Make your own free website on Tripod.com

Afonrere YORUBA Gbode

Irohin Titun

Abawole Home Bonvenido Bonvenu | Igbelaruge Yoruba | Irohin Lakotun | oloyenewsgbode.tripod.com | Konyin, opon-itewe titun wo'ja agbaye | Irohin | Irohin | Iforowero Interview Page | Ikede | Photo Album Page | Leta Mailbag | E kowe si wa lori ero okan yin tabi nipa Yoruba: afonrereyoruba@yahoo.com E seun | Archives | New Page Title

Awon irohin olorijori

Soyinka fowo si lilo ede Yoruba ni Ile Igbimo Asofin

 

Otunba Oni yoo si aka oda si Igboho

Lati ibere osu ti n bo lo, awon eniyan agbegbe Oke ogun ko nii daamu lo si ona jinjin mo lati ri oda ikunle (paints). Nobel ni won n pe oda naa.

Idi abajo ni pe lati igbayi lo ni ile ise ti n po oda kan yoo si gbongan ipate oja re si ilu Igboho, olu-ilu ijoba ibile Oorelope, ipinle Oyo.

Irohin to te AfonrereYoruba lowo fi han pe ile ise Toki Chemical Manufacturers Limited yoo si gbongan ipate ti a wi yii ni ojo keta osu kokanla odun ti a wa yii.

Agogo mokanla owuro ni ayeye naa yoo waye nibi eyi ti awon eniyan jannkan-jannkan jakejado ile Naijiria yoo peju si.

Otunba Olawuwo Amao Oni ti o je omo bibi ilu Igboho ni o da ile ise pataki yii sile lati nnkan bi odun mewaa sehin.

Sanngo-Ota ni ipinle Ogun ni ile-ise yii  wa ni opopona Igboho bi a ba ti ya lati ori titi Marose to ti Eko lo si  Abeokuta. Sugbon gbogbo bi Oni, eni ti o je onimo-ijinle nipa eroja (chemical engineer) se gbe ile-ise re kale si agbegbe eko yii, ko gbagbe adugbo re rara. Eyi lo faa ti o fi ri pe ona to lo si ibi ti ile ise naa wa n je oruko Igboho. Bakannaa ni o se je pe o ronu ati wa si gbongan ipate awon ohun ti ile ise ti a wi yii n se si ilu Igboho fun anfaani awon ara ilu ati eniyan Oke ogun.

Oda olomi (emulsion), oda olororo (gloss paint) oda ti won le fi dara si aso (textile paint)  pelu eyi ti won le fi kun moto ni ile ise yii n se jade.

Ko tan sibe o. Toky Chemical Manufacturers tun n se oogun apefon (insecticide) ati apa kokoro (disinfectant and anti-septic) orisirisi. Beeni won n se oda ti awon tewetewe (printing ink) le lo paapaa.

Gbogbo eniyan ni awon alase Toky n reti nibi ayeye naa. Gbogbo awon ti n lo oda fi se ise ati awon kolekole ni won si n reti lati wa maa ba won ra oja.

Omi yoo bere si i yo pada ni Igbeti laipe

Ise ti bere ni pereu lati ri pe omi ero bere sii yo pada ni ilu Igbeti ti i se olu-ilu ijoba ibile Olorunsogo, Ipinle Oyo.

Iwadii AfonrereYoruba fi han pe lati bi odun kan sehin ni omi ko ti yo deede ni ilu naa. Asiko ti omi ba yo, kokoko ni omi naa yoo pon - de bi pe iru omi naa ko see mu tabi fi gbo jije.

A gbo pe ohun to se okunfa eyi ni ti bibe amu paipu to n gbe omi kasi lo si ibiti won yoo ti foo ki o to di pe won dari re si igboro fun lilo ara ilu. Inu odo gangan ni won gbe paipu yii gba tele. Oju ibi ti o ti be yii ni omi pelu idoti ti n wo inu re. Idoti yii wa lara ohun ti n ba paipu naa wa si igboro nitori ase ti o ye ki o se omi yii ati oogun apakokoro to wa ninu agbada naa ko ni agbara fun iru awon idoti ti n gba ona koro wo inu paipu to be naa. Eyi lo fa awon idoti inu omi ati pipon ti  omi naa n pon tele.

