye Walker ti ko nipa asa Yoruba - bi o tile je pe omobibi ile Amerika ni. O si ti se opolopo abewo si ile Yoruba. Oye Bobaselu ti ilu Osogbo ni Ataoja, Oba Oyewale Matanmi fi da lola, nigba ti o tun je oye Obadio ti ilu Remo ni ipinle Ogun.

Ajodun Omo Yoruba ni Filadefia

Awon omo Yoruba to wa ni ilu Filadefia (Philadephia) ni orile-ede Amerika yoo se ayeye kan lati gbe ogo Yoruba ga ni ojo kerindinlogbon osu kejo (osu Ogun) odun yii.

Irohin to te wa lowo so pe gbongan Salvation Army Complex to wa ni ojule 2128 North Broad Street, Philadephia ni ayeye yii yoo ti waye bere lati agogo mefa irole. Agogo mejila ale ni eto naa yoo wa si opin.

Ijo, ilu, ewi, aso ibile ati bee bee lo ni yo sele lojo naa.

AfonrereYORUBA: Fun ipolongo, imugbooro ati ilosiwaju Yoruba kaakiri agbanla-aye. E-mail: afonrereyoruba@yahoo.com