Adele Giiwa ajo olomi ipinle Oyo, Iyaafin Ibilola ‘Dotun   Oyegade fi to onirohin wa leti pe eyi ni ajo naa ri ti o se paa lase pe ki won dawo fifi omi rannse si igboro duro.

“A se eleyii lati ri pe awon ara ilu ko ko arunkarun latari omi ti n ti enu ero jade”.

Giiwa naa jeeri pe paipu akotun ni ajo naa n ri bayii. Won o si gbe gba inu omi mo. Won se eyi ki isoro ti won koju tele ma ba a tun yoju mo.

Oloye Gbode ri gbo pe nnkan bi ogofa ese bata ni ona ti paipu atijo gba. Sugbon eyi ti won n se bayi ti o je ti ori-ile gun to irinwo ese bata o din ogoji. Se Yoruba kuku so pe ona jinjin ki i ta’ni losi. O san ki won se nnkan bo se ye ju ki a gba ona eburu eyi ti yoo maa mu ipalara ati inawo idakureku lowo lo.

Bi nnkan ba lo bo se ye ki o lo, o ye ki a so pe ki osu  kewaa ti a wa nibe yii to pari ki omi o ti maa yo pada.

 Odunlade f’akoyo ni Amerika

Ogbontagi onise-ona kan, Omooba Tunde Odunlade se afihan awon ise ona ni ilu Washington DC ti i se olu ilu orile ede Amerika laipe yii nibi ayeye ti won fi se iranti orirun Aafirika (Africa Day).

Asoju opolopo orile-ede to wa ni Aafirika lo peju pese nibi ayeye naa, nigba ti akowe agba fun Ajo Agbaye, Omowe Kofi Annan ati asoju ijoba ile Amerika paapaa wa nibi apeje to kase ayeye naa nile.

Lara ohun iwuri to tun sele nibe ni ti Arabinrin Abiodun Koya to ko oriki orile-ede Amerika ati ti orirun

Aafirika lai wo iwe kankan nibe.

Fun oju-inu to ni ati oro iwuri to so nibi ayeye naa, opo oro awon to wa nibi ayeye naa lo kan saara fun asise-ona ti a wi yii, Tunde Odunlade.

Odunlade je eni ti ise ona sise je aayo re. Nnkan bi ogoji odun o din die ni o si ti wa lenu re. Odun gbonhan ni o ti n gbe asa awa alawodudu laruge lati ibi yii titi o fi de oke okun.

Aworan yii fi Omo-oba Odunlade han pelu die lara awon to wa nibi ayeye ti a wi yii, eyi to waye ninu osu karun-un odun yii.

Ayeye ojo Okeho

Igbaradi n lo lowo fun sise ayeye Ayajo Ojo Okeho.

Ojo kejidinlogun osu kokanla tii se osu Belu ni ayeye naa yoo waye ni ilu naa.

Nibi iru ayeye yii ni won ti ma a n se eto nipa idagbasoke ilu naa ti o je olu-ilu ijoba ibile Kajola.

Ekunrere alaye ninu Oloye Gbode ti n bo.

 

Fulani n fi eran je oko wa

Agbe olokonla kan, Ogbeni Ademola Olowooko ti ke gbajare si ijoba ati awon agbofinro lati wa ko awon Fulani daran-daran ni ijanu.

Ademola ti o je mo ile Olowooko ni ilu Iseyin so pe inu oko awon ni awon Fulani naa n da eran won si. “Eni ti o ba si ta ko won, sise ni won n se onitohun lese”. O ni oun n gba enu awon agbe agbegbe naa soro ni.Ajoro Egbe

 

Apero Onimo-Ede Yoruba tun ko

Awon omo egbe Onimo-Ede Yoruba (Yoruba Studies Association of Nigeria) ati awon to ni ife si ede Yoruba yoo bere ajoro olodoodun won ni Ojo Isegun ojo Keje Osu  Belu (Osu Kokanla) odun yii.

Gbongan Ikekoo-Nla to wa ni Eka ti n ko nipa Ise Oju-Inu (Faculty of Arts Large Lecture Theatre) ni ile eko giga Fasiti ti Ibadan ni ajoro olose kan naa yoo ti waye. AfonrereYoruba ri gbo pe Imo Ero ati Sayensi Yoruba (Yoruba Science and Technology) ni Ori-Ero (Theme) ti odun yii.

Ojo’Ru tii se ojo kejo osu kokanla odun ni apero gan-an yoo bere ni deede aago mewaa owuro. Ojo kokanla osu Kokanla ni apero yoo to wo.

Giiwa ile eko giga naa, Ojogbon O.A. Bamiro ni yoo je olugbalejo pataki nibe nigba ti alakoso Eka ti n ko’ni nipa Ise Oju-Inu,, Ojogbon Aduke Adebayo ni yoo maa ki awon olujiroro kaabo.

Ojogbon E.O. Oladiran ti Eka ti n ko’ni nipa ‘fiyiwoyi’ (Physics - fisiksi) ni yoo si’de apero naa nipa siso oro eyi ti akori re je Afojusun Ara Afrika nipa Imo Ijinle ti a n fi oju ri (The African Perspectives of the Physical Sciences).

Awon oluko onimo ijinle meji miran yoo pelu Oladiran nipa kika iwe apileko.

Akori oro awon ojogbon meji naa ni Die ninu Oye Yoruba nipa  awon Eweko ti a fi n se Iwosan ati Igbese Ilosiwaju fun Imo Ero ati Sayensi Yoruba. Ojogbon A. Egunyomi ti Eka ti n ko nipa Imo Eweko ati Kokoro Wewe ati Ojogbon O. Omole ti Eka ti n ko nipa Imo Ero ti awon mejeeji wa lati Fasiti Ibadan ni yoo ka iwe apileko kinni ati ikeji.

Eka Ori-Oro ti awon omowe lati itosi ati ona jijin yoo so oro le lori lo bayii:

Imo ero ounje Yoruba (Yoruba food technology)

Imo ero ise irin Yoruba (Yoruba metallurgy)

Imo sayensi ati eto aabo Yoruba (Yoruba science and security)

Imo ise isegun Yoruba (Yoruba medicine)

Imo ero ise aso hihunYoruba (Yoruba textile technology)

Imo ero ise afigise Yoruba (Yoruba wood technology)

Imo ero ise agbe Yoruba (Yoruba agricultural technology)

Imo ero ise aro rire Yoruba (Yoruba dyeing technology)

Imo ero ise oti pipon Yoruba (Yoruba brewery technology)

Imo sayensi abinibi iran Yoruba (Yoruba traditional science)

Sayensi Yoruba ninu oogun pipo (Yoruba pharmacognosy/pharmacology)

Sayensi Yoruba ninu imo eko (Yoruba science and technology in education)

Litireso ati sayensi Yoruba (Literature and Yoruba Science)

Ede ati sayensi Yoruba (Language and Yoruba Science)

Litireso ati imo ero Yoruba (Literature and Yoruba Technology)

Ede ati imo ero Yoruba (Language and Yoruba Technology)

Ero ijinle ati sayensi Yoruba (Philosophy and Yoruba Science)

Ero ijinle ati imo ero Yoruba (Philosophy and Yoruba Technology)

Imo isiro sayensi Yoruba ( Yoruba calculus)

Imo agbara-airi awon Yoruba (Yoruba metaphysics)

 

Olori Onigbeti waja

Olori Elizabeth Motunrayo Oyebisi ti i se iyawo keji Onigbeti ti ilu Igbeti, Oba Emmanuel Oyekan Oyebisi Keji dagbere f’aye ni ojo’Ru ti i se ojo kerin osu kewaa odun 2006.

Ile iwosan kan ni ilu Ilorin, Ipinle Kwara ni olori naa dake si. Ojo keji ni won gbe oku re wa si Igbeti nigba ti won si sin oku naa ni ojo’Bo ni Igbeti.

Gbogbo eniyan lo n soro olori Motunrayo pelu edun okan nitori eni rere ni nigba aye re.

 Osise ijoba ibile Olorunsogo ni eka eto ilera ni oloogbe naa je. Omo meji, Ponnle ati Mosunmola ni o fi s’aye lo.

Ilu Oyan ni o ti n sise tele. Lehin ti kabiyesi gun ori aga awon baba re ni olori naa gba iwe isipopada (transfer) wa si Olorunsogo.

Ki Oluwa de’le fun alaisi, ki ojo jinna sira, ase.

Odun meje ijoba alagbada:

 

Omo Naijiria n se paga!

 

Bi ere bi awada, o  pe  odun merindinlaadota ti orile-ede Naijiria ti gba ominira lowo awon Oyinbo Geesi. Bakannaa, odun meje abo ti ijoba alagbada ti wa lori aga n ko werewere.

Nigba ti o n tewo gba eto akoso ijoba ni odun 1999, Ogagun Matthew Olusegun Okikiola Aremu Obasanjo se awon ileri kan eyi to da lori ohun ti awon ara ilu le maa reti lati owo ijoba re.

Koko pataki to jeyo lara awon nnkan ti Aare titun naa so pe oun yoo mojuto ni:

1. mimu iderun ba awon omo ile Naijiria

2. gbigbe ogun aja aiwehin ti iwa ibaje

3. sise ajinde igbagbo awon eniyan ninu ijoba

4. sise eto ijoba lona ti ise ijoba yoo fi maa ja fafa

5. mimu opin de si wahala ti n sele ni agbegbe ese-odo Naija Delta

6. mimu ijafafa de si ina oba - eyi ti a mo si NEPA nigbanaa

7.  riro awon jagunjagun orile-ede yii lagbara lona ti won yoo fi le ta kanngban pelu awon elegbe                                    won nibikibi lorile agbaye

8. sise eto eko, eto ilera ati eto igbokegbodo eto irinna to ye kooro

9. mimu idagbasoke to yanrannti de ba eto ogbin

10. riri pe ina ajorehin ti awon eto oko-owo ati ile-ise gbogbo n jo ko sele mo

11. mimu opin de si oro adigunjale ati aiko lee fi edo le ori oronro ninu ile tabi lona irinajo

12. rira iyi Naijiria to ti sonu pada

13. eto to gbooro laarin awon eka ijoba meteeta to wa loride ede yii - eyiini, ijoba apapo, ijoba ipinle ati ijoba ibile

14. sise atunse si reluwee ati ile-ise oko oju omi ti won ti di akurete.

Odun keje-abo ti adehun yii ti je sise, kin ni a le so nipa ijoba Ogagun Olusegun Obasanjo?

Eyi ni akori oro to gba enu awon to ba Oloye Gbode soro latari ayeye sise odun merindinlaadota ti orile-ede Naijiria ti gba ominira.

Afenuko opo awon to ba wa soro ni pe yato si asiko ogun ati asiko rogbodiyan June 12, ifooro-emi, aini aabo lori, ifoya nipa kin ni eniyan yoo je kin ni eniyan yoo mu ati ona wo ni a o gbo bukaata ko ti le koko to bayii ri nigba ti orile-ede Naijiria ti n be.

Lara awon to ba wa soro ni Ogbeni Kunle Okesipe, oluko kan ti o je omo Saki, Alufaa Amusat Adebisi lati Tede, Iyaafin Yinka Owolabi ti o je onise-ona kan, Ogbeni Abdul-wahab Abdullhameed ni Ilorin.

Afenukoo won ni pe yato si ero gaasimileti (GSM) ati owo epo ti n gbe owo lori, ohun gbogbo ti ijoba yii ba nigba to de lo ni ifasehin.

“O je ohun edun-okan fun wa pe lati ipari odun yii, owo epo yoo tun gbe owo loi gege bi Aare se pa asamo re ninu oro to so ni ojo kinni osu kewaa yii. Afi Oluwa gba wa.”

OPA n mura fun ayeye odun kewaa

Egbe kan ti idagbasoke agbegbe Oke ogun je logun, Oke Ogun Progressive (USA) Incorporated n gbaradi fun ayeye odun kewaa ti o ti di dida sile.

Ojo kokandinlogbon osu kokanla (osu Belu, November) odun yii ni ayeye naa yoo waye.

Agbegbe Queens ni ilu New York ni ayeye naa yoo si ti sengere.

Awon omo-bibi agbegbe Oke ogun ni ipinle Oyo ni o da egbe yii sile. Gege bi alukoro egbe naa, Ogbeni Sunday Adegbola se fi to wa leti, ona ati ri pe, “ a ko ara wa jo, a si jo n se asepo, a si tun n jiroro lori idagbasoke enikookan wa ati ti ilu ti a ti wa” ni o se okunfa dida egbe yii sile.

Lenu igba ti egbe yii di kikojo, opo nnkan idagbasoke lo ti gbe se. Pataki ninu eyi ni iranlowo owo goboi ti won n fun awon akekoo to wa ni ile-eko giga ni Naijiria. Egberun meedogbon naira ni won n fun akekoo kookan lodoodun. Akekoo bii metala ni n je anfaani yii lodun kan. Titi ti akekoo bee yoo si fi pari eko re ni ile eko giga ni yoo ma je anfaani naa niwon igba ti o ba ti n se daadaa ninu eko re. Odun bii merin sehin ni eto pataki yii ti bere.

AfonrereYoruba ri gbo pe egbe naa yoo maa se iranlowo fun awon omo egbe to ba jade ile iwe ni Amerika paapaa bere lati odun yii lo.

Lara awon to se agbateru egbe yii ni Alagba Tolani Ogundiran ti o je Aare egbe naa ki o to di oloogbe ni odun 2004, Ojogbon Segun Odesina, Alhaji Yekini Salami, Oloye R. Adedokun Atitebi, Diakoni Timothy Ayinla, Ogbeni Toye Okesola, Alhaja Yinka Atitebi, Oloye Yinka Ayedun, Ogbeni Sunday Adegbola, Alhaja Adunola Salami, Ogbeni Adejare ati Alagba Olaleye.

Lara awon ti won fun dijo n gbe egbe yii ro ni Iyaafin Ayinla, Ogbeni Omodewu, Ogbeni Adesola Ige, Ogbeni Akande, Iyaafin Oladokun ati Iyaafin Akande ati awon jankan jankan miran.

Ogunsola n fe ifowosopo fun idagbasoke

 Alaga ijoba ibile Ila-Oorun Saki, Honerebu Muda Dayo Ogunsola ti ke si awon eniyan ijoba ibile naa lati fi owo so owo po pelu ijoba oun ati pelu ijoba ipinle Oyo ki idagbasoke ti kaluku n fi okan si le baa tete waye.

Ago Amodu ti i se ibujokoo ijoba ibile naa ni Ogunsola ti so oro yii ni ojo ketala osu to koja nigba ti o n bura fun igbakeji alaga titun ti won sese yan fun ijoba ibile naa.

Oluware ni Honerebu Joseph Adejumobi Adegoke lati  Oje Owode, Woodu 6 & 7.

Alaga naa woye pe iyipada ko lee  sai waye ni idakookan ninu oro awa omo eniyan ki ilosiwaju baa le wa.

O so pe bibo si ipo igbakeji ti Adegoke bo si yii yoo so eso rere fun agbegbe ila-oorun Saki.

A o se iranti pe igbakeji alaga tele, Honerebu Kola Abimbola ni won ro loye ni bi osu meloo sehin.

Olori omo egbe to po julo ni ile igbimo Asofin ijoba ibile naa ni Adegoke ki o to de ipo titun yii. Oje Owode  kan naa ni igbakeji tele, Abimbola ti wa.

Igbakeji titun naa ti bere sii sise po pelu alaga ati awon osise yooku fun idagbasoke ijoba ibile naa.

 

Oludije Gomina labe egbe PDP ni Ipinle Oyo  Adeojo so pe idibo ‘ko mese o yo’ yoo waye - Adedibu, Akala so pe ‘beeko’

Eekan kan ninu egbe agboorun (PDP), Oloye Yekinni Ayoade Adeojo ti so pe ibo talo ga ju l’aba ni won yoo fi mo eni ti yoo dije ibo gomina ipinle Oyo loruko egbe naa.

Ilu Ibadan ni Oloye Adeojo ti so oro yii ninu iforowere pelu onitrohin wa. O so oro naa ni ifesi si oro ti ogbontagi oloseelu nni, Oloye Lamidi Ariyibi Adedibu so pe ko nii si ibo abele kankan nitori pe Gomina ti o wa lori aga lowo bayii, Otunba Christopher Alao Akala ni egbe yoo fa kale.

Adeojo ti oun naa fee dije fun ipo ti a wi yii fi idi re mule pe ohun ti awon alase egbe fi enu ko si ni pe eto ‘ta lo ga ju laba?’ ni won yoo fi yanju eni ti yoo dije fun ipo gomina loruko egbe alaburanda, Peoples Democratic Party, PDP.

A o se iranti pe Oloye Adedibu so nibi ayeye ti won fi n se ajodun odun kokandinlogorin to ti de’le aye pe ko ni si ibo abele eyi ti a mo si praimari lati fi yan eni ti yoo gbe asia egbe PDP lasiko idibo gomina ti n bo. O ni eyi ri bee nitori pe Akala ni oun fa kale. Akala si ni yoo see.

Otunba Akala funraare naa so ni ojo’Bo to koja pe enikeni to ba gba ‘foomu mo fe dije’ fun ipo gomina labe asia egbe PDP kan fi owo re jona ni.

Kayeefi ati ala ti ko lee se ni Adeojo ka gbogbo oro yii kun.

Gege bi o ti wi, “awa meta ni won ko egbe PDP le lowo ni ipinle Oyo, Baba Oloye Baba Olopoenia, emi gege bi enikan ati Baba Adedibu. Kin ni enikan soso yoo se wa so pe ohun ti oun ba fe ni yoo se. Ibikibi ti iyen ba ti n waye, iyan ki i se egbe mo. Bee si ni egbe ti o bowo fun demokresi

ni egbe wa.”.

Adeojo ti o je Seriki Musulumi ile Yoruba fi idi re mule pe enikeni to ba ja ewe olubori nibi ibo ‘praimari’ ni oun o fi owo sowopo pelu “niwon igba ti ibo naa ba ti je sise ni iroworose. Ti ko si fifi igba kan bo okan ninu. Ti ko si si tipa-tikuuku”.

Seriki laa mole pe ohun edun okan gbaa lo je pe awon to wa n fe fi owo lale ninu egbe yii, asawo ni won je ninu egbe PDP.

“Se bi inu egbe APP ni Baba Adedibu wa  tele. O ri pe a sise, a gbe egbe jokoo tan o wa sa wa. Dide to si de, ko duro si egbe jegede....”

Oloye Adeojo fi owo re soya pe oun ni o n se akoso opo omo egbe to po ju ni ipinle Oyo lowo bayii “pelu ogo Olohun Eledumare.” Latari eyi, o ni bi ibo gbangba lasaa ta ba waye, oun ko ni iyemeji pe oun ni yo jawe olubori ‘niwon igba ti o ba ti lo ni iroworose’.

O se alaye pe nigba ibo to koja ‘se bi kansilo kansoso ni Baba Adedibu ni ni gbogbo ile Ibadan nigba ti emi ni aadojo (150). E o ri pe iyato wa nibe gedegbe?’

Oloye Adedibu ni tire n fi owo lale pe bi oun ti wi ni oro yoo ti ri.

Agboroso kan fun alaga egbe PDP ni Abuja, Oloye Ahmadu Ali fi to AfonrereYoruba leti pe egbe naa ko fe se nnkan ti yoo mu idarudapo wa sinu egbe.

“Ibo ta lo ga ju laba?’ la o fi yan awon ti yoo gbegba ibo loruko egbe wa. Idi abajo ni pe a ko fe ki enikankan so pe n se ni won ti Kandideeti le wa lori ni tipatipa. Bi olukaluku ba se gbe’won si ni yoo fi ibi ti kaluku yoo wa han”.

 

Akala ni ijoba oun ko ko iyan awon ori ade kere

Gomina Ipinle Oyo, Otunba Christopher Adebayo Alao Akala ti laa mole pe ijoba to wa lode yii ko ko iyan awon oba ati ijoye kere rara.

Igbope ni ijoba ibile Oorelope ni gomina ti so oro yii nibi ayeye gbigbe opa ase fun Onigbope titun, eyiini Oloye Mathew Olaniyi Atoyebi Keji. Omowe Ebenezer Okebukola ti i se akowe agba nile ise ijoba ti n mojuto oro ijoba ibile ati ti oye (Ministry of Local Government and Chieftaincy Matters) lo fi ise gomina nibi ayeye yi.

Latari eyi, gomina gba awon ara ilu ni imoran lati ba oba titun naa fi owo so owo po. O si ro gbogbo ori ade orun ileke to wa ni ipinle yii lati fi owo so owo po pelu ijoba oun, ki erongba ati mu idagbasoke ba ipinle yii le baa jo.

Nigba ti oun naa n soro nibi ayeye naa eyi to waye ni ojo kokanla osu kejo odun yii, Alaafin Oyo, Oba Lamidi Adeyemi Keta so pe irorun ati igbayegbadun awon ara ilu ni awon oba ati ijoye ilu n la kaka le lori. O so pe won sun mo awon eniyan wonyi, won mo ohun ti awon ara ilu n fe. Latari eyi o se pataki ki ijoba fun won laye lati maa ko ipa to joju ninu ise idagbasoke ati ase pipa ni ilu.

 

Iforukosile oludibo bere ni ipinle Oyo

Iforukosile awon omo Naijiria ti o to iboo di bere lojo’Bo ni Ipinle Oyo ati awon ipinle miran ni Naijiria.

Ojo keje osu kewaa ti a wa yi ni eto naa ye ki o bere gege bi ikede ti ajo dibo-dibo (Independent Electoral Commission, INEC) se tele.

Sugbon awon ipinle die nikan ni eyi ti sele. Olobo ti o te AfonrereYoruba  lowo ni pe ajo INEC se kinni naa ni mokan-mokan latari ohun-elo ti ko to.

Iwadii wa fi idi re mule pe aapon n se yo nibi eto naa nitori opo eniyan nilati duro pe ki won to ri oruko fi sile. Idi abajo ni pe ero ti yoo ya foto won gege bi o se je ara eto naa ko sise gaara. Idanilekoo ko tun to.

Alaga ajo INEC ni Ipinle Oyo, Alhaji Isiaku Maigoro  fi okan awon eniyan bale sa wipe gbogbo kudie-kudie ti o se’yo ni ajo naa ti n se ohun gbogbo to ye lati ri pe o dopin.

Eto fifi oruko sile lati di ibo wa fun enikeni to ba je omo ile Naijiria. Iru eni bee gbodo ti pe omo odun mejidinlogun tabi ju bee lo.

Ati okunrin ati obinrin ni eto naa si wa fun pelu.

Isunsiwaju eto naa ko ya awon onwoye lenu pupo. Idi ni pe imurasile Ajo INEC fun eto pataki yii ko dabi eni pe o to. Fun apere, ero ti yoo ya foto oludibo pamo gege bi ara eto ati ri pe ko si fifi oruko sile leemeji ni ko to.

Ero yii bi egberun lona ogofa ni Ajo naa so pe oun n reti. Nnkan bii egberun metalelogbon pere ni o wa ni arowoto Ajo naa titi irole ojo Eti ti o ku aaro ti eto naa yoo bere.

A o se iranti pe lopolopo igba, ibi ti ohun elo to, magomago kii se ko ma wa; ki a to wa so igba ti ohun elo  ko ba to.

Gbogbo bi o ba ti wu ki o ri sa, e je ki a jade daadaa, ki a lo fi oruko sile bi eto naa ba ti bere.

 

Ijoba Oorelope, Alepata gbe igbese akin lori oro awon ole

Ijoba Ibile Oorelope ti ra alupupu bii mewaa latari ati mu ise awon alaabo ilu jafafa si.

Eyi nikan ko, ijoba ibile naa, labe akoso Honerebu Sunday Adeola se atunse moto ti awon ojulalakan-fi-n-sori, beeni o si gba awon eniyan si ise ode si.

Alepata ti ilu Igboho, Oba Johnson Oyeyiola  Igbaraola Keta paapaa ko fi oro naa jataa rara. Se oniluu ko nifee ki o tu. Nse ni Kabiyesi gba awon ode bii mewaa kun eyi ti ijoba ibile gba lati ri pe gbogbo ona to wo ilu Igboho ni awon ode wonyi n yipo latari ati ri pe awon adigunjale ati awon onise-ibi miran ko fi adugbo naa se buba mo.

A o se iranti pe idaamu po pupo lati owo awon adigunjale ti won so jinni-jinni bo awon to ba ti fe rin ona gbogbo to wa ni agbegbe Oke ogun.

Awon ijoba ibile to wa ni agbegbe naa se eto ati ro awon olopaa lagbara. Beeni won se eto fun awon Ojulalakan-fi-n-sori (Fijilante).  Sibe eyi ko da awon onise-ibi naa lekun. Yato si pe won n ja nnkan gba lowo awon ero ti n ti Oke ogun lo si awon ilu nla to yi agbegbe naa ka, won a se ose si awon eniyan naa lara bi won ko ba pa won.

Oro naa le to bee ti o fi je pe bi eniyan ba lo  irinajo, o di igba ti o ba pada de, tabi ti o kan si awon eniyan re pe oun ti de ibi ti oun n lo laalaafia ki okan to bale.

Ni kopekope yii (ojo kerin osu kejo, lati so paato) ni awon amookunsika yii da awon eniyan kan lona ninu Igbo Ijoba to wa laarin Igbeti ati Igboho.

Ibi ti won n pe ni Tofolo ni awon eniyan naa de ti awon onise-ibi naa fi da won lona.

Won gba owo, won gba ero ibanisoro lowo won.

Lara awon to fi ara gba nibi isele yii ni Ogbeni Dele Ajala ti o je oluko kan ni Igbope. Oun ati idile Adeleke to wa ninu oko ni awon onise-ibi yii sose fun ninu oko ti Ogbeni Ajala n wa.

Oko to tele ti won, eyiini oko awon osise ile ifowopamo Wema to wa ni Igboho paapaa fi ara gba  nibi isele naa.

Awon bii marun-un to wa ninu oko naa ni awon ogaara yii gba ohun ti won ba lowo won.

Ojumomo ni nnkan bi agogo marun-un abo si mefa irole ni isele yii se ki i se pe ile ti su.

Lehin eyi ni awon otelemuye wa si ilu ti won ko awon ti won fura si. Ehin eyi kan naa ni Oba Oyeyiola ati ijoba ibile gbe awon igbese ti a so soke yii.

A si dupe pe lati igba ti eyi ti sele ni awon onise-ibi naa ti wo sin bi obe inu paanu. Ki Oluwa ba wa ko ese won kuro nile patapata, ase.

 

 

 

Enter supporting content here

AfonrereYORUBA: Fun ipolongo, imugbooro ati ilosiwaju Yoruba kaakiri agbanla-aye. E-mail: afonrereyoruba@yahoo.com